ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 1/8 ojú ìwé 16-19
  • Ọgbọ́n àti Àǹfààní Ṣíṣètò Dúkìá Ẹni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọgbọ́n àti Àǹfààní Ṣíṣètò Dúkìá Ẹni
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ìṣètò Dúkìá?
  • Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Ṣe
  • Ta Ló Lè Ṣèrànwọ́?
  • Àpòtí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Wọn Ṣe Ohun Ti Wọn Lè Ṣe
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Gbogbo Wọn Ń Fi “Ọkàn Kan” Sin Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Bí Àwọn kan Ṣe Ń Ṣe Ìtọrẹ Fún Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Náà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 1/8 ojú ìwé 16-19

Ọgbọ́n àti Àǹfààní Ṣíṣètò Dúkìá Ẹni

TỌKỌTAYA Petersons ní ìjákulẹ̀.a Wọ́n ti gbẹ́kẹ̀ lé owó tí wọ́n bá rí lórí àwọn dúkìá wọn tí wọ́n fẹ́ tà láti máa fi gbọ́ bùkátà wọn lẹ́yìn ìfẹ̀yìntì, àti níkẹyìn láti fi nínú rẹ̀ ra ẹ̀bùn tó gbámúṣé fún àwọn ọmọ wọn. Àwọn ohun tí wọ́n fojú sọ́nà fún yẹn forí ṣánpọ́n nígbà tí owó orí tí a bù lé owó ilé tí wọ́n tà náà kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ.

Tọkọtaya Smith pẹ̀lú ní àwọn dúkìá tí ìníyelórí rẹ̀ ti gbé pẹ́ẹ́lí bí ọdún ti ń gorí ọdún. Nípasẹ̀ àkànṣe ètò tí wọ́n ṣe lórí títa àwọn dúkìá náà, wọ́n ṣètò fún owó tí wọn óò máa fi gbọ́ bùkátà lẹ́yìn ìfẹ̀yìntì, ẹ̀bùn gbígbámúṣé fún àwọn ọmọ wọn, àti iye kan fún ọrẹ àánú tí wọ́n fẹ́ràn láti máa ṣe.

Ìdààmú ńlá bá Rose Jones. Gbàrà tí ọkọ rẹ̀ kú ikú àìtọ́jọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí rí àwọn ìwé tí kò mọ bí wọ́n ṣe jẹ́ gbà láti ọ̀dọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìjọba àpapọ̀. John tí í ṣe ọkọ rẹ̀ ló sábà máa ń bójú tó ọ̀ràn ìnáwó wọn, títí kan sísan owó orí, gbígba ẹ̀rí ìbánigbófò ẹ̀mí, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó sábà máa ń sọ fún aya rẹ̀ pé kó má ṣèyọnu—“gbogbo nǹkan ń lọ dáradára.” Àmọ́ níwọ̀n bí ọkùnrin náà kò ti ṣe ìwé ìhágún sílẹ̀ kó tó kú, díẹ̀ lára àwọn dúkìá tí obìnrin náà gbára lé pé yóò máa mú owó wá ni kò lè rí nǹkan kan láti inú wọn ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Wọ́n gbà á nímọ̀ràn pé kí ó gba agbẹjọ́rò kan tí yóò ràn án lọ́wọ́ láti wádìí iye dúkìá tí ọkọ rẹ̀ fi sílẹ̀ àti ohun tí yóò ṣe tí wọn ó fi yí wọn sí orúkọ rẹ̀. Wọ́n tún sọ fún un pé lọ́nà òfin, díẹ̀ lára àwọn dúkìá náà yóò di ti àwọn ọmọ tí ìyàwó àárọ̀ ọkọ rẹ̀ bí fún un, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé obìnrin náà mọ̀ pé kò sí lọ́kàn ọkọ òun láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àìmọ ohun tí yóò ṣe àti ìdààmú nípa ohun tí yóò gbà láti mú kí nǹkan gún régé padà wulẹ̀ tún ń mú kí kíkojú ìnira jíjẹ́ opó túbọ̀ máa burú sí i ni.

