Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣàtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní February 23, 2009. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ January 5 sí February 23, 2009, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á sì darí rẹ̀ fún ogún [20] ìṣẹ́jú.
1. Báwo ni Ọlọ́run ṣe mú kí ìmọ́lẹ̀ wà lọ́jọ́ kìíní nígbà tó jẹ́ pé ọjọ́ kẹrin ló tó ṣe àwọn ohun atànmọ́lẹ̀? (Jẹ́n 1:3, 16) [w04-YR 1/1 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 5]
2. Kí nìdí tí Nóà ṣe fi Kénáánì gégùn-ún? (Jẹ́n. 9:20-25) [w04-YR 1/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 2]
3. Ọjọ́ wo ni májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, títí dìgbà wo ló sì máa wà? (Jẹ́n. 12:1-4) [w04-YR 1/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 4; w01-YR 8/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 13]
4. Kí ló fi hàn pé fífẹ́ tí Nímírọ́dù àtàwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ fẹ́ “ṣe orúkọ lílókìkí fún ara [wọn]” forí ṣánpọ́n? (Jẹ́n. 11:4) [w98-YR 3/15 ojú ìwé 25]
5. Níwọ̀n bí 2 Pétérù 2:7, ti pe Lọ́ọ̀tì ní “olódodo,” kí ló ṣeé ṣe kó mú kó yọ̀ǹda àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ fáwọn èèyànkéèyàn yẹn? (Jẹ́n. 19:8) [w05-YR 2/1 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 15 àti 16; w04-YR 1/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 3]
6. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ojúṣe àwọn ọkọ tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni láti bójú tó ìdílé wọn, kí ló mú kí Ábúráhámù lé Hágárì àti Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ lọ́ sí aginjù? (Jẹ́n. 21:10-21; 1 Tím. 5:8) [w88-YR 2/15 ojú ìwé 31]
7. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìsapá Élíésérì láti ṣe nǹkan bí Jèhófà ṣe fẹ́ nígbà tó ń wá aya fún Ísákì? (Jẹ́n. 24:14, 15, 17-19, 26, 27) [w97-YR 1/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 2]
8. Kí ni ìtúmọ̀ àlá tí Jékọ́bù lá níbi tó ti rí àwọn áńgẹ́lì lórí ‘àkàsọ̀ tí wọ́n ń gòkè, tí wọ́n sì ń sọ̀ kalẹ̀ lórí rẹ̀’? (Jẹ́n. 28:10-13) [w03-YR 10/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1; w04-YR 1/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 6]
9. Kí nìdí tí Rákélì fi fẹ́ gba èso máńdírékì tó jẹ́ ti ọmọ Léà? (Jẹ́n. 30:14, 15) [w04-YR 1/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 7]
10. Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dínà ṣe jẹ́ ká mọ jàǹbá tó wà nínú kéèyàn máa rìn ní bèbè ewu? (Jẹ́n. 34:1, 2, 19) [w04-YR 10/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 6 àti ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 5]