ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/11 ojú ìwé 4
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 4/11 ojú ìwé 4

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé tá a máa lò ní April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kò tíì máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, ẹ fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Kẹ́ ẹ sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ fún un ní ìwé èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ẹ tún lè lo Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà gẹ́gẹ́ bí àfidípò. July àti August: Ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tí àwọn èèyàn máa ń nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ẹ tún lè lo ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀ níbi tí àwọn Mùsùlùmí bá wà.

◼ Lọ́jọ́ Friday, October 22, 2010, Arákùnrin Stephen Lett, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí, mú odindi Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Ẹ́fíìkì ní àpéjọ àgbègbè tí wọ́n ṣe ní ìlú Awi nítòsí Kàlàba. A lo ẹ̀rọ Íńtánẹ́ẹ̀tì láti ta àsọyé Arákùnrin Lett látagbà sí àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ méjì míì ní Ikot Ekpene àti Uyó lẹ́ẹ̀kan náà. Ní báyìí, a ti ní odindi Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lóríṣi èdè mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ báyìí lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn èdè náà ni Ẹ́fíìkì, Ìgbò àti Yorùbá.

◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù May, kí gbogbo ìjọ máa lo Saturday àkọ́kọ́ nínú oṣù láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A kọ ọwọ́ àwọn àpilẹ̀kọ náà “Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun” kó lè ran àwọn akéde lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ojú ìwé tó gbẹ́yìn Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa kọ̀ọ̀kan á máa ní àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò fún oṣù tó máa tẹ̀ lé e, tó fi mọ́ àbá lórí bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday àkọ́kọ́.

◼ Gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣe ìfilọ̀ tẹ́lẹ̀, Sunday April 17, 2011 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Orin 8 la máa fi bẹ̀rẹ̀, a ó sì fi orin 109 parí, nínú ìwé orin wa tuntun.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́