Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá wàásù fún ẹnì kan. Bí onílé bá ti ní ìwé náà, tí kò sì fẹ́ kí á wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹ lè fún un ní àwọn ìwé ìròyìn tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ tàbí ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí onílé nífẹ̀ẹ́ sí. July àti August: Ẹ lo ọ̀kan lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú-ewé 32 wọ̀nyí: Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, àti Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! kẹ́ ẹ́ sì gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, ẹ lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí kẹ́ ẹ fún un ní ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa nífẹ̀ẹ́ sí. September: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò ẹ lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí kẹ́ ẹ fún un ní èyí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa nífẹ̀ẹ́ sí nínú ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀.
◼ A rọ gbogbo yín pé kẹ́ ẹ wo fídíò Our Whole Association of Brothers. Tẹ́ ẹ bá nílò rẹ̀, ẹ lè béèrè fún un nípasẹ̀ ìjọ.
◼ Èyí ni láti sọ fún yín pé àdírẹ́sì ìfìwéránṣẹ́ tuntun tá à ń lò báyìí ní Ọ́fíìsì wa tuntun tó wà ní Ikeja ni P.M.B. 21845, Alausa 100212, Ikeja, Lagos State.