Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Àwọn akéde tó ròyìn lóṣù December 2011 jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ àti irinwó lé mẹ́rìndínlógójì [308,436]. Ìyẹn sì fi ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lè mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [13,627] ju àwọn akéde tó ròyìn lóṣù December 2010 lọ. Àwọn akéde yìí lo wákàtí mílíọ̀nù márùn-ún, ẹgbẹ̀rún márùnlélọ́gọ́rin ó dín mẹ́tàdínlógún [5,084,977] nínú iṣẹ́ ìwàásù. Èyí wúni lórí gan-an ni, pàápàá tá a bá fi sọ́kàn pé ọ̀pọ̀ ìjọ ló ṣì ń ṣe àpéjọ àgbègbè wọn lóṣù yẹn.