Ìtọ́jú àti Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀ Laráyé Ń Gba Tiẹ̀ Báyìí
“Àwọn tí iṣẹ́ wọ́n jẹ mọ́ ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ àtàwọn tó ń tọ́jú àwọn aláìsàn tó wá ṣe iṣẹ́ abẹ, gbogbo wọn ló yẹ kí wọ́n ronú nípa iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀.”—Dókítà Joachim Boldt, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa oògùn apàmọ̀lára, nílùú Ludwigshafen, ní Jámánì.
OHUN tí àrùn éèdì ti fojú àwọn èèyàn rí, ti sọ ọ́ di kàráǹgídá fáwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àtàwọn oníṣègùn láti rí i dájú pé iyàrá tí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ abẹ wà láìséwu. Dájúdájú, èyí ti mú kí wọ́n túbọ̀ máa yẹ ẹ̀jẹ̀ wò fínnífínní. Àmọ́ àwọn ògbógi sọ pé ìgbésẹ̀ wọ̀nyí pàápàá kò lè mú gbogbo ewu ìfàjẹ̀sínilára kúrò. Ìwé ìròyìn náà, Transfusion, sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa ènìyàn túbọ̀ ń náwó nára láti rí sí i pé ẹ̀jẹ̀ táa tọ́jú wà láìséwu, a mọ̀ pé àwọn aláìsàn yóò ṣì máa yẹra fún gbígbẹ̀jẹ̀ ẹlòmíì sára, nítorí pé kò sí báa ṣe lè pa ẹ̀jẹ̀ mọ́ láìséwu.”
Abájọ táwọn dókítà kan fi wá ń kọminú báyìí sí fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára. Dókítà Alex Zapolanski, tó wà nílùú San Francisco, ní California, sọ pé: “Táa bá ní ká sòótọ́, ìfàjẹ̀sínilára kò dáa rárá, a sì ń sa gbogbo ipá wa láti yẹra fún fífún ẹnikẹ́ni lẹ́jẹ̀.”
Ńṣe ni ojú àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò túbọ̀ ń là sí àwọn ewu ìfàjẹ̀sínilára. Àní, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lọ́dún 1996 fi hàn pé ìpín mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Kánádà ló ń fẹ́ kí wọ́n lo nǹkan míì fáwọn dípò ẹ̀jẹ̀ ẹlòmíì. Ìwé ìròyìn Journal of Vascular Surgery sọ pé: “Kì í ṣe gbogbo aláìsàn ló ń kọ gbígba ẹ̀jẹ̀ ẹlòmíì sára bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe. Síbẹ̀síbẹ̀, kékeré kọ́ ni ewu kíkó àrùn àti ewu dídabarú ètò ìgbéjàko-àrùn, a sì gbọ́dọ̀ tìtorí èyí wá àwọn nǹkan míì tí a ó lò fáwọn táà ń tọ́jú.”
Irú Ìtọ́jú Táwọn Èèyàn Yàn Láàyò
A dúpẹ́ pé ọ̀nà míì ti wà báyìí—èyí ni ìtọ́jú àti iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀. Kì í ṣe torí pé ọ̀pọ̀ aláìsàn ò rọ́nà gbé e gbà ni wọ́n fi ń yíjú sọ́nà yìí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ irú ìtọ́jú tí wọ́n yàn láàyò, ó sì nídìí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Stephen Geoffrey Pollard, tí í ṣe ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó sì jẹ́ ògbóǹkangí oníṣègùn iṣẹ́ abẹ, ṣàkíyèsí pé iye àwọn tí àìsàn ń ràn àti iye àwọn tó ń kú nínú iye àwọn tó ṣe iṣẹ́ abẹ láìgbẹ̀jẹ̀ “kò kúkú yàtọ̀ sí tàwọn tó gbẹ̀jẹ̀, ṣùgbọ́n ní tàwọn tí kò gbẹ̀jẹ̀, kì í sábàá sí àkóràn lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ, wọn kì í sì í ní àwọn ìṣòro míì tó sábà máa ń bá gbígba ẹ̀jẹ̀ rìn.”