Ìbànújẹ́ ikú ọkọ láìtọ́jọ́ bá Mary Brown pẹ̀lú. Mímọ̀ pé ọkọ rẹ̀ ti ṣe ètò dáradára nípa ìpèsè ìbánigbófò ẹ̀mí tí yóò jẹ́ kí òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì lè rówó ná tù ú nínú díẹ̀. Ó tún mọ èyí tí yóò di tirẹ̀ lára àwọn dúkìá wọn ní gbàrà tí ọkọ rẹ̀ kú àti àwọn dúkìá tí yóò máa dọ́wọ́ rẹ̀ nítorí ohun tó wà nínú ìwé ìhágún tí ọkọ rẹ̀ ṣe. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gbìyànjú láti mú ara rẹ̀ bá ipò opó mú, inú rẹ̀ dùn gan-an fún ìgbatẹnirò tí ọkọ rẹ̀ lò nínú ìṣètò àwọn àlámọ̀rí rẹ̀, tó fi jẹ́ pé òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ máà ní ìṣòro owó nígbà tó kú.

Kí ló mú kí ọ̀ràn tọkọtaya Smith àti Mary Brown yàtọ̀? Ìṣètò dúkìá ẹni.

Kí Ni Ìṣètò Dúkìá?

Ìṣètò dúkìá jẹ́ ìgbésẹ̀ pípinnu bí a ó ṣe pín ogún rẹ nígbà tí o bá kú, kí o sì gbé ìgbésẹ̀ láti mú àwọn ìpinnu rẹ ṣẹ lọ́nà tó gbéṣẹ́, tó sì mú ìṣọ́ra lọ́wọ́. Irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè kan fífi orúkọ ra àwọn dúkìá lábẹ́ òfin, dídárúkọ àwọn tí yóò jogún nǹkan, àti ṣíṣe àwọn ìwé bí àwọn ìwé ìhágún àti ohun-ìní ìfisíkàáwọ́. Nínú àwọn ipò tó díjú, yóò ní nínú ju ìyẹn lọ.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn kò ní jiyàn lórí ọgbọ́n tó wà nínú ṣíṣe irú ètò bẹ́ẹ̀, àwọn díẹ̀ kéréje ló ti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó yani lẹ́nu pé ìpín àádọ́rin lára àwọn àgbàlagbà tó wà ní United States ni kò tíì ṣe ìwé ìhágún wọn! Àwáwí tí wọ́n sábà máa ń ṣe ni pé: “Ọwọ́ mi dí gan-an; Màá ṣe é láìpẹ́.” “N kò ní owó tó pọ̀, n kò sì ní dúkìá tí mo lè fi sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.” “N kò ní agbẹjọ́rò.” “N kò fẹ́ máa ronú nípa ikú mi.” “N kò mọ ibi tí mo ti máa bẹ̀rẹ̀.”

Òtítọ́ ni pé èrò nípa ṣíṣètò dúkìá ẹni lè máa dẹ́rù bani. Ṣùgbọ́n kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Àtibẹ̀rẹ̀ sábà máa ń jẹ́ kìkì ọ̀ràn ṣíṣètò ara ẹni, kí o sì lóye ìpinnu tó wà níwájú rẹ. Bí ti ọ̀pọ̀ nǹkan, ṣíṣètò dúkìá kò ṣòro tí a bá pín in sí ìsọ̀rí ìsọ̀rí, tí a sì yanjú rẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan.

Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Ṣe

Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni pé kí o ṣàkọsílẹ̀ dúkìá rẹ. Kì í ṣe kí o kàn kọ àwọn ohun tí o ní ṣùgbọ́n kí o kọ iye tí dúkìá kọ̀ọ̀kan tó àti bí wọ́n ṣe di tìrẹ àti orúkọ tí ẹ fi rà á. (Wo àpótí náà, “Àkọsílẹ̀ Gbogbo Dúkìá.”) A lè pín èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn dúkìá sí ìsọ̀rí bí àwọn ẹ̀rí jíjẹ́ oníǹkan (owó ìdókòwò, owó ìdúró, owó àjọdá), dúkìá ilẹ̀ tàbí ilé (ilé rẹ, ohun ìní tí o fi háyà tàbí tí o fi dókòwò), àkáǹtì tí o ní ní báńkì (àkáǹtì oníwèé ìfowópamọ́, àkáǹtì onísọ̀wédowó, owó ìṣòwò oníwèé ẹ̀rí), ohun ìní ara ẹni (àkójọ ohun ìpàtẹ, iṣẹ́ ọnà, àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ara, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ohun ẹ̀ṣọ́ àfitolé), ìbánigbófò ẹ̀mí; owó ìfẹ̀yìntì, àti àwọn òwò. Lẹ́yìn kíkọ àwọn ohun tí o ní sílẹ̀, kọ àwọn gbèsè tí o jẹ, bí àwọn ohun àfidúró, owó tí o yá, àwọn ìwé àdéhùn láti san gbèsè, àti iye tí o ní san lórí káàdì ìrajà àwìn. Yíyọ àwọn gbèsè wọ̀nyí kúrò nínú àròpọ̀ àwọn dúkìá rẹ yóò fi gbogbo ohun tí o ní hàn. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, a máa ń bu owó orí lé ohun tó bá di ti ẹlòmíràn lẹ́yìn ikú ẹnì tó ni ín. Iye owó orí tí wọn óò bù lé e sinmi lé iye tí gbogbo dúkìá tí a kó fún ẹlòmíràn náà jẹ́, nítorí náà iye gbogbo dúkìá rẹ jẹ́ fígọ̀ pàtàkì tí o ní láti mọ̀.

