Ó Pẹ́ Tí Ìfàjẹ̀sínilára Ti Ń Fa Arukutu
“Ká ní oògùn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dóde ni sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ ni, ì bá nira gan-an láti ríwèé àṣẹ gbà fún un.”—Dókítà Jeffrey McCullough.
NÍGBÀ òtútù ọdún 1667, wọ́n gbé wèrè jáwéjura kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Antoine Mauroy wá sọ́dọ̀ Jean-Baptiste Denis, sànmọ̀rí oníṣègùn tó ń tọ́jú Ọba Louis Kẹrìnlá tí í ṣe ọba ilẹ̀ Faransé. Denis sọ pé òun ní “oògùn” ajẹ́bíidán tóun máa fi wo wèrè tó ń ṣe Mauroy sàn—ó lóun máa fa ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù sí i lára, ó rò pé ìyẹn á jẹ́ kí ara aláìsàn yìí balẹ̀. Àmọ́ wèrè Mauroy kò ṣeé wò. Òtítọ́ ni pé nígbà tó fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára lẹ́ẹ̀kejì, ara rẹ̀ balẹ̀ díẹ̀. Àmọ́ kò pẹ́ tí aṣiwèrè ará Faransé yìí tún fi já, tí kò ṣeé mú so, kò sì pẹ́ tó fi kú.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó pẹ́ káwọn èèyàn tó mọ̀ pé májèlé arsenic gan-an ló pa Mauroy, ìtọ́jú tí Denis fi ẹ̀jẹ̀ ẹran ṣe yìí fa arukutu nílẹ̀ Faransé. Àbárèbábọ̀ rẹ̀ ni pé, wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ọ̀nà ìtọ́jú yẹn lọ́dún 1670. Bí àkókò ti ń lọ, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti póòpù pàápàá gbẹ́sẹ̀ lé ọ̀nà ìtọ́jú yẹn. Bí ìfàjẹ̀sínilára ṣe dohun ìgbàgbé fún àádọ́jọ ọdún tó tẹ̀ lé e nìyẹn.
Àwọn Ewu Tó Kọ́kọ́ Yọjú
Nígbà tó tún di ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ni ìfàjẹ̀sínilára tún yọ kúlẹ́. Ẹni tó mú ìfàjẹ̀sínilára padà wáyé ni James Blundell, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń ṣiṣẹ́ agbẹ̀bí. Nítorí pé Blundell mú ọ̀nà ìtọ́jú yìí dán mọ́rán sí i, tó sì lo àwọn àgbà irinṣẹ́—àti pé ó fi dandan lé e pé ẹ̀jẹ̀ èèyàn nìkan ni kí wọ́n máa lò—òun ló mú kí ìfàjẹ̀sínilára tún gba àfiyèsí aráyé.
Àmọ́ lọ́dún 1873, dókítà ará Poland náà, F. Gesellius, tún fẹ́ tẹ ìfàjẹ̀sínilára rì nígbà tó ṣe àwárí tó ń dáyà jáni nípa rẹ̀: Iye tó lé ní ìdajì gbogbo àwọn tí wọ́n fàjẹ̀ sí lára ló kú. Nígbà táwọn sànmọ̀rí oníṣègùn gbọ́ èyí, ṣe ni wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí bẹnu àtẹ́ lu ọ̀nà ìtọ́jú yìí. Bí ìfàjẹ̀sínilára tún ṣe wọ̀ọ̀kùn nìyẹn o.
Ìgbà tó wá di ọdún 1878, ni oníṣègùn ọmọ ilẹ̀ Faransé nì, Georges Hayem, parí iṣẹ́ lórí àpòpọ̀ oníyọ̀ kan, ó sì sọ pé èèyàn lè lò ó dípò ẹ̀jẹ̀. Àpòpọ̀ oníyọ̀ yìí kò dà bí ẹ̀jẹ̀, ní ti pé kì í ṣeni ní jàǹbá kankan, kì í dì, kò sì ṣòro láti gbé kiri. Ìdí rèé táwọn èèyàn kárí ayé fi bẹ̀rẹ̀ sí lo àpòpọ̀ oníyọ̀ tí Hayem ṣe. Ṣùgbọ́n ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ nígbà táwọn èèyàn tún ń sọ pé àwọn fẹ́ padà sídìí lílo ẹ̀jẹ̀. Èé ṣe?
Lọ́dún 1900, Karl Landsteiner, tí í ṣe ọmọ ilẹ̀ Austria, tó sì jẹ́ onímọ̀ nípa àrùn inú ara, ṣàwárí pé ẹ̀jẹ̀ pín sí onírúurú, ó sì rí i pé irú ẹ̀jẹ̀ kan kì í sábàá bá òmíràn mu. Abájọ tí àwọn tí wọ́n fàjẹ̀ sí lára láyé ọjọ́un fi kàgbákò! Gbogbo ìyẹn ò ní ṣẹlẹ̀ mọ́ báyìí, tí wọ́n bá sáà ti rí i dájú pé ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n fi tọrẹ bá tẹni tí wọ́n fẹ́ fàjẹ̀ sí lára mu. Èyí táwọn oníṣègùn gbọ́ yìí ló tún jẹ́ kí wọ́n padà sídìí ìfàjẹ̀sínilára—ó tún wá lọ bọ́ sí sáà ìbẹ̀rẹ̀ Ogun Àgbáyé Kìíní.
