Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀—Àwọn Ènìyàn Ń Mọ Àǹfààní Rẹ̀
NÍ 1996, Ẹgbẹ́ Àwọn Oníṣẹ́ Abẹ ní England tẹ ìwé kékeré kan jáde tí wọ́n pè ní Code of Practice for the Surgical Management of Jehovah’s Witnesses. Nínú ìwé kékeré yẹn, àwọn oníṣẹ́ abẹ náà sọ pé: “Àwọn ewu tó rọ̀ mọ́ ìfàjẹ̀sínilára mú kí ó bọ́gbọ́n mu láti ronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ àfirọ́pò nígbàkigbà tó bá ṣeé ṣe.”
Ìwé ìròyìn AHA NEWS, tí Ẹgbẹ́ Òṣìṣẹ́ Ilé Ìwòsàn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe, tún sọ nípa ohun tó mú kí àwọn ènìyàn máa mọ àwọn àǹfààní iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀. Ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ náà sọ pé: “Ohun tó bẹ̀rẹ̀ bí ìgbàgbọ́ ìsìn ti ń di ohun àyànláàyò nínú iṣẹ́ ìṣègùn àti ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀. Ṣíṣe ìṣègùn àti iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀, tí àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fínná mọ́ lápá kan, ti kúrò ní ohun tí ẹgbẹ́ onísìn kan nílò, ó sì ti ń wọnú àwọn iyàrá iṣẹ́ abẹ jákèjádò orílẹ̀-èdè.”
Kókó ọ̀rọ̀ àkànṣe inú ìtẹ̀jáde àfikún ìwé ìròyìn Time ti ìgbà ìwọ́wé 1997 jẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ìdí tí ọ̀pọ̀ dókítà fi ń gbé iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ lárugẹ. Àpilẹ̀kọ náà wí pé: “Ìbẹ̀rù àrùn AIDS wulẹ̀ jẹ́ ìdí kan lásán ni.” Ní pàtàkì, àpilẹ̀kọ náà ròyìn nípa iṣẹ́ tí a ń ṣe ní ẹ̀ka Ilé Ìwòsàn Englewood tí a ń pè ní Ibùdó Ìtẹ̀síwájú Ìṣègùn àti Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀ ti New Jersey, ní Englewood, New Jersey.
Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Ibùdó náà jẹ́ aṣáájú nínú àwọn tó lé ní 50, tí ń ṣe iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ ní United States, nísinsìnyí. Láìlo ẹ̀jẹ̀ tí a fi tọrọ kankan, wọ́n ń ṣe onírúurú iṣẹ́ abẹ tí ì bá gba ìfàjẹ̀sínilára, wọ́n ń lo àwọn ọ̀nà ìṣeǹkan tó dín ìpàdánù ẹ̀jẹ̀ kù gidigidi, tàbí tí kò tilẹ̀ jẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ rárá.”
Ó Gbéṣẹ́, Kò sì Léwu
Ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn Time náà sọ ìrírí Henry Jackson, tó ń ṣẹ̀jẹ̀ sínú tó bẹ́ẹ̀ tí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ dà nù, tó sì dín ìwọ̀n èròjà àwọ̀ pupa inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kù sí ìwọ̀n tí ń wu ẹ̀mí léwu ti gíráàmù 1.7 nínú ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ dẹ̀sílítà kan. Láti ilé ìwòsàn kan ní New Jersey, tí kò fẹ́ tọ́jú Jackson láìfa ẹ̀jẹ̀ sí i lára ni wọ́n ti gbé e lọ sí Ilé Ìwòsàn Englewood.
Nílé ìwòsàn ti Englewood, lábẹ́ àbójútó Dókítà Aryeh Shander, wọ́n fún Jackson ní “àwọn àpòpọ̀ lílágbára ti àlékún èròjà iron àti fítámì, wọ́n sì tún fún un ní egbòogi amẹ́jẹ̀pọ̀ kan, àtọwọ́dá omi ìsúnniṣe inú kíndìnrín tí ń mú sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa pọ̀ sí i, tí ń fún mùdùnmúdùn inú egungun lágbára láti mú sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa jáde, ní ‘ìwọ̀n púpọ̀ gan-an.’ Níkẹyìn wọ́n fún un ní abẹ́rẹ́ àwọn ohun olómi tí yóò mú kí ìwọ̀nba ẹ̀jẹ̀ tó kù lára rẹ̀ lè máa lọ káàkiri ara.”
