Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ March 1
Ka Ẹ́kísódù 20:15. Kó o wá sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbìyànjú láti pa àṣẹ yìí mọ́, síbẹ̀, àwọn kan rò pé kò burú téèyàn bá jalè tàbí téèyàn bá pa àwọn irọ́ kan nígbà tí kò bá sí ọgbọ́n míì tó lè dá. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa ṣòótọ́ nígbà gbogbo.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 12 hàn án.
Ji! April–June
Ka Ìṣe 17:31a. Kó o wá sọ pé: “Ọjọ́ Ìdájọ́ máa ń ba ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́rù. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì kọ́ wa pé Ọjọ́ Ìdájọ́ máa mú ọ̀pọ̀ ìbùkún bá aráyé. Àlàyé púpọ̀ sí i wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.
Ilé Ìṣọ́ April 1
“Nígbà tí wọ́n ní kí àwọn èèyàn sọ ẹni tí wọ́n kà sí pàtàkì jù lọ nínú ìtàn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló dárúkọ Jésù. Ṣé ìwọ náà gbà bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Jẹ́ ká wo ìdí tó fi yẹ ká mọ èyí tó jẹ́ òótọ́ nínú àwọn èrò tó ta kora táwọn èèyàn ní nípa Jésù. [Ka Jòhánù 17:3.] Àkànṣe ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa Jésù àtàwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀.”
Ji! April–June
“Ìkọ̀sílẹ̀ wọ́pọ̀ gan-an lóde òní. Ǹjẹ́ o rò pé àwọn tọkọtaya tó ń kọ ara wọn sílẹ̀ máa ń ro gbogbo ìṣòro tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ yọ kí wọ́n tó pinnu láti kọ ara wọn sílẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Òwe 14:15.] Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn nǹkan mẹ́rin tó yẹ kí tọkọtaya gbé yẹ̀ wò bí wọ́n bá ń gbèrò láti kọ ara wọn sílẹ̀.”