ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/12 ojú ìwé 2
  • Àpòtí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpòtí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọgbọ́n àti Àǹfààní Ṣíṣètò Dúkìá Ẹni
    Jí!—1999
  • Báwọn Òbí Mi Ò Bá Lówó Ńkọ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Ní Ẹ̀mí Ìmúratán
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Mọrírì Ìwà Ọ̀làwọ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
km 6/12 ojú ìwé 2

Àpòtí Ìbéèrè

◼ Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ kí díẹ̀ lára ogún wa tàbí kí gbogbo ẹ jẹ́ ti ètò Jèhófà lẹ́yìn tá a bá kú?

Bí àwa èèyàn bá ti kú a ò ní agbára kankan lórí àwọn ohun ìní wa mọ́. (Onw. 9:5, 6) Torí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń ṣe àkọsílẹ̀ bí wọ́n ṣe fẹ́ kí wọ́n pín ogún àwọn. (2 Ọba. 20:1) Lára ohun tó sábà máa ń wà nínú àkọsílẹ̀ tó la ọ̀ràn òfin lọ yìí ni orúkọ ẹni tí èèyàn fẹ́ kó ṣètò pínpín ogún. Bí ẹnì kan kò bá ṣe irú àkọsílẹ̀ yìí, ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ìjọba ló máa ń pinnu bí wọ́n ṣe máa pín ogún olóògbé náà. Torí náà, tá a bá ní ohun kan lọ́kàn nípa bá a ṣe fẹ́ kí wọ́n pín ogún wa, bóyá ńṣe la fẹ́ kí díẹ̀ tàbí gbogbo rẹ̀ jẹ́ ti ètò Jèhófà, ó ṣe pàtàkì pé ká ṣe àkọ́sílẹ̀ kan tó bófin mu láti ṣàlàyé ohun tá a fẹ́, ká sì fara balẹ̀ yan ẹni tá a fẹ́ kó ṣètò pínpín ogún náà.

Bí wọ́n bá yan ẹnì kan láti bójú tó pínpín ogún, kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá. Bí ohun ìní onítọ̀hún bá ṣe pọ̀ tọ́ ló máa pinnu bí iṣẹ́ náà á ṣe pọ̀ tó. Ó máa pọn dandan pé kí ẹni tí wọ́n yàn náà kọ́kọ́ ṣètò àwọn ohun ìní olóògbé pa pọ̀ kó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá pín wọn, èyí sì lè gba pé kí ó ṣe àwọn wàhálà kan, ó sì máa gba àkókò rẹ̀. Bákan náà, ó gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àwọn òfin kan tí ìjọba sábà máa ń ṣe lórí ọ̀ràn ogún pínpín. Ti pé ẹnì kan wà nínú ìjọ Kristẹni kì í ṣe ẹ̀rí pé ó lè ṣe àbójútó pínpín ogún. Ẹni tá a máa yàn gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó lè ṣe irú wàhálà bẹ́ẹ̀, tó ṣeé fọkàn tán, tó sì ṣe tán láti tẹ̀ lé ohun tá a fẹ́.—Wo àpilẹ̀kọ náà “Ọgbọ́n àti Àǹfààní Ṣíṣètò Dúkìá Ẹni,” nínú Jí! January 8, 1999.

Bí Wọ́n Bá Ní Kó O Ṣètò Pínpín Ogún: Bí ẹni kan bá ní kó o bá òun ṣètò pínpín ogún lẹ́yìn ikú òun, ńṣe ni kó o kọ́kọ́ ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa, kó o sì gbàdúrà nípa rẹ̀ kó o lè mọ̀ bóyá agbára rẹ á gbé e láti ṣe iṣẹ́ náà. (Lúùkù 14:28-32) Lẹ́yìn ikú onítọ̀hún, o gbọ́dọ̀ sọ fún gbogbo àwọn tí orúkọ wọn wà lákọsílẹ̀ pé wọ́n máa pín nínú ogún náà. Nígbà tó jẹ́ pé àṣẹ ti wà lọ́wọ́ rẹ báyìí, ojúṣe rẹ ni láti pín ogún náà níbàámu pẹ̀lú òfin àti níbàámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú ìwé ìhágún náà. Ó yẹ kí ẹni tó máa ṣètò pínpín ogún náà mọ̀ pé bóyá ohun ìní olóògbé náà pọ̀ ni tàbí ó kéré, òun kò ní òmìnira kankan láti yí ohunkóhun pa dà. Bí olóògbé bá ní kí á pín ohunkóhun fún àjọ kan tá a fi òfin gbé kalẹ̀ tó jẹ́ ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun tá a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ètò Jèhófà sì ló ni ín—Lúùkù 16:10; 21:1-4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́