Kíkojú Ọ̀ràn Ìṣègùn Àìròtẹ́lẹ̀
“ÈMI yóò sọ ojú abẹ níkòó; o ní kókó ọlọ́yún bíburú jáì. Bí a kò bá yọ ọ́ kúrò kánkán, yóò pa àwọn ẹ̀yà ara pàtàkì míràn lára. Ìyẹn ló mú kí n dámọ̀ràn gígé ẹsẹ̀ rẹ kúrò.”
Ọ̀rọ dókítà náà wọ̀ mí lára gan-an, bí omi tútù nínú ọyẹ́, bí a ti ń sọ ọ́ níhìn-ín ní Peru. Ọmọ ọdún 21 péré ni mí. Ní oṣù kan ṣáájú ni orúnkún mi òsí bẹ̀rẹ̀ sí í ro mí, wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi làkúrègbé. Bí ó ti wù kí ó rí, níwọ̀n ọjọ́ díẹ̀, n kò lè dìde dúró pàápàá.
Ní àkókò náà, mo ń sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Andes, ní àárín gbùngbùn Peru. Lẹ́yìn tí mo padà sí ìlú ìbílẹ̀ mi ní Huancayo, màmá mi rìnrìn àjò pẹ̀lú mi lọ sí ìlú Lima, ní etíkun. Níbẹ̀, ní July 22, 1994, a gbà mí sí ilé ìwòsàn ìtọ́jú àrùn jẹjẹrẹ, tí ó dára jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà, níbi tí mo ti mọ̀ pé àrùn tí ń ṣe mí ni a ń pè ní osteosarcoma [kókó ọlọ́yún aṣekúpani tí ń bẹ̀rẹ̀ nínú egungun].
Ọ̀ràn Ẹ̀rí Ọkàn
Láìpẹ́, a sọ fún mi pé ilé ìwòsàn náà kì í ṣe iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀. Dókítà kán tilẹ̀ sọ pé: “Ó tẹ́ mi lọ́rùn kí o kú sílé ju kí o wá kú sí mi lọ́rùn lọ.” Ṣùgbọ́n Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC) àdúgbò náà, àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ń ṣagbátẹrù ìgbọ́ra-ẹni-yé láàárín ilé ìwòsàn àti olùgbàtọ́jú, dá sí ọ̀ràn náà nítorí mi. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ọ̀gá àgbà oníṣẹ́ abẹ yọ̀ǹda fún dókítà èyíkéyìí, tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, tí ó sì fẹ́ láti kojú ìpèníjà náà, láti ṣiṣẹ́ abẹ náà. Dókítà kán fẹ́, a sì múra mi sílẹ̀ fún iṣẹ́ abẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ọ̀pọ̀ àlejò ló bẹ̀ mí wò ṣáájú iṣẹ́ abẹ náà. Àlùfáà kan tí ó gbé Bíbélì dání wá, ó sì sọ pé àìsàn mí jẹ́ ìjìyà láti ọwọ́ Ọlọ́run. Ó rọ̀ mí láti fara mọ́ oríṣi ìtọ́jú èyíkéyìí tí ó bá lè gba ẹ̀mí mi là. Mo sọ fún un pé, mo ti pinnu láti rọ̀ mọ́ àṣẹ Bíbélì láti ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀.’—Ìṣe 15:19, 20, 28, 29.
Àwọn olùtọ́jú aláìsàn pẹ̀lú ń wọlé wá, wọ́n sì ń ráhùn pé: “Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ìwà òmùgọ̀ tó, ẹ wo bí ó ti jẹ́ ìwà òmùgọ̀ tó!” Ẹgbẹẹgbẹ́ àwọn dókítà náà wá. Wọ́n fẹ́ láti rí ọ̀dọ́kùnrin náà tí kò fẹ́ gba ẹ̀jẹ̀ fún irúfẹ́ iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ti ka ẹ̀jẹ̀ sí kòṣeémágbà. Bí ó ti wù kí ó rí, ìbẹ̀wò tí ó ṣe pàtàkì sí mi jù lọ ni ti àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi àti àwọn ìbátan mi. Àwọn ìbẹ̀wò oníṣìírí wọ̀nyí wọ àwọn olùtọ́jú aláìsàn lọ́kàn gan-an.