Ìgbésẹ̀ kejì ni láti wo àwọn lájorí ìlépa rẹ—kì í ṣe ní ti iye owó, àmọ́ ní ti ohun tí o fẹ́ ṣàṣeparí rẹ̀ fún ara rẹ àti àwọn tí yóò jogún rẹ. Bí ó ti máa ń rí, ẹni tó ti ṣègbéyàwó yóò fẹ́ láti fọkàn ọkọ tàbí aya rẹ̀ balẹ̀. Òbí kan lè fẹ́ láti pèsè ìwọ̀n ìfọ̀kànbalẹ̀ ní ti owó fún àwọn ọmọ rẹ̀. Ọmọ kan tó ti dàgbà lè fẹ́ láti ṣètò fún àbójútó òbí kan tó ti darúgbó. Láfikún, o lè fẹ́ láti rántí àwọn ọ̀rẹ́ kan tàbí àwọn ìṣètò ọrẹ àánú kan nínú ìṣètò dúkìá rẹ. Ó ṣe pàtàkì láti kọ orúkọ àwọn tí ìwọ yóò pín dúkìá rẹ fún àti ohun tí o ń wéwèé fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.

Má ṣe gbàgbé láti ronú nípa onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ tí ó lè nípa lórí ìṣètò dúkìá rẹ. Fún àpẹẹrẹ, bó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹni tí yóò jogún náà kú ṣáájú rẹ ńkọ́? Ṣé wàá kó ogún náà fún ọkọ tàbí aya rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ tàbí ẹlòmíràn?

Ìgbésẹ̀ kẹta ni láti yan àwọn tó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ tí yóò bá ọ mú ìpinnu rẹ ṣẹ. A sábà máa ń nílò baba-ìsìnkú àti bóyá aláṣẹ̀yìndè òkú àti amòfin tí yóò rí sí ètò ìpíngún. Ẹni yòówù kí o yàn, ní ẹlòmíràn nílẹ̀ tó lè rọ́pò ẹni náà bí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀, kí o sì rí i dájú pé olúkúlùkù ẹni tí o bá yàn yóò múra tán láti ṣe iṣẹ́ náà. Baba-ìsìnkú ni yóò kó gbogbo dúkìá rẹ jọ lẹ́yìn ikú rẹ, yóò bójú tó ọ̀ràn òfin àti ti fífìdí ìjótìítọ́ àwọn àkọsílẹ̀ èyíkéyìí múlẹ̀, yóò sì wá pín ogún rẹ bí o ṣe fẹ́. Ẹbí ẹni ló sábà máa ń dára jù kí a fi ẹrù iṣẹ́ yìí lé lọ́wọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè yàn láti gbé iṣẹ́ náà fún ilé iṣẹ́ bí ẹ̀ka abánibójútó-ǹkan ní báǹkì kan bí ọ̀ràn rẹ bá ní ìṣòro nínú. O gbọ́dọ̀ kọ orúkọ aláṣẹ̀yìndè òkú sínú ìwé ìpíngún rẹ láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ dàgbà bó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ àti aya tàbí ọkọ rẹ kú nígbà tí àwọn ọmọ yín ṣì kéré. Bí ètò tí o ń ṣe bá kan kí àwọn ọmọ rẹ ní abánibójútó-ǹkan, o lè fi orúkọ aláṣẹ̀yìndè òkú náà síbẹ̀ bí abánibójútó-ǹkan, ìyẹn tí ó bá mọ bí a ṣe ń ṣètò ìnáwó. Bí aláṣẹ̀yìndè òkú náà kò bá mọ bí a ṣe ń ṣètò ìnáwó, a lè fi orúkọ ilé iṣẹ́ kan bí ẹ̀ka abánibójútó-ǹkan ní báǹkì síbẹ̀ bí èyí tí yóò nìkan báni bójú tó nǹkan ẹni tàbí kí ó ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú aláṣẹ̀yìndè òkú náà.

