Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní June 25, 2012. A fi déètì ọ̀sẹ̀ tá a máa jíròrò kókó kọ̀ọ̀kan sínú àwọn ìbéèrè náà, kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣèwádìí nípa wọn nígbà tá a bá ń múra ìpàdé ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
1. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú bí Jèhófà ṣe dá Jeremáyà sí lákòókò tí jíjẹ àti mímu di ìṣòro nílùú? (Jer. 37:21) [May 7, w97 9/15 ojú ìwé 3 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 1]
2. Báwo ni àwọn Kristẹni tó nírètí àtijogún ayé ṣe lè fara wé àpẹẹrẹ rere Ebedi-mélékì? (Jer. 38:8-13) [May 7, su ojú ìwé 179 ìpínrọ̀ 9]
3. Níwọ̀n bí Jèhófà ti lo àwọn ẹ̀ṣọ́ Nebukadirésárì láti dáàbò bo Jeremáyà àti Bárúkù, ǹjẹ́ ó bójú mu pé kí àwọn Kristẹni gbà kí àwọn ọlọ́pàá tó ń gbé ìbọn máa dáàbò bo àwọn? (Jer. 39:11-14) [May 14, w84 1/15 ojú ìwé 31]
4. Àwọn “ohun ńláńlá” wo ló ṣeé ṣe kí Bárúkù ti máa wá fún ara rẹ̀, kí lohun tó sì yẹ ká fi sọ́kàn látàrí bó ṣe fetí sí ìmọ̀ràn Jèhófà? (Jer. 45:5) [May 21, w06 8/15 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 1; ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 6]
5. Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa ìyà tó tọ́ tóun máa fi jẹ Édómù, kí ló mú kó fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí òun máa ṣe àti èyí ti “àwọn olè” àti “àwọn olùkó èso àjàrà” máa ń ṣe? (Jer. 49:9, 10) [May 28, w78 1/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 3 àti 4]
6. Ẹ̀kọ́ tó ń múni ronú jinlẹ̀ wo la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ọba Sedekáyà lẹ́yìn tó “tẹ̀ síwájú láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Bábílónì”? (Jer. 52:3, 7-11) [June 4, w88 9/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 8; w81 10/1 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 3 àti 4; ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 6]
7. Kí ni “àpótí ìtìsẹ̀” Jèhófà àti “àtíbàbà” rẹ̀? (Ìdárò 2:1, 6) [June 11, w07 6/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 2]
8. Kí ni Jeremáyà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ọkàn Jèhófà “yóò rántí, yóò sì tẹ̀ ba mọ́lẹ̀ lórí” òun, kí sì nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì gan-an sí wa? (Ìdárò 3:20) [June 18, w07 6/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 3]
9. Kí nìdí tó fi ṣàǹfààní pé kéèyàn mọ bó ṣe lè ru àjàgà ìnira nígbà ọ̀dọ́? (Ìdárò 3:27) [June 18, w07 6/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 5; g89 11/22 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 3]
10. Báwo ni àpẹẹrẹ Ìsíkíẹ́lì ṣe lè mú ká máa fìgboyà sọ̀rọ̀ kódà tí àwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń dágunlá sí ọ̀rọ̀ wa? (Ìsík. 3:8, 9) [June 25, w08 7/15 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 6 àti 7]