Báwo ni ìtọ́jú láìlo ẹ̀jẹ̀ tiẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ ná? Táa bá wò ó lọ́nà kan, ìbéèrè yẹn fẹ́ jọ bí àsé, torí pé ìtọ́jú láìlo ẹ̀jẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ tipẹ́ kó tó di pé àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí lo ẹ̀jẹ̀. Àní, apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún ni ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìfàjẹ̀sínilára ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀ síwájú débi pé ó wá di ohun tí wọ́n sọ dàṣà. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn kan ti sọ iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ di ọ̀nà ìtọ́jú tó gbajúmọ̀. Fún àpẹẹrẹ, láàárín ọdún 1960 sí 1969, Denton Cooley, tó jẹ́ sànmọ̀rí oníṣègùn iṣẹ́ abẹ, wà lára àwọn tó kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ abẹ lórí ọkàn-àyà láìlo ẹ̀jẹ̀.
Nígbà tí àrùn mẹ́dọ̀wú bẹ̀rẹ̀ sí kọ lu àwọn tó gba ẹ̀jẹ̀ sára láàárín ọdún 1970 sí 1979, ló di pé ọ̀pọ̀ dókítà bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà míì tí ò la lílo ẹ̀jẹ̀ lọ. Ìgbà tó fi máa di ọdún 1980 sí 1989, àwùjọ ọ̀pọ̀ oníṣègùn ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀. Nígbà tó tún di pé àjàkálẹ̀ àrùn éèdì bẹ́ sílẹ̀, ṣe ni àwọn míì tó ń hára gàgà láti máa lo ọ̀nà ìtọ́jú yìí wá lọ ń bá àwùjọ oníṣègùn wọ̀nyí láti gba ìmọ̀ kún ìmọ̀. Láwọn ọdún 1990 sí 1999 ni ọ̀pọ̀ ọsibítù ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò ìtọ́jú tí kò jẹ mọ́ lílo ẹ̀jẹ̀ fáwọn aláìsàn wọn.
Nísinsìnyí, àwọn dókítà ti bẹ̀rẹ̀ sí lo ìlànà ìtọ́jú tí kò jẹ mọ́ ẹ̀jẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ abẹ àti nígbà ìtọ́jú pàjáwìrì, àmọ́ bó jẹ́ tẹ́lẹ̀ ni, wọn ò ní ṣàìfa ẹ̀jẹ̀ síni lára. Ọ̀gbẹ́ni D.H.W. Wong sọ nínú ìwé ìròyìn Canadian Journal of Anaesthesia pé: “Àṣeyege là ń ṣe àwọn iṣẹ́ abẹ ọkàn-àyà, ti òpójẹ̀, fun àwọn obìnrin àti èyí tó jẹ mọ́ ọmọ bíbí, ti egungun, àti ti ọ̀nà ilé ìtọ̀, gbogbo rẹ̀ là ń ṣe láìlo ẹ̀jẹ̀ tàbí ohunkóhun tó wá látinú ẹ̀jẹ̀.”
Ọ̀kan lára àwọn àǹfààní iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ ni pé ó ń gbé ìtọ́jú tó pegedé lárugẹ. Dókítà Benjamin J. Reichstein, tó jẹ́ olùdarí iṣẹ́ abẹ nílùú Cleveland, ní ìpínlẹ̀ Ohio, sọ pé: “Bí oníṣègùn bá ṣe mọṣẹ́ sí ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọ̀ràn yíyẹra fún pípàdánù ẹ̀jẹ̀.” Ìwé ìròyìn kan ní Gúúsù Áfíríkà tó dá lé ọ̀ràn òfin sọ pé nígbà míì, iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ ló máa “ń yá jù, kì í sábàá kó èèràn ranni, kò sì wọ́nwó.” Ó fi kún un pé: “Ó dájú pé ìtọ́jú lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ yìí kì í náni lówó púpọ̀, kì í sì í gba àkókò.” Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára ìdí tí nǹkan bí ọgọ́sàn-án ọsibítù kárí ayé báyìí fi ní àwọn ètò tó dá lé ìtọ́jú àti iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹ̀jẹ̀
Nítorí ohun tí Bíbélì sọ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gbẹ̀jẹ̀.a Àmọ́ wọ́n ń gba àwọn ìtọ́jú míì tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ, wọ́n sì ń fi taratara wá irú ìtọ́jú wọ̀nyí. Nígbà tí Dókítà Richard K. Spence jẹ́ olùdarí iṣẹ́ abẹ ní ọsibítù kan ní New York, ó sọ pé: “Ọ̀ràn ìtọ́jú tó dáa jù lọ jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lógún púpọ̀. Lápapọ̀, àwọn ni òye yé jù lọ nínú gbogbo àwọn aláìsàn tó wá ń gbàtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn tó ń ṣiṣẹ́ abẹ.”
