Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò lóṣù August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tẹ́ ẹ ní lọ́wọ́, irú bí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Ẹmi Awọn Oku, Wọn Ha Le Ran ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha wa Niti Gidi Bi, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?, àti “Sawo o! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ká sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tá a bá kọ́kọ́ bá onílé sọ̀rọ̀ tá a sì fún un níwèé. Jẹ́ kó mọ bó ṣe lè jàǹfààní látinú ìwé náà nípa fífi bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án ní ṣókí. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Bí onílé bá fìfẹ́ hàn, ẹ fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Bí onílé bá ti ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, kẹ́ ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ lè fún un ní ìwé tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ìwé míì tẹ́ ẹ tún lè lò bí àfidípò ni, Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà.
◼ A máa sapá gidigidi láti kéde àpéjọ àgbègbè ti ọdún 2009 fáwọn èèyàn. Olúkúlùkù akéde máa láǹfààní láti pín ìwé ìkésíni àkànṣe ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Tí àpéjọ àgbègbè tá a yan ìjọ yín sí bá ku ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ni kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni náà.
◼ A máa fi báàjì àyà ránṣẹ́ sí gbogbo akéde nípasẹ̀ ìjọ. Irú báàjì àyà kan náà làwọn tó ń lọ sí àpéjọ àgbáyé máa lò.