Ìtọ́jú Kíkẹ́sẹ Járí Láìlo Ẹ̀jẹ̀
Ní kìkì ìṣẹ́jú díẹ̀ kí a tó kùn mí lóorun, mo gbọ́ tí ọ̀kan lára àwọn akunnilóorun ń sọ pé: “Ohun yòówù kí ó ṣẹlẹ̀ kò kàn mí!” Ṣùgbọ́n akunnilóorun kejì, àti ẹni tí yóò ṣiṣẹ́ abẹ fún mi àti àwọn olùdarí ilé ìwòsàn, bọ̀wọ̀ fún ẹ̀bẹ̀ mi láti má ṣe gba ẹ̀jẹ̀. Ohun tí mo gbọ́ tẹ̀ lé e ni ìgbà tí akunnilóorun kan wí pé: “Samuel, dìde. Iṣẹ́ abẹ rẹ ti parí.”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti gé odindi ẹsẹ̀ mi kúrò, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìrora níbi tí ó ti wà tẹ́lẹ̀. Mo fẹ́ láti pa ìrora náà nípa fífi ọwọ́ pa itan mi tí wọ́n ti gé kúrò. Mo ń ní ìrírí ṣíṣàjèjì tí wọ́n ń pè ní òjìji ìrora. Mo nímọ̀lára ìrora gan-an, ó sì mú mi joró, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, wọ́n ti gé ibi tí ó jọ pé ìrora náà ti ń wá kúrò.
Lẹ́yìn náà, a ṣètò pé kí n gba ìtọ́jú oníkẹ́míkà. Ìyọrísí búburú kan tí irú ìtọ́jú yìí ní jẹ́ ìpàdánù àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa àti funfun àti àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pẹlẹbẹ, tí wọn kò ṣeé máà ní fún ìdìpọ̀ ẹ̀jẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé, a ní láti fi tó àwùjọ àwọn dókítà tuntun létí pé n kò fẹ́ láti gba ẹ̀jẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ìgbìmọ̀ HLC tún bá àwọn tí ọ̀rọ́ kan sọ̀rọ̀, àwọn dókítà náà sì gbà láti ṣe ìtọ́jú náà láìlo ẹ̀jẹ̀.
Àwọn ìyọrísí búburú wíwọ́pọ̀ ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé ìtọ́jú oníkẹ́míkà náà—irun mi bẹ̀rẹ̀ sí í tu dà nù, ẹ̀dọ́ sì ń rìn mí, mo ń bì, mo sì sorí kọ́. Wọ́n ti sọ fún mi tẹ́lẹ̀ pé ewu ìṣẹ̀jẹ̀ ọpọlọ́ lè jẹ́ ìpín 35 nínú ọgọ́rùn-ún. N kò ṣàìbi dókítà kan léèrè ohun tí ó fẹ́ pa mí gan-an—àrùn jẹjẹrẹ náà tàbí ìtọ́jú oníkẹ́míkà náà.
Lẹ́yìn náà, àwọn dókítà sọ pé àwọn kò lè fún mi ní ìgbésẹ̀ kejì ìtọ́jú oníkẹ́míkà láìkọ́kọ́ fi kún ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ ara mi nípa fífa ẹ̀jẹ̀ sí mi lára. Dókítà kán fìbínú sọ fún mi pé, bí òún bá lágbára rẹ̀ ni, òun ì bá kùn mí lóorun, òun ì bá sì fún mi lẹ́jẹ̀ náà. Mo sọ fún un pé kí n tó fàyè gba ìyẹn láti ṣẹlẹ̀, n óò kúkú ṣíwọ́ gbígba ìtọ́jú oníkẹ́míkà náà pátápátá. Dókítà náà sọ pé ìdúró ṣinṣin mi jọ òun lójú.
