Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ ká máa torí ẹ̀ dúpẹ́. Nígbà tá a ṣàròpọ̀ àwọn ìròyìn wa ti oṣù March ọdún 2009, inú wa dùn láti rí i pé iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a darí jẹ́ ọ̀kẹ́ méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàje àti ọ̀ọ́dúnrún ó lé méjìlá [573,312], èyí tó fi ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàje àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó dín méje [33,893] ju iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a darí lóṣù March ọdún tó kọjá.