Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù July
“Láti bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn báyìí, ọ̀pọ̀ èèyàn túbọ̀ ń fẹ́ láti mọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì. Ǹjẹ́ o gbà pé àwọn áńgẹ́lì wà lóòótọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí ohun tí ibí yìí sọ.” Fún onílé ní Ilé Ìṣọ́ July 1, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àwọn ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ lójú ìwé 16 àti ọ̀kan lára ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n tọ́ka sí, ó kéré tán. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ July 1
Ka Sáàmù 65:2. Kó o wá sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ló gbà pé Ọlọ́run jẹ́ ‘Olùgbọ́ àdúrà,’ torí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe máa ń gbàdúrà lójoojúmọ́. Àmọ́, àwọn míì máa ń ronú pé, ‘Tí Ọlọ́run bá wà lóòótọ́, kí nìdí tí ìṣòrò fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ láyé?’ Kí lèrò tìẹ? Ṣé Ọlọ́run kan wà tó ń gbọ́ àdúrà wa? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ìdáhùn Bíbélì sí ìbéèrè náà: ‘Kí nìdí tí Olùgbọ́ àdúrà fi fàyè gba ìjìyà?’”
Ji! July–September
“Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló ń kó àìsàn látinú oúnjẹ eléwu tí wọ́n ń jẹ. Lójú tiẹ̀, ǹjẹ́ oúnjẹ tá à ń jẹ ládùúgbò wa yìí léwu tàbí kò léwu? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àwọn nǹkan mẹ́rin tá a lè ṣe láti dáàbò bo ìdílé wa lọ́wọ́ àìsàn téèyàn ń kó látinú oúnjẹ. Ó tún sọ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì pé láìpẹ́ gbogbo èèyàn á máa jẹ̀gbádùn ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ aṣaralóore.” Ka Sáàmù 104:14, 15.