Ṣe làwọn dókítà túbọ̀ ń mọṣẹ́ sí i bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká gbé ìrírí Denton Cooley yẹ̀ wò, tí í ṣe oníṣègùn tó ń ṣiṣẹ́ abẹ lórí ọkàn-àyà àti òpójẹ̀. Ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n lòun àtàwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ fi ṣe iṣẹ́ abẹ ọkàn-àyà láìlo ẹ̀jẹ̀ fún ẹ̀tàlélọ́gọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àbáyọrí rẹ̀ fi hàn kedere pé iṣẹ́ abẹ ọkàn-àyà ṣeé ṣe láṣeyọrí láìlo ẹ̀jẹ̀.
Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ti bẹnu àtẹ́ lu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí pé wọn kì í gbẹ̀jẹ̀. Àmọ́ ìwé ìtọ́ni tí Ẹgbẹ́ Àwọn Oníṣègùn Apàmọ̀lára ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ireland tẹ̀ jáde sọ pé lójú ìwòye àwọn Ẹlẹ́rìí, “ìwàláàyè ṣeyebíye.” Táwọn èèyàn bá fẹ́ sòótọ́, wọ́n á gbà pé akitiyan àwọn Ẹlẹ́rìí ni ohun pàtàkì tó ti mú kí ìtọ́jú tó gbé pẹ́ẹ́lí wà fún gbogbo èèyàn. Ọ̀jọ̀gbọ́n Stein A. Evensen, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ìwòsàn Ìjọba Norway, kọ̀wé pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wá fún iṣẹ́ abẹ ló fọ̀nà hàn wá, akitiyan wọn ló jẹ́ ká ṣe ọ̀pọ̀ àtúnṣe sí apá pàtàkì ètò ìlera ilẹ̀ Norway.”
Láti lè gbárùkù ti àwọn dókítà bí wọ́n ti ń ṣètọ́jú láìlo ẹ̀jẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣètò ìgbìmọ̀ alárinà. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, ó lé ní egbèje Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn tó wà kárí ayé, wọ́n sì wà ní sẹpẹ́ láti pèsè àwọn ìwé nípa ìṣègùn fáwọn dókítà àtàwọn olùwádìí, èyí jẹ́ àwọn ìwé látinú ìsọfúnni táa kó jọ látinú àwọn àpilẹ̀kọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìṣègùn àti iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀. Dókítà Charles Baron, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní Boston College Law School, sọ pé: “Ní ti bí nǹkan ṣe rí lónìí yìí, kì í ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo aláìsàn ni a kì í fún lẹ́jẹ̀ láìyẹ, èyí sì jẹ́ nítorí iṣẹ́ Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn táwọn Ẹlẹ́rìí dá sílẹ̀.”b
Ìsọfúnni nípa ìtọ́jú àti iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀, èyí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kó jọ, ti ṣàǹfààní fún ọ̀pọ̀ oníṣègùn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn tó ṣe ìwé tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Autotransfusion: Therapeutic Principles and Trends, ń kó ìsọfúnni wọn jọ, wọ́n ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún àwọn ní ìsọfúnni nípa àwọn ìtọ́jú míì tó ṣeé lò dípò ìfàjẹ̀sínilára. Àwọn Ẹlẹ́rìí fi tayọ̀tayọ̀ pèsè ìsọfúnni wọ̀nyí fún wọn. Àwọn òǹṣèwé náà wá fi ẹ̀mí ìmoore sọ lẹ́yìn náà pé: “Lára gbogbo ohun táa kà nípa kókó yìí, a ò tíì rí irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ rí, tó sọjú abẹ níkòó, tó sì kún rẹ́rẹ́, nípa báa ṣe lè yẹra fún ìfàjẹ̀sínilára.”
Ìtẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìṣègùn ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn yan ìtọ́jú láìlo ẹ̀jẹ̀ láàyò. Ibo ni yóò tẹ̀ síwájú dé? Ọ̀jọ̀gbọ́n Luc Montagnier, tó ṣàwárí fáírọ́ọ̀sì tó ń fa àrùn éèdì, sọ pé: “Òye wa tó túbọ̀ ń jinlẹ̀ sí i nínú iṣẹ́ yìí fi hàn pé níjọ́ ọjọ́ kan, a ò ní fàjẹ̀ sí àwọn èèyàn lára mọ́.” Ṣùgbọ́n, ní báyìí ná, àwọn nǹkan táà ń lò dípò ẹ̀jẹ̀ ń gba ẹ̀mí là.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
b Nígbà tí wọ́n bá pe àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn, wọ́n tún máa ń ṣe àpérò pẹ̀lú àwọn tí iṣẹ́ wọ́n jẹ mọ́ ìṣègùn nílé ìwòsàn. Ìyẹn nìkan kọ́, bí wọ́n bá dìídì béèrè ìrànlọ́wọ́ wọn, wọ́n máa ń ran àwọn aláìsàn lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe lè sọ èrò ọkàn wọn jáde fún oníṣègùn tó ń tọ́jú wọn, láìfọ̀rọ̀ falẹ̀, láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ohun Táwọn Dókítà Kan Sọ
‘Iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ kò wà fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan, bí kò ṣe fún gbogbo aláìsàn. Lójú tèmi, gbogbo dókítà ló yẹ kó lọ́wọ́ sí i.’—Dókítà Joachim Boldt, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa oògùn apàmọ̀lára, nílùú Ludwigshafen, ní Jámánì.
“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ewu tó wà nínú ìfàjẹ̀sínilára ti dín kù lóde òní, síbẹ̀ ewu ṣì ńbẹ o, ó ṣì ń ṣàkóbá fún ètò tí ń gbógun ti àrùn nínú ara, ó sì ń kó àrùn mẹ́dọ̀wú tàbí àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré ranni.” —Dókítà Terrence J. Sacchi, igbá kejì ọ̀jọ̀gbọ́n àgbà nípa ìmọ̀ ìṣègùn.
“Ọ̀pọ̀ dókítà ni kì í tilẹ̀ ronú lẹ́ẹ̀mejì nípa ìfàjẹ̀sínilára, ṣe ni wọ́n kàn ń fa ẹ̀jẹ̀ sáwọn èèyàn lára yàà. Èmi kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ní tèmi.”—Dókítà Alex Zapolanski, olùdarí iṣẹ́ abẹ ọkàn ní Ilé Ìtọ́jú Àrùn Ọkàn ní San Francisco.
“Lójú tèmi, táa bá wo ọ̀pọ̀ jù lọ aláìsàn, kò sí iṣẹ́ abẹ èyíkéyìí táa sábà máa ń ṣe nínú ikùn tí a ò lè ṣe láìfàjẹ̀ sí aláìsàn lára.”—Dókítà Johannes Scheele, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa iṣẹ́ abẹ, ní Jena, Jámánì.
[Àwọn àwòrán]
Dókítà Terrence J. Sacchi
Dókítà Joachim Boldt
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Ìtọ́jú àti Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀
Díẹ̀ Lára Ọ̀nà Tí Wọ́n Ń Gbà Ṣe É
Àwọn Èròjà Olómi: Àpòpọ̀ oníyọ̀ ti Ringer, dextran, táàṣì hydroxyethyl, àtàwọn èròjà míì ni wọ́n fi ń mú kí ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ wà bó ṣe wà, kí ẹ̀jẹ̀ tó wà nínú ara má bàa kéré jù, kó sì wá mú kí àwọn ẹ̀yà ara kan kọṣẹ́. Àwọn èròjà olómi kan tí wọ́n ń yẹ̀ wò lọ́wọ́ báyìí lè máa gbé afẹ́fẹ́ kiri inú ara.
Egbòogi: Àwọn èròjà purotéènì àtọwọ́dá lè ṣokùnfa ìmújáde ọ̀pọ̀ yanturu sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ (omi ìsúnniṣe inú kíndìnrín tí ń mú sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ pọ̀ sí i), àti ìmújáde àwọn sẹ́ẹ̀lì tí ń mú kí ẹ̀jẹ̀ dì (interleukin-11), àti onírúurú sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀ (GM-CSF, G-CSF). Àwọn oògùn míì kì í jẹ́ kí ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ lọọlẹ̀ púpọ̀ jù nígbà iṣẹ́ abẹ (aprotinin, antifibrinolytics), àwọn oògùn míì kì í sì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ dà púpọ̀ jù (desmopressin).
Àwọn èròjà tí ń dí ojú ibi tó ń ṣẹ̀jẹ̀: Wọ́n máa ń lẹ èròjà collagen àti cellulose tó rí bí àwọ̀n mọ́ ibi tó ń ṣẹ̀jẹ̀, kí ẹ̀jẹ̀ náà lè dá. Èròjà fibrin tó ń ṣiṣẹ́ bí àtè àtàwọn èròjà tí wọ́n fi ń dí ojú ibi tó ń ṣẹ̀jẹ̀, lè dí ojú ọgbẹ́ tàbí kó bo ojú ibi fífẹ̀, níbi tí òpójẹ̀ kan ti bẹ́.