Ìgbésẹ̀ kẹrin ni láti lóye ohun èlò tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí ìpinnu rẹ. Ṣé ẹ̀bùn kan lo fẹ́ fún ẹnì kan, àbí ìwọ yóò kúkú fi ohun ìní sábẹ́ àbójútó ẹnì kan fún àǹfààní ẹni yẹn? Ìyàtọ̀ ńlá kan wà. Tí o bá fi ohun ìní sílẹ̀, ìfẹ́ tí o ní nínú dúkìá yẹn yóò dópin tí o bá kú. Àmọ́, lẹ́yìn ikú rẹ pàápàá, o ṣì ní àkóso díẹ̀ lórí ohun ìní tí o fi sílẹ̀ fún ẹnì kan láti bójú tó. Abánibójútó-ǹkan tí o fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀ yóò bójú tó dúkìá náà, yóò sì lò ó fún àǹfààní ẹni tí yóò jogún rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́ni inú àdéhùn ìbánibójútó-nǹkan-ẹni. Fún àpẹẹrẹ, àdéhùn bíbójú tó nǹkan ẹni lè ní bíbójú tó àwọn ọmọ tí wọ́n ṣì kéré gan-an nínú, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n nílò lẹ́nìkọ̀ọ̀kan, kí ó wá sọ iye ọdún tí ọmọ kọ̀ọ̀kan yóò pé tí yóò fi gba ohun ìní tó wà nínú àdéhùn bíbójú tó nǹkan ẹni náà.

Ta Ló Lè Ṣèrànwọ́?

Tí ó bá ṣeé ṣe nínú gbogbo ọ̀ràn, ó yẹ kí o bá ẹnì kan tí ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣètò dúkìá sọ̀rọ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kí o lè lóye àwọn ohun èlò tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú àwọn ìpinnu rẹ ṣẹ. Ó yẹ kí o wéwèé ìṣètò dúkìá rẹ lọ́nà tí yóò bá àwọn góńgó pàtàkì tí o ní àti ipò rẹ mu. O lè nílò ìrànlọ́wọ́ onírúurú àwọn olùgbaninímọ̀ràn bí aṣírò owó, elétò ìnáwó, àti aṣojú ilé iṣẹ́ ìbánigbófò tí o bá ń ṣètò dúkìá rẹ. Bí ìṣètò dúkìá rẹ bá ní fífúnni ní ọrẹ àánú nínú, o lè gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọ̀fẹ́ fún ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ ẹ̀ka ìfúnni ní ọrẹ àánú tí a wéwèé. Fún àpẹẹrẹ, Ẹ̀ka Ìfúnni Ní Ọrẹ Àánú Tí A Wéwèé ti Watch Tower Bible and Tract Society, ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n bá fẹ́ fi Society sínú ètò tí wọ́n ń ṣe nípa dúkìá wọn. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ti jàǹfààní nínú ìpèsè yìí nípa gbígba àbá tí ó ṣe kedere nípa bí wọ́n ṣe lè ṣètò àlámọ̀rí wọn dáradára kí owó orí tí wọn ó san má bàa pọ̀ jù, kí àǹfààní tí yóò ṣẹ́ kù fún àwọn olólùfẹ́ wọn àti Society lè pọ̀.b

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn lè lọ́wọ́ nínú àwọn ìpele ìṣètò náà, jẹ́ kí amòfin kan tí ó jẹ́ ògbóǹtagí nínú ìṣètò dúkìá ṣe àṣekágbá ètò dúkìá rẹ àti àwọn ìwé tó pọndandan. Má ṣe lọ́ra láti béèrè lọ́wọ́ olùgbaninímọ̀ràn èyíkéyìí nípa ohun tó mọ̀ àti ìrírí tó ti ní nínú ṣíṣètò dúkìá. Ní pàtàkì, bí ohun kan bá ń jẹ ọ́ lọ́kàn, bí gbígbé òwò kan fún ìdílé rẹ tàbí bíbójú tó ẹbí kan tí ó jẹ́ abirùn, béèrè lọ́wọ́ olùgbaninímọ̀ràn náà bí ó bá ti nírìírí irú ohun bẹ́ẹ̀ rí. Nínú gbogbo ohun tó bá ṣẹlẹ̀, ní kí ó ṣàlàyé iye tí owó iṣẹ́ náà yóò jẹ́, kí o sì ṣàkọsílẹ̀ àdéhùn yìí.

