Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lo
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù May
“Ǹjẹ́ o ti ṣe kàyéfì rí nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ibi àti ìjìyà? [Jẹ́ kó fèsì.] Mo fẹ́ fi ohun kan tó o máa nífẹ̀ẹ́ sí hàn ẹ́ lórí kókó yìí.” Ẹ jọ ka àwọn ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ lójú ìwé 16 nínú Ilé Ìṣọ́ May 1 àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí wọ́n tọ́ka sí. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ May 1
Ka Sáàmù 37:10, 11. Kó o wá sọ pé: “Ǹjẹ́ o rò pé ìlérí yìí máa ní ìmúṣẹ láìpẹ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ nípa àsọtẹ́lẹ̀ mẹ́fà nínú Bíbélì tí à ń rí ìmúṣẹ wọn báyìí, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ìlérí tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn kò ní pẹ́ ní ìmúṣẹ.”
Ji! April–June
Tó o bá pàdé ọ̀dọ́ kan, fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án. Tọ́ka sí àwọn ìbéèrè tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́, kó o sì béèrè pé, “Ṣé o gbà pé òótọ́ ni àwọn gbólóhùn yìí àbí irọ́? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka 2 Kọ́ríńtì 7:1.] Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò ewu tó wà nínú sìgá mímu tó yẹ kó o mọ̀ àti bí ẹni tó ń mu sìgá ṣe lè jáwọ́ nínú sìgá mímu.”