Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Ṣèrànlọ́wọ́ Láti Mú Kí Iṣẹ́ Abẹ Ọkàn-àyà Sunwọ̀n Sí I
ÌWÉ agbéròyìnjáde New York Daily News ti August 27, 1995, kọ àkọlé ìròyìn wọn pé, “Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀.” Ó sọ pé, Ibùdó Ìṣègùn Ilé Ìwòsàn Cornell ti New York yóò “fi ọ̀nà pàtàkì tuntun láti ṣe iṣẹ́ abẹ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ọkàn-àyà hàn—irú iṣẹ́ abẹ kan náà tí alákòóso tẹ́lẹ̀ rí náà, David Dinkins, béèrè fún—láìpàdánù ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ kan ṣoṣo.”
Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdàníyàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ló ru ìṣètò tuntun náà sókè, ìyanu rẹ̀ . . . yóò fara hàn nínú dídín àwọn ilé ìwòsàn ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún dọ́là àti ewu dídín ìsẹ̀jẹ̀deléèérí kù jọjọ fún àwọn aláìsàn.” Dókítà Todd Rosengart, olùdarí ìtòlẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ ti ilé ìwòsàn náà, sọ pé: “Nísinsìnyí, a lè dín iye ìfàjẹ̀sínilára tí ó pọn dandan ní àkókò iṣẹ́ abẹ yìí kù láti orí ẹyọ méjì sí mẹ́rin fún aláìsàn kan sí òfo.”
Dókítà Karl Krieger, oníṣẹ́ abẹ ọkàn-àyà fún ilé ìwòsàn náà, tí ó ṣagbátẹrù ìṣètò náà, sọ pé: “Nípasẹ̀ mímú ìfẹ̀jẹ̀tọrẹ àti àwọn ohun tí a fi ẹ̀jẹ̀ ṣe kúrò, a tún ń dín ewu irú àwọn ibà tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ àti àwọn àkóràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìfàjẹ̀sínilára kù.”
Àwọn ògbógi mìíràn sọ pé, “iṣẹ́ abẹ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ọkàn láìlo ẹ̀jẹ̀ ń dín àkókò tí a ń lò láti pèsè ìtọ́jú kíkún rẹ́rẹ́ lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ kù—láti wákàtí 24 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sí wákàtí mẹ́fà péré. Àwọn aláìsàn tí a ṣà yàn fún iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ tètè ń kọ́fẹ padà, wọ́n sì tètè ń kúrò ní ilé ìwòsàn ní nǹkan bíi wákàtí 48 ṣáájú àwọn tí ó lo ẹ̀jẹ̀.” Ìyẹ́n túmọ̀ sí dídín ìnáwó kù gan-an fún àwọn ilé ìwòsàn, ìjọba àti àwọn ilé iṣẹ́ abánigbófò. Dókítà Rosengart díwọ̀n rẹ̀ pé, “iṣẹ́ abẹ yìí lè dín, ó kéré tán, 1,600 dọ́là kù lórí aláìsàn kan.”
Ìròyìn ìwé agbéròyìnjáde Daily News ń bá a lọ pé:
“Ó jẹ́ ohun tí ó jọni lójú pé kì í ṣe ìjẹ́kánjúkánjú ọrọ̀ ajé tàbí ìṣègùn ní o súnná sí iṣẹ́ abẹ tuntun yìí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nítorí ìsúnniṣe ìsìn. Àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa—àwọn tí ìgbàgbọ́ ìsìn wọn ka ìfàjẹ̀sínilára léèwọ̀—ń wá ìrànwọ́ fún àwọn mẹ́ḿbà wọn tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà tí ń ní àrùn ọkàn-àyà. . . .
“Nítorí ìrọni tí àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe, àwọn dókítà pa àwọn ọ̀nà ọgbọ́n ìdáàbò bo ẹ̀jẹ̀ wọn pọ̀ mọ́ oògùn tuntun náà. Wọ́n tún ṣàwárí ọ̀nà tuntun kan láti lo ẹ̀rọ ọkàn-àyà òun ẹ̀dọ̀fóró tí a ń lò láti mú kí àwọn aláìsàn wà láàyè ní àkókò iṣẹ́ abẹ ọkàn-àyà.
“Ní àfikún sí àwọn 40 aláìsàn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí wọ́n wà nínú àwọn tí a kọ́kọ́ ṣà yàn fún ìwádìí iṣẹ́ abẹ náà, ní oṣù mẹ́fà sẹ́yìn, ẹgbẹ́ ìṣègùn ilé ìwòsàn Cornell ti New York mú iṣẹ́ abẹ náà wọnú àwùjọ aláìsàn ti gbogbogbòò. Krieger sọ pé: “Láti ìgbà náà, wọ́n ti ṣe àṣeparí léraléra nínú iṣẹ́ abẹ 100 tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ọkàn láìlo ẹ̀jẹ̀, láìsí ẹni tí ó kú.’ Iye ikú tí ń ṣẹlẹ̀ nínú iṣẹ́ abẹ tí a ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ọkàn-àyà jẹ́ nǹkan bíi ìpín 2.3 nínú ọgọ́rùn-ún.”
Kárí ayé ilé ìwòsàn 102 ti fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ kún ìlànà iṣẹ́ wọn, ní mímú àwọn ìṣètò iṣẹ́ abẹ tí ó láàbò wọ̀nyí wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún gbogbo àwùjọ àwọn aláìsàn ní gbogbogbòò káàkiri ilẹ̀ ayé.