Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní February 1 sí 15: Pínpín ìwé Àṣàrò Kúkúrú Lákànṣe. February 16 sí 28: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà la máa lò. Ìwé míì tá a tún lè lò bí àfidípò ni ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la máa lò. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ wa míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kì í ṣe déédéé nínú ìjọ, ẹ sapá láti fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ká sì ní in lọ́kàn láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wọn.
◼ Ẹṣin ọ̀rọ̀ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi tọdún 2009 ni “Ṣé Gbogbo Ìsìn Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?” Ẹ wo ìfilọ̀ tó jọ èyí nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù September 2008.
◼ Ẹ̀ka ọ́fíìsì nílò àwọn tó lè túmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Ísókó. Awọn tó bá fẹ́ yọ̀ọ̀da ara wọn fún iṣẹ́ yìí gbọ́dọ̀ mọ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Ísókó sọ dáadáa, kí wọ́n mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Kí ẹni tó bá rò pé òun tóótun, tó sì fẹ́ láti ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì kọ̀wé láti fi tó ẹ̀ka ọ́fíìsì létí. Ẹni tó bá fẹ́ kọ̀wé gbọ́dọ̀ jẹ́ àpọ́n, kó sì jẹ́ ẹni tí kò ní ohun tó lè dí i lọ́wọ́ láti lè wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì tá a bá pè é.