ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 5/8 ojú ìwé 16-17
  • “Wàá Kàn Kú Dànù Ni!”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Wàá Kàn Kú Dànù Ni!”
  • Jí!—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkojú Ọ̀ràn Ìṣègùn Àìròtẹ́lẹ̀
    Jí!—1996
  • Dídáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Ìlòkulò Ẹ̀jẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Lílo Ara Ẹni Fáwọn Ẹlòmíràn Ń Dín Ìṣòro Kù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìrànlọ́wọ́ Láti Múni Dúró Ṣinṣin Lórí Ọ̀ràn Ìjẹ́mímọ́ Ẹ̀jẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Jí!—2000
g00 5/8 ojú ìwé 16-17

“Wàá Kàn Kú Dànù Ni!”

BÍ LEANNE KARLINSKY ṢE SỌ Ọ́

Ìrìnkèrindò mi lórí wíwá ìtọ́jú tó dáa láìní lo ẹ̀jẹ̀ ní Sípéènì

BÍ O bá ní àǹfààní láti lọ síbikíbi lágbàáyé, ibo lo máa fẹ́ lọ? Ní tèmi, mi ò dààmú jù kí n tó dáhùn ìbéèrè náà. Èdè Spanish ni mo ń kọ́ àwọn ọmọ ilé ìwé, ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti ń sọ èdè Spanish ní Galax, Virginia, U.S.A., sì ni èmi, Jay tó jẹ́ ọkọ mi, àti Joel, ọmọ mi, ń lọ. Nígbà náà, Sípéènì ló wà lọ́kàn mi láti lọ. Nítorí náà, ẹ lè ronú nípa bí inú mi ti dùn tó nígbà tí àwọn òbí mi sọ pé àwọn á mú mi lọ síbẹ̀! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ mi àti ọmọ wa ò lè bá wa lọ, ohun tí mo ti ń fojú sọ́nà fún ti fẹ́rẹ̀ẹ́ nímùúṣẹ bí èmi àti àwọn òbí mi ti tẹkọ̀ létí tí a sì wọkọ̀ òfuurufú tó ń lọ sí Madrid tààràtà. Nígbà táa débẹ̀ ní April 21, a pinnu láti wọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lọ sí Estella, ìlú kékeré kan ní àgbègbè Navarre, ní àríwá Sípéènì. Mo rọra wábi tó dáa jókòó sí lẹ́yìn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo sì sùn lọ.

Ohun tí mo rántí lẹ́yìn náà ni pé mo nà gbalaja sórí pápá kan, tí oòrùn sì ń wọ̀ mí lójú. ‘Ibo ni mo wà yìí? Báwo ni mo ṣe débí? Àbí mo ń lálàá ni?’ Bí gbogbo ìbéèrè wọ̀nyí ṣe ń wá sọ́kàn mi, ọkàn mi ń sọ pé aburú kan ti ṣẹlẹ̀. Nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀, àlá kọ́ ni mo ń lá o. Ọwọ́ aṣọ mi ti ya jálajàla lápá òsì, mi ò lè gbé apá, bẹ́ẹ̀ ni mi ò lè gbé ẹsẹ̀ mi. Ìgbẹ̀yìngbẹ́yín ni mo wá gbọ́ pé ńṣe ni ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa lọ forí sọ irin tí wọ́n fi pààlà títì, tó sì bẹ́ sódì kejì àti pé ńṣe ni mo jábọ́ látinú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà nígbà tó ń tàkìtì láti ibi tó ga ní ogún mítà sísàlẹ̀. Ká tún dúpẹ́ pé èmi àti àwọn òbí mi ò rántí bí ìjàǹbá náà ṣe ṣẹlẹ̀.

