Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 9
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 9
Orin 78 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 23 ìpínrọ̀ 9 sí 15, àti àpótí tó wà ní ojú ìwé 184 àti 186 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 11-14 (10 min.)
No. 1: Ìsíkíẹ́lì 11:14-25 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ǹjẹ́ Ó Tọ́ Ká Máa Pe Màríà Ní ‘Ìyá Ọlọ́run’?—td 23A (5 min.)
No. 3: Kí Ni Ọkàn Tútù, Báwo Ló Sì Ṣe Lè Jẹ́ Ká Ní Èrò Tó Tọ́?—Sef. 2:3 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
15 min: Máa Ṣe Ìpadàbẹ̀wò Tó Múná Dóko. Ìjíròrò tá a gbé ka àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí: (1) Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ohun kan pàtàkì lọ́kàn tá a fẹ́ ṣe ní gbogbo ìgbà tá a bá pa dà lọ bẹ àwọn èèyàn wò? (2) Báwo la ṣe lè ṣàlàyé irú ẹni tá a jẹ́ nígbà tá a bá pa dà lọ? (3) Kí la lè sọ tí ẹni tá a lọ bẹ̀ wò bá ní òun kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa? (4) Tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tá a fún ní ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé pẹlẹbẹ tàbí ìwé ìròyìn, ìgbà wo ni a lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, báwo la sì ṣe lè bẹ̀rẹ̀? (5) Báwo la ṣe lè mú kí ẹnì kan nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa tó bá ń ṣòro fún wa láti bá ẹni náà nílé nígbà ìpadàbẹ̀wò? (6) Báwo la ṣe lè dá àwọn akéde tí kò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí lẹ́kọ̀ọ́ nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò?
15 min: “Kí Ni Ìdí Tó O Fi Ní ‘Ayọ̀ Ńláǹlà’?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, fún gbogbo àwọn ará níṣìírí láti máa ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn lóṣooṣù. Ṣe àlàyé àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 88 sí 90.
Orin 9 àti Àdúrà