Ìṣètò dúkìá jẹ́ ọ̀ràn tí ó léwu tí a kò bá ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀ nípa rẹ̀. Gbé àpèjúwe tọkọtaya, tí a óò pè ní Paul àti Mary, yẹ̀ wò. Wọ́n fẹ́ pín gbogbo ohun ìní wọn fún àwọn ọmọbìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lọ́gbọọgba. Níwọ̀n bí ọmọbìnrin wọn tí ń jẹ́ Sarah ti ń gbé ìtòsí wọn, wọ́n pinnu láti fi orúkọ rẹ̀ kún tiwọn, wọ́n kọ orúkọ rẹ̀ mọ́ orúkọ tó wà lórí àwọn dúkìá wọn. Wọ́n ronú pé, ‘lọ́nà yìí, Sarah yóò lè bójú tó dúkìá wá bí a kò bá lágbára àtiṣe-ǹkan mọ́. Láfikún, kíkọ orúkọ Sarah mọ́ orúkọ tó máa ń wà lára gbogbo nǹkan wọn túmọ̀ sí pé òun nìkan ni yóò ni gbogbo rẹ̀ nígbà tí a bá kú, a kò sì ní nílò ìwé ìhágún tàbí àkọsílẹ̀ fífìdí ìjótìítọ́ nǹkan múlẹ̀. Ó wulẹ̀ lè pín ohun tó ṣẹ́ kù pẹ̀lú àwọn arábìnrin rẹ̀ lẹ́yìn tí a bá kú.’

Ṣùgbọ́n nǹkan kò já sí bí Paul àti Mary ṣe wéwèé. Lẹ́yìn tí àwọn òbí Sarah kú, ó pín àwọn dúkìá wọn láàárín òun àti àwọn arábìnrin rẹ̀, àmọ́ fífà wọ́n lé wọn lọ́wọ́ mú kí wọ́n bu owó orí tí ó mú kí ìpín tirẹ̀ dín kù gan-an lé e. Yàtọ̀ sí ìyẹn, jíjẹ́ tí Sarah bá wọn jẹ́ oníǹkan kò fún un ní gbogbo agbára àbójútó tí àwọn òbí rẹ̀ fẹ́ kí ó ní. Paul àti Mary ní èrò rere lọ́kàn. Wọ́n fẹ́ rí i dájú pé a óò bójú tó wọn bí àwọn kò bá lágbára àtiṣe-ǹkan mọ́. Wọ́n kò tún fẹ́ kí ètò fífa àwọn dúkìá wọn lé àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ gbówó lórí. Àmọ́, wọ́n gba ọ̀nà tí kò tọ́ láti mú àwọn ìpinnu wọn ṣẹ.

Ṣíṣètò dúkìá rẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tí o máa gbé yẹ̀ wò lẹ́ẹ̀kan péré. Àyẹ̀wò látìgbàdégbà pọndandan nítorí àwọn òfin owó orí máa ń yí padà, àwọn òfin lórí ogún máa ń yí padà, ipò nǹkan sì máa ń yí padà nínú ìgbésí ayé. Ikú ẹbí kan, ọmọ-ọmọ kan tí a bí, ogún tí a jẹ, àti dúkìá tí ń pọ̀ sí i jẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó lè mú kí o fẹ́ láti ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìwéwèé rẹ.

