Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 25
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 25
Orin 63 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 22 ìpínrọ̀ 15 sí 21 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìsíkíẹ́lì 1-5 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Fi àbá tó wà lójú ìwé 4 ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo àwọn ìwé ìròyìn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday àkọ́kọ́ lóṣù July.
15 min: Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Rẹ Lóde Ẹ̀rí. (Éfé. 5:15, 16) Ìjíròrò. Ló àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí. (1) Báwo la ṣe lè fọgbọ́n lo àkókó wa nígbà (a) tá a bá ń darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá? (b) tí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá bá parí? (d) tí ọ̀kan lára àwọn tá a jọ jáde bá rí ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn tí wọn ò sì tíì parí ọ̀rọ̀ wọn? (e) tí ilé àwọn tá a fẹ́ padà lọ bẹ̀ wò bá jìnnà síra? (2) Báwo la ò ṣe ní fi àkókò ṣòfò (a) tí àwa àti ìdílé wa bá ti jẹun ká tó lọ síbi tá a ti ń pàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá? (b) tí ẹsẹ̀ gbogbo wa bá ti pé kí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá tó bẹ̀rẹ̀? (d) tá a bá fiyè sí olùdarí nígbà tó ń pín àwọn èèyàn àti ibi tí wọ́n ti máa ṣiṣẹ́, tí kò sì sí pé à ń tún àwọn èèyàn pín lẹ́yìn tí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ti parí? (e) tí gbogbo wa bá ti mọ ibi tá a ti máa siṣẹ́ ká tó kúrò níbi tá a ti ṣèpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá?
10 min: Ìwé Tá A Máa Lò Lóṣù July. Ìjíròrò. Sọ àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ìwé tá a máa lò, kó o sì ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì.
Orin 29 àti Àdúrà