Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Ó jẹ́ ayọ̀ wa láti sọ fún yín pé àwọn akéde tí iye wọn jẹ́, ẹgbàá méjìlélógóje àti okòó lé nírínwó àti mẹ́ta [284,423] ló ròyìn lóṣù September 2008, wọ́n sì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jẹ́, ọ̀kẹ́ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé ẹgbàajì àti àádọ́ta lérúgba àti mẹ́rin [544,254] pẹ̀lú àwọn tó fìfẹ́ hàn. Èyí fi hàn pé a darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó fi, ẹgbàá mẹ́tàdínlógún àti okòó lé lẹ́gbẹ̀rin àti mẹ́jọ [34,828] ju ti oṣù September ọdún tó kọjá lọ. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa fìtara bá iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ náà nìṣó.—Mát. 28:19, 20.