Ìwé ìròyìn Time sọ pé, lọ́jọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, “ilé ìwòsàn àkọ́kọ́ tẹ̀ wọ́n láago láti mọ̀ bóyá Jackson ti kú. Pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn tí a kò fi bò, Shander sọ fún wọn pé, ‘Yàtọ̀ sí pé kò kú, ara rẹ̀ ti le dáadáa, a sì ti fẹ́ yọ̀ǹda fún un pé kí ó máa lọ sílé, yóò sì máa bá ìgbòkègbodò rẹ̀ ojoojúmọ́ nìṣó láìpẹ́.’”
Nínú ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò kan lórí tẹlifíṣọ̀n ní November 28, 1997, Dókítà Edwin Deitch, oníṣègùn tí ń bójú tó ètò ìtọ́jú láìlo ẹ̀jẹ̀ ní Ilé Ìwòsàn Yunifásítì, ní Newark, New Jersey, ṣàlàyé bí ìwádìí nípa iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ ṣe wáyé, pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà . . . ń sapá púpọ̀púpọ̀ láti rí ẹni tí yóò ṣiṣẹ́ abẹ fún wọn láìlo ẹ̀jẹ̀. Àwọn kan lára àwọn àbájáde ìwádìí wọ̀nyẹn fi hàn pé wọ́n ń kọ́fẹ padà ju bí a ti retí lọ, [ju] àwọn tó gbẹ̀jẹ̀ sára [lọ].”
Dókítà Deitch ṣàfikún pé: “Ẹ̀jẹ̀ lè dín bí agbára tí ara ní láti dènà àrùn ṣe gbéṣẹ́ tó kù, kí ó sì fa àwọn àrùn tí ń jẹ yọ lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ; ó lè mú kí ewu níní àrùn jẹjẹrẹ tí ń ṣeni lemọ́lemọ́ pọ̀ sí i, nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀jẹ̀ ń ṣàǹfààní ní àwọn ọ̀nà kan, ó wá já sí pé, ó ní àwọn àbájáde tí a kò fẹ́.” Dókítà Deitch parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ pé: “Ó ṣe kedere pé ó ń mú kí bí a ṣe ń ṣètọ́jú aláìsàn sunwọ̀n sí i láìsí àbájáde búburú púpọ̀, [ó] sì ń dínni lówó kù. Nítorí náà, ó ṣàǹfààní lọ́nà gbogbo.”
Nípa báyìí, ìwé ìròyìn Time sọ pé, “àwọn aláìsàn tí ń pọ̀ sí i ń wá àwọn ọ̀nà tí kò léwu, tó sì gbéṣẹ́ ju ìfàjẹ̀sínilára lọ.” Ìwé ìròyìn náà tún sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìfojúdíwọ̀n kan ṣe fi hàn, ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún ìfàjẹ̀sínilára tí a ń ṣe ní United states ni kò pọndandan. Àwọn àmì ìtọ́ka tún wà pé ara àwọn aláìsàn kò lè gba ìwọ̀n èròjà àwọ̀ pupa inú ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ tó bí a ti rò tẹ́lẹ̀ àti pé àwọn ọ̀dọ́ ní pàtàkì ní àfipamọ́ ẹ̀jẹ̀ nínú ara wọn. . . . Ó dá [Shander] lójú pé ohun tí ó dára jù, tó sì ṣeé yàn láàyò jù fún ọ̀pọ̀ aláìsàn, ni kí wọ́n má gba ẹ̀jẹ̀ sára.”
Bí kíkó àrùn nípasẹ̀ ìfàjẹ̀sínilára tilẹ̀ jẹ́ ewu ńlá kan, àwọn ewu mìíràn tún wà. Dókítà Shander sọ pé: “Lẹ́yìn tí ẹ̀jẹ̀ tí a gbà pa mọ́ bá ti tutù, tó sì ti wà nípamọ́, kò ní agbára láti gbé afẹ́fẹ́ oxygen kiri inú ara bí ẹ̀jẹ̀ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà. Ìgbà yìí la ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí a bá ń fàjẹ̀ síni lára.”
“Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Ìníyelórí”
Ìwé ìròyìn Time parí ọ̀rọ̀ pé: “Níkẹyìn, ohun tó ń náni wà níbẹ̀: bí ìfàjẹ̀sínilára kọ̀ọ̀kan ṣe ń náni ní nǹkan bí 500 dọ́là, pẹ̀lú àwọn àfikún owó iṣẹ́, àpapọ̀ owó náà ń lọ sí àárín bílíọ̀nù kan sí méjì dọ́là lọ́dọọdún, ìdí pàtàkì kan tó tó múni ronú nípa àfidípò.” Ó wá jọ pé iye owó tó gadabú tí ìfàjẹ̀sínilára ń náni jẹ́ ìdí pàtàkì kan tí iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ fi lókìkí tó bẹ́ẹ̀.
Sharon Vernon, olùdarí Ibùdó Ìṣègùn àti Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀ ní Ilé Ìwòsàn St. Vincent Charity, Cleveland, Ohio, sọ nípa títọ́jú àwọn aláìsàn láìlo ẹ̀jẹ̀ pé: “Ó ń gbilẹ̀ nítorí pé àwọn oníṣègùn ti ń rí i pé ìṣègùn tí kò lo ẹ̀jẹ̀ ni ọ̀pá ìdiwọ̀n ìníyelórí ní àyíká tí a kò bá ti fẹ́ fi nǹkan ṣòfò. Ìrírí wa ni pé, àwọn ilé iṣẹ́ abánigbófò tí kì í sábà bá wa dòwò pọ̀, ń darí àwọn ènìyàn sọ́dọ̀ wa, nítorí pé ó ń dín ìnáwó wọn kù.”
Ó ṣe kedere pé, iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ ń yára di ìlúmọ̀ọ́ká láàárín àwọn oníṣègùn, ohun púpọ̀ ló sì ń fà á.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
Àwọn Ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ ní Lọ́ọ́lọ́ọ́
Àwọn ìdájọ́ méjì tí ilé ẹjọ́ ṣe ní ìpínlẹ̀ Illinois, U.S.A., ní November àti December 1997, gbàfiyèsí. Nínú ẹjọ́ àkọ́kọ́, a dájọ́ pé kí a san 150,000 dọ́là bí owó ìtanràn fún Mary Jones, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nítorí pé a ti fa ìgò ẹ̀jẹ̀ méjì sí i lára ní 1993 láìka kíkọ̀ tí ó kọ oríṣi ìtọ́jú yìí ní kedere sí. Èyí ni iye owó tí ó pọ̀ jù lọ tí a tíì san fún Ẹlẹ́rìí kankan nítorí ìjàǹbá tí a ṣe fún ìmọ̀lára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí fífa ẹ̀jẹ̀ tí kò fẹ́ sí i lára.
Ẹjọ́ kejì ni ti Ẹlẹ́rìí kan, Darlene Brown, aboyún tí a fipá fa ẹ̀jẹ̀ sí lára nítorí ọlẹ̀ ọlọ́sẹ̀ 34 tó wà nínú rẹ̀ nígbà náà. Ní December 31, 1997, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti Illinois ṣàlàyé ìdájọ́ tó ṣe pé, “ìfàjẹ̀sínilára jẹ́ ìlànà ìṣègùn tí ń wọ inú ara, tí ń da ìjípépé ara àgbàlagbà dídáńgájíá kan rú.” Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn náà ṣàkópọ̀ ìdájọ́ rẹ̀ nípa sísọ pé, “lábẹ́ òfin Ìpínlẹ̀ yìí, . . . a kò lè lo àìgbọdọ̀máṣe lábẹ́ òfin kankan láti fipá mú aboyún kan pé kí ó fara mọ́ ìlànà ìṣègùn kan tí ń wọnú ara.”
Ní February 9, 1998, Ilé Ẹjọ́ Gígajùlọ ti Tokyo yí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kékeré kan padà, tó ti dájọ́ pé dókítà kan jàre láti fa ẹ̀jẹ̀ sí Misae Takeda lára nígbà iṣẹ́ abẹ kan tó ṣe ní 1992. Ilé Ẹjọ́ Gígajùlọ náà kéde pé, “ó yẹ kí a bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ aláìsàn láti yan irú ìtọ́jú tí ó bá fẹ́. Kò bófin mu láti fàjẹ̀ síni lára.” Wọ́n dájọ́ pé kí a san 550,000 yen (4,200 dọ́là) bí owó ìtanràn fún Misae Takeda.