Lótìítọ́, iṣẹ́ ńlá ni ọ̀ràn ṣíṣètò dúkìá jẹ́. Ó ń gba àkókò, agbára, àti ìfọkànsìn. Ó sì máa ń kan ṣíṣe àwọn ìpinnu tó ṣòro. Ọ̀ràn ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ gbáà ni ọ̀ràn ṣíṣètò dúkìá kan jẹ́. Ó kan àwọn ènìyàn àti àwọn ọ̀ràn tí o bìkítà nípa wọn àti àwọn ohun tí o fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó gba ìrònú jinlẹ̀ gidigidi láti pinnu bí o ṣe fẹ́ ṣe àwọn dúkìá rẹ, kí o sì pinnu ọ̀nà tó dára jù lọ láti ṣe àwọn ohun náà. Ṣùgbọ́n bí a kò bá fún ṣíṣètò dúkìá ẹni láfiyèsí tó tọ́, ó lè yọrí sí àwọn ìṣòro tí ó le, bí a ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú àwọn ìrírí tí a fi ṣí àpilẹ̀kọ yìí. Lótìítọ́ ni, àwọn àǹfààní rẹ̀ yóò fi hàn pé ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àǹfààní rẹ̀ tí ó tóbi jù lọ ni àlàáfíà ọkàn tí ń wá láti inú mímọ̀ pé o ní ìṣètò tó bágbà mu láti dáàbò bo àwọn olólùfẹ́ rẹ.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àpẹẹrẹ tí a lò nínú àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ àbámodá, wọ́n dá lórí ọ̀kankòjọ̀kan ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an. Ní àfikún, àwọn ìsọfúnni tí a gbé kalẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí dá lórí òfin United States ní tààràtà, àmọ́ àwọn ìlànà tí a jíròrò wúlò ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè mìíràn.

b Fún ìsọfúnni síwájú sí i, jọ̀wọ́ wo ìwé pẹlẹbẹ náà Planned Giving to Benefit Kingdom Service Worldwide, tí Watch Tower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn Ohun Tí A Ní Láti Ṣe

• Ṣàkọsílẹ̀ àwọn dúkìá rẹ, kọ àwọn ohun tí o ní àti àwọn gbèsè tí o jẹ

• Pinnu ohun tí o fẹ́ gbé ṣe àti àwọn èyí tí ìdílé rẹ fẹ́ gbé ṣe, àti àwọn ohun tí o nílò

• Yan àwọn ènìyàn bí baba-ìsìnkú, abánibójútó-ǹkan, àti aláṣẹ̀yìndè òkú tí yóò ṣe àwọn ohun tí o fẹ́ kí ó ṣe fún àwọn ọmọ rẹ, sì rí i dájú pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí gbígba ẹrù iṣẹ́ náà

• Wádìí àwọn oríṣi ìṣètò dúkìá tó wà nípa bíbèèrè àmọ̀ràn lọ́dọ̀ ẹni tó nírìírí nínú ìṣètò dúkìá

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 17]

Àkọsílẹ̀ Gbogbo Dúkìá

Àwọn Dúkìá Lórúkọ Rẹ Lórúkọ Ọkọ Lórúkọ Àjọdá

Tàbí Aya Rẹ

Ibùgbé (iye tí ó tó ₦ ₦ ₦

lọ́jà ní lọ́ọ́lọ́ọ́)

Dúkìá ilé àti ilẹ̀ mìíràn ₦ ₦ ₦

Àkáǹtì ní báńkì (sọ̀wédowó ₦ ₦ ₦

àti oníwèé ìfowópamọ́)

Àkáǹtì mìíràn tí ó ₦ ₦ ₦

lówó nínú

Owó ìdókòwò, owó ìdúró, ₦ ₦ ₦

àti owó àjọdá

Ìbánigbófò ẹ̀mí ₦ ₦ ₦

(iye tó wà lórí ìwé ẹ̀rí)

Èrè orí òwò àjọdá ₦ ₦ ₦

Àkáǹtì ìwéwèé ìfẹ̀yìntì ₦ ₦ ₦

Ohun ìní ẹni ₦ ₦ ₦

Àwọn dúkìá mìíràn (kọ wọ́n) ₦ ₦ ₦

Àròpọ̀ dúkìá ₦ ₦ ₦

Gbèsè

Ohun àfidúró ₦ ₦ ₦

Owó mìíràn tí a yá tàbí ₦ ₦ ₦

gbèsè (owó tí a dá yá,

káàdì ìrajà àwìn,

àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ)

Àròpọ̀ gbèsè ₦ ₦ ₦

Gbogbo dúkìá ilẹ̀ àti ilé ₦ ₦ ₦

(yọ gbèsè kúrò nínú dúkìá)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ṣíṣètò dúkìá ní ṣíṣètò sílẹ̀ de ọjọ́ iwájú fún àwọn olólùfẹ́ rẹ nínú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́