Mo kígbe pé kí àwọn èèyàn gbà mí o, awakọ̀ akẹ́rù kan sì sáré wá bá mi. Lẹ́yìn náà ló lọ sídìí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà nísàlẹ̀, níbi tí àwọn òbí mi há sí. Ọkùnrin náà kígbe pe ẹnì kejì rẹ̀ pé: “Ké sí ọkọ̀ tí wọ́n fi ń gbé aláìsàn pé kó tètè máa bọ̀! Àwọn tó wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yìí fara pa gan-an!” Lẹ́yìn náà, ó padà wá síbi tí mo wó sí, tí mi ò lè gbé ọwọ́ gbé ẹsẹ̀, pẹ̀lú èrò àtiràn wá lọ́wọ́, ó gbìyànjú láti na ẹsẹ̀ mi. Bí ara ṣe ro mí tó ni mo bugbe ta, ìgbà yẹn ni mo sì kọ́kọ́ mọ̀ pé mo fara pa gan-an.

Láìpẹ́, mo ti bára mi ní iyàrá ìtọ́jú pàjáwìrì nílé ìwòsàn kan ládùúgbò Logroño. Àwọn ọlọ́pàá ṣe dáadáa, wọ́n sọ ibi tí mo wà fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè náà, wọ́n sì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn. Láìpẹ́, ọ̀pọ̀ àwọn ará láti ìjọ Estella àti Logroño ti wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibùsùn mi, pẹ̀lú àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn àdúgbò náà. Kí n sọ tòótọ́, jálẹ̀ gbogbo ìṣòro tí mo ní nílé ìwòsàn yìí, àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi ọ̀wọ́n, tí mi ò mọ̀ rí, múra tán, wọ́n sì fínnúfíndọ̀ tọ́jú mi, tọ̀sántòru. Wọ́n tún fi tìfẹ́tìfẹ́ tọ́jú àwọn òbí mi, tí ara tiwọn ti yá dáadáa débi tí wọ́n fi lè dá wọn sílẹ̀ nílé ìwòsàn láti máa lọ sílé ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn ìjàǹbá náà.

Ní nǹkan bí aago kan òru ọjọ́ Wednesday, àwọn dókítà wá ṣiṣẹ́ abẹ ní ìgbáròkó tí mo fi ṣẹ́. Mo sọ fún dókítà náà pé mi ò gbẹ̀jẹ̀ o.a Ó gbà láti ṣe bí mo ṣe wí bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lọ́ra, ṣùgbọ́n ó sọ fún mi pé mo lè tibẹ̀ kú o. Iṣẹ́ abẹ náà lọ láìsí aburú, ṣùgbọ́n ó yà mí lẹ́nu pé wọn ò wẹ ojú ọgbẹ́ mi, wọn ò sì pààrọ̀ ọ̀já ìdigbẹ́ mi nígbà tó yẹ.

Nígbà tó fi máa di ọjọ́ Friday ẹ̀jẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán lára mi, kò sì sókun nínú mi mọ́. Dókítà gbà láti lo ìlànà ìtọ́jú míì fún mi—abẹ́rẹ́ èròjà erythropoietin (EPO), tí òun àti èròjà iron àti àwọn èròjà tó ń ṣàlékún ẹ̀jẹ̀ mú kí èròjà pupa inú ẹ̀jẹ̀ mi pọ̀ sí i.b Lákòókò tí mo ń sọ yìí, Jay àti Joel ti dé. Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo rí ọkọ mi àti ọmọ mi!

Ní nǹkan bí aago kan ààbọ̀ òru, dókítà kan sọ fún Jay pé ilé ìwòsàn àwọn ti gba àṣẹ nílé ẹjọ́ láti fàjẹ̀ sí mi lára bí ipò mi bá burú sí i. Jay sọ fún un pé ipò yòówù kí ń wà, mi ò fẹ́ kí wọ́n fàjẹ̀ sí mi lára rárá. Dókítà náà wá fèsì pé: “Ó máa kú nìyẹn o!”