Mo fara mọ́ lílo omi ìsúnniṣe inú kíndìnrín tí ń mú sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa pọ̀ sí i láti mú kí ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ ara mi lọ sókè. Nígbà tí wọ́n lò ó fún mi, ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ náà ròkè. Lẹ́yìn náà, wọ́n gún mi ní abẹ́rẹ́ ìtọ́jú oníkẹ́míkà náà fún sáà ọjọ́ bíi mélòó kan. Mo ń wà ní ìdùbúlẹ̀ níbẹ̀, tí mo sì ń ṣe kàyéfì pé, ‘Ṣé èyí tí mo ń lò yìí ni yóò fún mi ní ìṣẹ̀jẹ̀ ọpọlọ?’ Mo dúpẹ́ pé mo parí lílo gbogbo egbòogi náà láìsí àbájáde oníjàábá kankan.
Ṣáájú iṣẹ́ abẹ mi, ìpinnu ilé ìwòsàn náà ni láti dá àwọn ènìyàn tí kò bá fara mọ́ ìfàjẹ̀sínilára padà sílé. Ṣùgbọ́n ìpinnu yìí yí padà. Ní gidi, lọ́jọ́ tí ó tẹ̀ lé iṣẹ́ abẹ mi gan-an, oníṣẹ́ abẹ mi tún ṣiṣẹ́ abẹ mìíràn láìlo ẹ̀jẹ̀, olùgbàtọ́jú náà kì í sì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́tẹ̀ yìí! Ní báyìí, ọ̀pọ̀ lára àwọn dókítà ilé ìwòsàn náà ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ HLC, wọ́n sì ti gbà láti máa gba àwọn olùgbàtọ́jú tí ń fẹ́ iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀.
Mímú Ara Bá Àwọn Ààlà Mu
Wọ́n ti fi ọ̀nà Ọlọ́run kọ́ mi láti kékeré. Ó dá mi lójú pé èyí ràn mí lọ́wọ́ láti di ìdánilójú mi tí a gbé karí Bíbélì mú nínú ọ̀ràn ìṣègùn àìròtẹ́lẹ̀ yìí. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó bà mí nínú jẹ́ pé n kò lè ṣe tó bí mo ṣe fẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Mo sọ ìmọ̀lára mi fún arákùnrin ìyá mi kan, tí ó jẹ́ Kristẹni alàgbà. Ó rán mi létí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàápàá ní ohun tí ó pè ní ‘ẹ̀gún kan nínú ẹran ara rẹ̀,’ ìyẹ́n sì ṣèdíwọ́ fún un láti ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run bí ó ti fẹ́. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù ṣe ìwọ̀n tí ó lè ṣe. (Kọ́ríńtì Kejì 12:7-10) Ọ̀rọ̀ arákùnrin ìyá mi ràn mí lọ́wọ́ gidigidi.
Láìpẹ́ yìí, a ṣètò pé kí n máa lo ẹsẹ̀ àtọwọ́dá. Mo nírètí pé èyí yóò mú kí n lè ṣe iṣẹ́ ìsìn gbígbòòrò púpọ̀ sí i sí Ọlọ́run wa, Jèhófà. Mo dúpẹ́ pé mo di ẹ̀rí ọkàn rere mú nígbà ìtọ́jú ìṣègùn àìròtẹ́lẹ̀ mi. Ó dá mi lójú pé bí mo bá ń bá a lọ nínú ìṣòtítọ́, Jèhófà yóò fún mi ní èrè ìlera àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè ilẹ̀ ayé, níbi tí ìrora àti ìjìyà kì yóò ti sí mọ́.—Ìṣípayá 21:3, 4.—Gẹ́gẹ́ bí Samuel Vila Ugarte ṣe sọ ọ́.