Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 2
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 2
Orin 99 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 3 ìpínrọ̀ 4 sí 11 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóòbù 38-42 (10 min.)
No. 1: Jóòbù 40:1-24 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Jíjẹ́ Onínú Tútù àti Onísùúrù (5 min.)
No. 3: Ìrìbọmi Kì Í Wẹ Ẹ̀ṣẹ̀ Nù—td 17B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Lo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé yìí láti fi ṣàṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday àkọ́kọ́ lóṣù May. Fún gbogbo àwọn ará ní ìṣírí láti lọ́wọ́ nínú rẹ̀.
15 min: Àwọn Ọ̀ràn Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ. Àsọyé tá a gbé ka ìwé àsọyé tá a pé àkòrí rẹ̀ ní “Àpéjọ Àgbègbè Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2011.”
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Lóṣù May. Ìjíròrò. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì sọ̀rọ̀ lórí ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà. Lẹ́yìn náà, yan àpilẹ̀kọ méjì tàbí mẹ́ta, kó o sì ní kí àwùjọ sọ àwọn ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan.
Orin 91 àti Àdúrà