Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ August 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé gbogbo ẹni rere ló ń lọ sọ́run. Ṣéwọ náà gbà bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ nípa ayé. [Ka Sáàmù 37:11, 29.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Jésù kọ́ni nípa bí ọjọ́ iwájú àwa èèyàn ṣe máa rí láyé ńbí.” Sọ̀rọ̀ lórí àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 22.
Jí! July–September
“Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé béèyàn bá lóyún láìròtẹ́lẹ̀, ṣíṣẹ́yún lọ̀nà àbáyọ tó rọrùn. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé gbàrà tóbìnrin bá ti lóyún báyìí ni ìwàláàyè ọmọ náà ti bẹ̀rẹ̀. [Ka Jóòbù 3:3.] Kí wá nìdí tẹ́nì kan á ṣe fẹ́ láti fòpin sí ìwàláàyè ṣíṣeyebíye ọmọ tá ò tíì bí?” Fi àwọn àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 3 sí 9 hàn án.
Ilé Ìṣọ́ September 1
“Àwọn kan máa ń sọ pé béèyàn bá ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, ó máa ń fi ọrọ̀ dá èèyàn lọ́lá, àmọ́ béèyàn bá wà nípò òṣì, ó túmọ̀ sí pé inú Ọlọ́run ò dùn sónítọ̀hún nìyẹn. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Ohun kan tó gbàfiyèsí ni pé Jésù kì í ṣe ọlọ́rọ̀ nígbà tó wà láyé. [Ka Lúùkù 9:58.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé irú ìbùkún táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè máa retí látọ̀dọ̀ rẹ̀.”
Jí! July–September
“Bóyá wọ́n mọ̀ tàbí wọn ò mọ̀, ọ̀pọ̀ òbí tọ́rọ̀ ọmọ jẹ lógún máa ń ṣe ohun tó wà nínú Òwe 22:6. Ṣó o mọ ohun tó jẹ́ apá pàtàkì lára ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 20 nínú ìwé ìròyìn yìí tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa kọ́ àwọn ọmọ ní ìwà ọmọlúwàbí.”