Kò Juwọ́ Sílẹ̀
NÍ October 5, 1995, Matt Tapio, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, ṣe iṣẹ́ abẹ nítorí ohun kan tó wú sínú ọpọlọ rẹ̀. Ohun tó wú sọ́pọlọ rẹ̀ náà jẹ́ èyí tó lè ṣekúpani. Iṣẹ́ abẹ náà jẹ́ èkíní nínú ọ̀pọ̀ tí yóò ṣe láàárín ọdún méjì ààbọ̀ tí yóò tẹ̀ lé e. Àwọn ìtọ́jú oníkẹ́míkà àti ìtọ́jú onítànṣán ni ó tẹ̀ lé èyí.
Michigan, ní United States of America, ni Matt ń gbé, ibẹ̀ ló ti ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ìjọba àti àwọn ìpàdé Kristẹni. Ó ń lo gbogbo àǹfààní tí ó bá ní láti bá àwọn olùkọ́ àti àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀, bákan náà ni ó tún ń kópa nínú bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba. Láàárín àwọn àkókò tí ó fi wà ní ilé ìwòsàn, níbi tó ti lo ọdún kan ààbọ̀ lára ọdún méjì ààbọ̀ tí ó kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀, ó fún àwọn tó bá pàdé níbẹ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó máa ń dà bí ẹni pé Matt yóò kú, ṣùgbọ́n gbogbo àkókò bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń sọjí padà. Nígbà tó ń lọ sí ilé ìwòsàn ní ọjọ́ kan, gìrì mú un, ó sì dá kú. Wọ́n wá lo ìlànà ìmọ́kànsọjí fún un, ó sì sọjí padà. Nígbà tí ó wá mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé: “Jagunjagun ni mi! Jagunjagun ni mi! N kì í ṣẹni tí ń juwọ́ sílẹ̀!” Àwọn ènìyàn sọ pé ìgbàgbọ́ tí Matt ní nínú Ọlọ́run ni ó ràn án lọ́wọ́ láti wà láàyè fún àkókò tí ó gùn tó bẹ́ẹ̀.
Matt mú ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ tí ó ṣìkẹ́ gan-an ṣẹ nígbà tó ṣe ìrìbọmi tí ó jẹ́ ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run ní January 13, 1996. Ó ṣe ìrìbọmi náà nínú omi tí a ṣètò fún òun nìkan nítorí ewu àkóràn àrùn. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó tún padà sí ilé ìwòsàn láti ṣe àwọn iṣẹ́ abẹ mìíràn. Ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ ni Matt fi bì léraléra ní August 1997, àmọ́, ara rẹ̀ tún padà bọ̀ sípò lẹ́yìn tí wọ́n tún ṣe iṣẹ́ abẹ fún un.
Ní gbogbo àkókò yìí, Matt ń lo ànímọ́ ìpanilẹ́rìn-ín dáradára tó ní, ó ń bá gbogbo àwọn dókítà àti àwọn nọ́ọ̀sì dápàárá. Wọn kò mọ ìdí tí ó fi ní irú àgbàyanu ànímọ́ ìpanilẹ́rìn-ín bẹ́ẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn dókítà náà sọ fún un pe: “Matt, tó bá jẹ́ pé èmi ni ẹ́, màá ta aṣọ yí ibùsùn mi po, màá wá daṣọ borí, màá sì sọ pé kí olúkúlùkù máa lọ.”
Matt padà sílé ní ìgbà kan lára àwọn àkókò tí ó lò kẹ́yìn nínú ìgbésí ayé rẹ̀ ní February 1998. Inú rẹ̀ dùn gan an láti wà láàyè àti láti wà ní ilé, débi pé bí ó ṣe ń wọlé láti ẹnu ilẹ̀kùn ni ó sọ pé: “Inú mi dùn gan an ni! Ẹ jẹ́ ká gbàdúrà.” Ó wá fi ìdùnnú rẹ̀ hàn sí Jèhófà nínú àdúrà. Oṣù méjì lẹ́yìn náà, ní April 19, àrùn jẹjẹrẹ náà pa á.
Ṣáájú àkókò yìí, wọ́n gbé ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò kan tí a gbà sílẹ̀ lẹ́nu Matt sáfẹ́fẹ́ ní àkókò kan tí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lọ lọ́wọ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò rẹ̀. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni ìwọ yóò sọ fún àwa tí ara wá yá nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa àti àwọn ìpàdé Kristẹni?”
Matt dáhùn pe: “Ẹ ṣe ohun tí ẹ lè ṣe báyìí. . . . Ẹ kò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀. . . . Àmọ́, ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ má ṣe dẹ́kun jíjẹ́rìí nípa Jèhófà láé.”