Ṣíṣàìfi ẹ̀jẹ̀ ṣòfò: Àwọn ẹ̀rọ kan wà tí kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ ṣòfò nígbà iṣẹ́ abẹ tàbí nígbà téèyàn bá fara gbọgbẹ́. Wọ́n máa ń yọ́ ìdọ̀tí kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ yìí, bí ó ti ń ṣàn nìṣó lára aláìsàn náà. Tó bá jẹ́ ọ̀ràn tó le ni, ọ̀pọ̀ lítà ẹ̀jẹ̀ ló ṣeé dáàbò bò bí wọ́n bá lo ọ̀nà yìí.
Àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ abẹ: Àwọn ẹ̀rọ kan wà tó jẹ́ pé gbàrà tó bá gé òpójẹ̀ ló máa ń dí i. Àwọn ẹ̀rọ míì wà tó lè dí àwọn ibi fífẹ̀ tó ń ṣẹ̀jẹ̀ lára òpójẹ̀. Àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n fi ń wo inú lọ́hùn-ún àtàwọn irinṣẹ́ tó ṣeé rọra tì bọnú ara ń jẹ́ kó ṣeé ṣe láti ṣe iṣẹ́ abẹ láìpàdánù ẹ̀jẹ̀ púpọ̀, bó ti máa ń rí nígbà tí wọ́n bá gé ibi tó fẹ̀.
Ọgbọ́n tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ abẹ: Ìwéwèé tó kúnná nípa iṣẹ́ abẹ náà, títí kan fífọ̀ràn lọ àwọn onírìírí olùtọ́jú aláìsàn, máa ń ran àwọn oníṣègùn iṣẹ́ abẹ lọ́wọ́ láti yàgò fún àwọn ìṣòro dídíjú. Ó pọndandan láti tètè dí ibikíbi tó bá ń ṣẹ̀jẹ̀. Bí wọn ò bá wá nǹkan ṣe sí i lẹ́yìn wákàtí mẹ́rìnlélógún, ó lè tètè ṣekú pa aláìsàn náà. Ẹ̀jẹ̀ ò ní dà púpọ̀ jù bí wọ́n bá pín àwọn iṣẹ́ abẹ ńláńlá sọ́nà kéékèèké.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìtọ́jú Láìlo Ẹ̀jẹ̀—Ṣé Òun Ni “Ìlànà Ìtọ́jú fún Gbogbo Gbòò”?
JÍ! bá oníṣègùn mẹ́rin tó jẹ́ ògbóǹkangí sọ̀rọ̀ nípa àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìṣègùn àti iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀.
Yàtọ̀ sáwọn aláìsàn tí kì í gbẹ̀jẹ̀ nítorí ọ̀ràn ẹ̀sìn, àwọn wo ló tún ń fẹ́ ìtọ́jú tí kò la lílo ẹ̀jẹ̀ lọ?
Dókítà Spahn: Lọ́dọ̀ tiwa, àwọn aláìsàn tó mọ ohun tó ń lọ ló sábà máa ń béèrè fún ìtọ́jú tí kò la lílo ẹ̀jẹ̀ lọ.
Dókítà Shander: Ní 1998, iye àwọn aláìsàn tó sọ pé àwọn ò gbẹ̀jẹ̀, fún ìdí tó jẹ́ pé àwọn nìkan ló yé, pọ̀ ju iye àwọn aláìsàn tó sọ pé àwọn ò gbẹ̀jẹ̀ nítorí ọ̀ràn ẹ̀sìn.
Dókítà Boyd: Àpẹẹrẹ kan ni tàwọn tí àrùn jẹjẹrẹ ń ṣe. Ọ̀pọ̀ ìgbà la ti rí i pé bí wọn ò bá gbẹ̀jẹ̀, ipò wọn máa ń sunwọ̀n sí i, àìsàn náà kì í sì í tètè kì wọ́n mọ́lẹ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀.
Dókítà Spahn: A sábà máa ń tọ́jú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n láti yunifásítì àti ìdílé wọn láìlo ẹ̀jẹ̀. Àwọn oníṣẹ́ abẹ pàápàá máa ń sọ fún wa pé àwọn ò fẹ́ gbẹ̀jẹ̀ o! Fún àpẹẹrẹ, oníṣègùn kan tó ń ṣiṣẹ́ abẹ gbé ìyàwó rẹ̀ wá sọ́dọ̀ wa pé ká ṣiṣẹ́ abẹ fún un. Ó sọ pé: “Nǹkan kan ni màá bẹ̀ yín fún—ẹ jọ̀ọ́, ẹ ò gbọ́dọ̀ fún un lẹ́jẹ̀ o!”