Jay bá Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn sọ̀rọ̀ pé kí wọ́n gbé mi kúrò níbẹ̀ lọ sí ilé ìwòsàn míì—níbi tí wọ́n á ti ṣe ohun tí mo fẹ́. Gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé ìwòsàn náà kọ́ ló ṣàtakò. Àpẹẹrẹ kan ni ti dókítà kan níbẹ̀ tó mú un dá mi lójú pé òún á sa gbogbo ipá òun láti rí i pé wọ́n fi ọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, àwọn dókítà míì bẹ̀rẹ̀ sí yọ mí lẹ́nu. Wọ́n bi mí léèrè pé: “Ṣé o fẹ́ kú kóo fi ìdílé ẹ sílẹ̀ ni?” Mo mú u dá wọn lójú pé mo fẹ́ kí wọ́n lo gbogbo ọ̀nà tí wọ́n bá mọ̀ láti fi tọ́jú mi láìlo ẹ̀jẹ̀. Àwọn dókítà náà ò torí ẹ̀ ṣàánú mi, kí wọ́n sì tọ́jú mi. Ìkan lára wọ́n tiẹ̀ jájú mọ́ mí pé: “Wàá kàn kú dànù ni!”

Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn rí ilé ìwòsàn kan ní ìlú Barcelona tí wọ́n ti gbà láti tọ́jú mi láìlo ẹ̀jẹ̀. Ilé ìwòsàn yẹn yàtọ̀ pátápátá sí ti àkọ́kọ́! Ní Barcelona, àwọn nọ́ọ̀sì méjì fẹ̀sọ̀ wẹ̀ fún mi, wọ́n sì ṣe mí jẹ́jẹ́. Nígbà tí wọ́n ń pààrọ̀ ọ̀já ìdigbẹ́ ara mi, ọ̀kan lára àwọn nọ́ọ̀sì náà rí i pé ó ti láwọ̀ ewé, ẹ̀jẹ̀ sì ti sọ ọ́ di gígan. Ó sọ pé ojú gba òun tì pé àwọn ọmọ ìlú òun ṣe mí bẹ́ẹ̀.

Láìpẹ́, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú mi bó ṣe yẹ kí ilé ìwòsàn tí mo wà tẹ́lẹ̀ ní Logroño ṣe. Àbájáde rẹ̀ kàmàmà. Láàárín ọjọ́ mélòó kan péré, kò séwu fún àwọn ẹ̀yà inú ara mi mọ́, ìwọ̀n èròjà pupa inú ẹ̀jẹ̀ mi sì ti pọ̀ sí i, ó ti gbé pẹ́ẹ́lí ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Nígbà tí mo fi máa kúrò ní ilé ìwòsàn náà, ó tún ti lọ sókè sí i. Nígbà tí wọ́n tún fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ́ míì fún mi ní ilé ìwòsàn kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ó tún ti ròkè sí i.

Mo dúpẹ́ fún ipá táwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì sà, àwọn tí wọ́n múra tán láti ṣe ohun tí àwọn èèyàn tí wọ́n ń tọ́jú bá fẹ́, yálà wọ́n gbà pẹ̀lú wọn tàbí wọn ò gbà pẹ̀lú. Tí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn bá bọ̀wọ̀ fún ohun tí aláìsàn kan gbà gbọ́, ẹni yẹn gan-an ni wọ́n ń tọ́jú—nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń tọ́jú rẹ̀ lọ́nà tó dára jù lọ́.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nítorí àwọn ìdí tí a gbé karí Bíbélì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gbẹ̀jẹ̀.—Wo Jẹ́nẹ́sísì 9:4; Léfítíkù 7:26, 27; 17:10-14; Diutarónómì 12:23-25; 15:23; Ìṣe 15:20, 28, 29; 21:25.

b Yálà Kristẹni kan yóò gba èròjà EPO sára tàbí kò ní gbà á jẹ́ ìpinnu tirẹ̀.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, October 1, 1994, ojú ìwé 31.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Èmi àti ọkọ mi, àti ọmọ wa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Méjì lára àwọn Alárinà Ilé Ìwòsàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́