Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 9
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 9
Orin 58 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 3 ìpínrọ̀ 12 sí 18 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 1-10 (10 min.)
No. 1: Sáàmù 7:1-17 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ọ̀rọ̀ Tó Ní Ìmísí Ọlọ́run Ni Bíbélì—td 8A (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Jésù Fi Sọ fún Ọkùnrin Kan Pé Kó Má Ṣe Pe Òun Ní “Olùkọ́ Rere”—Máàkù 10:17, 18 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Àwa Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣàkóso Dípò Àwọn Ènìyàn. (Ìṣe 5:29) Ìjíròrò tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ January 15, 2006 ojú ìwé 8 sí 9. Lẹ́yìn tó o bá ti jíròrò ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ní kí àwọn ará sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
10 min: Ǹjẹ́ O Lè Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ ní Àkókò Ìsinmi? Ìjíròrò. Ní ṣókí, jíròrò àwọn ohun tí à ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ bó ṣe wà nínú ìwé A Ṣètò Wa, lójú ìwé 112 sí 113. Ní kí àwọn tó ti fi àkókò ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tàbí ní ilé ẹ̀kọ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ sọ àwọn ìbùkún tí wọ́n ní.
10 min: “‘Ẹ Jẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn.’” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní kí àwọn ará sọ bí ìwà rere wọn ṣe mú kí wọ́n lè jẹ́rìí fáwọn èèyàn.
Orin 93 àti Àdúrà