Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 2
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 2
Orin 116 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 23 ìpínrọ̀ 1 sí 8, àti àpótí tó wà lójú ìwé 180 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 6-10 (10 min.)
No. 1: Ìsíkíẹ́lì 7:14-27 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Ni Jónátánì Ṣe Jẹ́ Àpẹẹrẹ Àtàtà Nípa Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀?—1 Sám. 23:16-18 (5 min.)
No. 3: Ìyàwó Kan Ṣoṣo Ni Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Máa Ń Fẹ́—td 19Ẹ (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Bá A Ṣe Lè Fèrò Wérò Pẹ̀lú Àwọn Tí À Ń Wàásù Fún—Apá 1. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ojú ìwé 251 sí ojú ìwé 253, ìpínrọ̀ 2. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn kókó kan tàbí méjì látinú àpá yìí.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù July. Ìjíròrò. Yan àpilẹ̀kọ méjì tàbí mẹ́ta, kó o wá fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan sọ ìdí táwọn èèyàn fi máa nífẹ̀ẹ́ sí wọn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ July, ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn, kí wọ́n sì sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! July–September 2012, tí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
Orin 31 àti Àdúrà