Dókítà Shander: Àwọn òṣìṣẹ́ tó ń bá mi ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìṣègùn tó jẹ mọ́ oògùn apàmọ̀lára sọ pé: ‘Àwọn aláìsàn wọ̀nyí tí kì í gbẹ̀jẹ̀ ń gbádùn dáadáa, kódà ó tiẹ̀ jọ pé àwọn ló tètè ń gbádùn jù. Kí ló dé tó jẹ́ oríṣi ìlànà ìtọ́jú méjì là ń lò? Bó bá jẹ́ pé ìtọ́jú yìí ló dáa jù, òun ló yẹ ká máa lò fún gbogbo èèyàn.’ Fún ìdí yìí, à ń wọ̀nà fúngbà tí ìtọ́jú láìlo ẹ̀jẹ̀ yóò di ìlànà ìtọ́jú fún gbogbo gbòò.
Ọ̀gbẹ́ni Earnshaw: Òótọ́ ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn èèyàn mọ̀ mọ́ iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀. Ṣùgbọ́n, ọ̀nà ìtọ́jú yìí ló wù wá ká máa lò fún gbogbo èèyàn.
Ṣé ìtọ́jú láìlo ẹ̀jẹ̀ ló wọ́n jù àbí òun ni ò wọ́n rárá?
Ọ̀gbẹ́ni Earnshaw: Ìtọ́jú yìí ń dín ìnáwó kù.
Dókítà Shander: Ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún ni ìtọ́jú láìlo ẹ̀jẹ̀ fi dínwó sí ìtọ́jú tí wọ́n ti lo ẹ̀jẹ̀.
Dókítà Boyd: Bó tiẹ̀ ṣe tìtorí ìyẹn nìkan ni, ó tó ohun tó fi yẹ ká máa lò ó.
Ibo la ti tẹ̀ síwájú dé báyìí nínú ìtọ́jú láìlo ẹ̀jẹ̀?
Dókítà Boyd: Mo rò pé a ti lọ jìnnà gan-an. Àmọ́, ṣíṣe ṣì kù. Gbogbo ìgbà la túbọ̀ ń rí ìdí gúnmọ́ tí kò fi yẹ ká máa lo ẹ̀jẹ̀.
[Àwọn àwòrán]
Dókítà Donat R. Spahn ọ̀gá pátápátá ní ẹ̀ka ìṣègùn tó jẹ mọ́ oògùn apàmọ̀lára, láti ìlú Zurich, Switzerland
Dókítà Aryeh Shander igbá kejì ọ̀gá pátápátá ní ẹ̀ka ìṣègùn tó jẹ mọ́ oògùn apàmọ̀lára, láti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà
Ọ̀gbẹ́ni Peter Earnshaw, FRCS, ògbóǹkangí oníṣègùn nípa eegun títò, láti ìlú London, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
Dókítà Mark E. Boyd ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ẹ̀ka ìṣègùn tó jẹ mọ́ ìbímọ àti àìsàn àwọn obìnrin, láti Kánádà
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
Ojúṣe Aláìsàn
▪ Bá dókítà rẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan míì tó ṣeé lò dípò ẹ̀jẹ̀ ṣáájú kí ọ̀ràn ìtọ́jú tiẹ̀ tó wáyé rárá. Èyí ṣe pàtàkì, àgàgà fáwọn aboyún, àwọn òbí ọlọ́mọ wẹ́wẹ́, àtàwọn àgbàlagbà.
▪ Kọ ohun tóo fẹ́ sínú ìwé, pàápàá bí àkọsílẹ̀ tó bófin mu bá wà fún ète yẹn.
▪ Bí oníṣègùn rẹ kò bá fẹ́ tọ́jú rẹ láìlo ẹ̀jẹ̀, wá oníṣègùn míì tí yóò ṣe ohun tóo fẹ́.
▪ Níwọ̀n bí àwọn nǹkan míì tí wọ́n ń lò dípò ẹ̀jẹ̀ ti máa ń pẹ́ díẹ̀ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára, má ṣe sún àkókò tó yẹ kóo lọ gba ìtọ́jú síwájú, bóo bá mọ̀ pé ó lè la ọ̀ràn iṣẹ́ abẹ lọ.