Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 2
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 2
Orin 59
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv-YR orí 1 ìpínrọ̀ 10 sí 18 àti àpótí tó wà lójú ìwé 13
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 36-39
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 39:1-16
No. 2: Àwọn Kan Wà Nípò Tó Ga Ju Tiwa Lọ (lr orí 8)
No. 3: Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́? (td-YR 13A)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 94
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn ará létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù February sílẹ̀.
10 min: Sísọ Orúkọ Ọlọ́run Di Mímọ̀. Ká fi ìtara sọ àsọyé yìí tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ojú ìwé 273 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 274 ìpínrọ̀ 1.
10 min: Bá a ṣe lè dáhùn ìbéèrè nípa ìfàjẹ̀sínilára. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, ẹ̀kọ́ 12, ìpínrọ̀, 1, 5, àti 6. Jẹ́ kí aṣáájú ọ̀nà kan ṣe àṣefihàn kúkúrú kan, nípa bó ṣe lè lo ìpínrọ̀ 5 àti 6 láti dáhùn ìbéèrè yìí, “Kí nìdí tẹ́ ẹ fi ń kọ ìfàjẹ̀sínilára?”
10 min: Ìwé Tá A Máa Lò Lóṣù March. Ní ṣókí, sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó inú ìwé tá a máa lò. Ní kí àwùjọ sọ ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ní lọ́kàn láti lò nígbà tí wọ́n bá fẹ́ fi ìwé náà lọ àwọn èèyàn. Ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì.
Orin 96