Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ July 1
“Ọ̀pọ̀ nínú wa ni kì í mọ ohun tá a lè sọ fún ọ̀rẹ́ wa tó bá ní àìlera tó le gan-an tàbí àìsàn tí kò gbóògùn. Kí lèrò rẹ nípa ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì yìí? [Ka Jákọ́bù 1:19. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí fúnni láwọn àbá tó wúlò gan-an, tá a gbé ka àwọn ìlànà inú Bíbélì.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.
Ji! July–September
“Ǹjẹ́ o rò pé ọrọ̀ ajé máa tó fara rọ? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ pé Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tó yẹ ká ṣe ní àwọn àkókò tí nǹkan bá nira. [Ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ bí títẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lásìkò tí ọrọ̀ ajé ò bá fara rọ.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.
Ilé Ìṣọ́ August 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bẹ̀rù pé ogun runlé-rùnnà tàbí ìyípadà ojú ọjọ́ máa pa ayé run. Ǹjẹ́ o rò pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí. [Ka Ìṣípayá 11:18.] Ìwé ìròyìn yìí dáhùn ìbéèrè mẹ́rin táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa òpin ayé.”
Ji! July–September
“Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì sábà máa ń gbowó lọ́wọ́ àwọn èèyàn tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìrìbọmi, ìgbéyàwó àti ìsìnkú. Ṣé o rò pé ó yẹ kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ìtọ́ni tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. [Ka Mátíù 10:7, 8b.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa gbígba owó nítorí àwọn ààtò ìsìn.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 24 hàn án.