Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ March 1
“Èrò tí àwọn èèyàn ní nípa Jésù ta ko ara wọn. Ṣé o gbà pé ọmọ Ọlọ́run ni àbí èèyàn rere kan lásán?” Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà kẹ́ ẹ wá jọ ka ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ìbéèrè tá a fi àwọ̀ dúdú kirikiri kọ lójú ìwé 16 sí 17, kó o sì ka ọkàn lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìbéèrè tó kàn pẹ̀lú rẹ̀.
Ji! April–June
“Àwọn kan gbà pé kò pọn dandan kéèyàn ronú jinlẹ̀ nípa ohun tó gbà gbọ́, tó bá ṣáà ti bá a lára mu. Kí lèrò rẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò yẹ kéèyàn kàn gba ohun tó bá ṣáà ti wù ú gbọ́. [Ka 1 Jòhánù 4:1.] Àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 28 jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè rí i dájú pé a ronú jinlẹ̀ nípa ohun tá a gbà gbọ́.”
Ilé Ìṣọ́ April 1
“Oríṣiríṣi nǹkan ni ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ nípa Jésù. Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn mọ òtítọ́ nípa Jésù? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Jòhánù 17:3.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa Jésù, ibi tó ti wá, bó ṣe lo ìgbésí ayé rẹ̀ àti ìdí tó fi kú.”
Ji! April–June
“Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló ń ṣàìsàn, à ń jíròrò ẹsẹ Bíbélì tó ń tuni nínú yìí pẹ̀lú gbogbo èèyàn. [Ka Aísáyà 33:24.] Ǹjẹ́ o kò rí i pé ìgbésí ayé wa á yàtọ̀ gan-an nígbà tí ohun tá a kà yìí bá ní ìmúṣẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Kó tó di ìgbà tí Ọlọ́run máa mú àwọn àyípadà yẹn wá, àwọn ohun kan wà tí gbogbo wa lè máa ṣe tó lè mú kí ara wa túbọ̀ jí pépé. Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àwọn ohun náà.”