Ìfàjẹ̀sínilára àti Ogun
Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, yàà ni wọ́n ń fa ẹ̀jẹ̀ sára àwọn jagunjagun tó fara pa. Ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ̀ kì í pẹ́ dì, bó bá sì jẹ́ ayé ìgbà kan ni, kì bá sọ́nà tí wọn ì bá fi gbé e dójú ogun. Àmọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, Dókítà Richard Lewisohn, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ìwòsàn Mount Sinai ní Ìlú New York, ṣe àṣeyẹ̀wò kan tó kẹ́sẹ járí, ó lo èròjà tí wọ́n ń pè ní sodium citrate tí kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ dì. Àfi bí ẹní pidán ni àwárí tuntun yìí rí lójú àwọn dókítà kan. Dókítà Bertram M. Bernheim, tó jẹ́ sànmọ̀rí oníṣègùn nígbà ayé rẹ̀, sọ pé: “Ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ti mú kí oòrùn dúró sójú kan.”
Ogun Àgbáyé Kejì ló tún jẹ́ kí ìlò ẹ̀jẹ̀ pọ̀ sí i. Ṣe ni wọ́n lẹ àwọn ọ̀rọ̀ amóríwú káàkiri ìgboro, àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Tètè Lọ Fẹ̀jẹ̀ Rẹ Tọrẹ,” “Ẹ̀jẹ̀ Rẹ Lè Gba Ẹ̀mí Ẹnì Kan Là,” àti “Ó Fẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ Tọrẹ. Ṣé Ìwọ Náà Á Fi Tìẹ Tọrẹ?” Ìpè náà ṣiṣẹ́, ńṣe làwọn èèyàn ń wọ́ wá láti fẹ̀jẹ̀ tọrẹ. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, nǹkan bí ìwọ̀n bílíọ̀nù mẹ́fà ààbọ̀ mìlílítà ẹ̀jẹ̀ ni wọ́n gbà jọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n ní ní London, lítà ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà jọ, tí wọ́n sì pín kiri, lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́tàlá. Láìṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa sọ ọ́, ìfàjẹ̀sínilára ń ṣe ọ̀pọ̀ ìpalára, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wá rí i láìpẹ́ láìjìnnà.
Àrùn Tí Àwọn Ènìyàn Ń Kó Nínú Ẹ̀jẹ̀
Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ìtẹ̀síwájú ńláǹlà nínú iṣẹ́ ìṣègùn wá mú kí á lè ṣe àwọn iṣẹ́ abẹ táwọn èèyàn rò pé kò lè ṣeé ṣe láé. Ìgbà yìí ni wọ́n dá iléeṣẹ́ kan sílẹ̀ kárí ayé, tó ń pa ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún, iléeṣẹ́ yìí ló ń tọ́jú ẹ̀jẹ̀ pa mọ́, èyí táwọn oníṣègùn fẹ́ sọ di ohun tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ nínú iṣẹ́ abẹ, fún fífà síni lára.
Àmọ́ o, ká tó wí ká tó fọ̀, ọ̀ràn àrùn tí ìfàjẹ̀sínilára ń fà ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ àwọn èèyàn lóminú. Fún àpẹẹrẹ, nígbà Ogun Ilẹ̀ Korea, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín méjìlélógún nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí wọ́n fa omi inú ẹ̀jẹ̀ sí lára tó kó àrùn mẹ́dọ̀wú—èyí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po mẹ́ta ti ìgbà Ogun Àgbáyé Kejì. Láàárín ọdún 1970 sí 1979, Ibùdó fún Ìkáwọ́ Àrùn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣírò pé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ló ń kú lọ́dọọdún nítorí àrùn mẹ́dọ̀wú tí wọ́n kó nígbà tí wọ́n fàjẹ̀ sí wọn lára. Àwọn míì tiẹ̀ sọ pé ìlọ́po mẹ́wàá iye yẹn ni.
Nítorí yíyẹ ẹ̀jẹ̀ wò dáadáa àti títúbọ̀ fẹ̀sọ̀ ṣe àṣàyàn àwọn tó ń fẹ̀jẹ̀ tọrẹ, iye àwọn tí ń kó àrùn nínú àwọn ẹ̀jẹ̀ tó ní àrùn mẹ́dọ̀wú ipele B ti dín kù. Ṣùgbọ́n oríṣi tuntun fáírọ́ọ̀sì náà, tó máa ń pààyàn—táa mọ̀ sí àrùn mẹ́dọ̀wú ipele C—ti bẹ̀rẹ̀ sí kọlu ọ̀pọ̀ èèyàn. Wọ́n sọ pé ó tó mílíọ̀nù mẹ́rin àwọn ará Amẹ́ríkà tí fáírọ́ọ̀sì náà ti ràn, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn yìí ló kó àrùn náà nígbà tí wọ́n fàjẹ̀ sí wọn lára. Òtítọ́ ni pé ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àyẹ̀wò fínnífínní dín ìtànkálẹ̀ àrùn mẹ́dọ̀wú ipele C kù. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń ba àwọn kan pé àwọn ewu tuntun yóò yọjú, ẹ̀pa ò sì ní bóró mọ́ nígbà tó bá ti bẹ̀rẹ̀ sí jà ràn-ìn.
Àṣírí Míì Tú: Àwọn Ẹ̀jẹ̀ Kan Ní Fáírọ́ọ̀sì Tí Ń Fa Àrùn Éèdì
Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1980 ni wọ́n ti rí i pé fáírọ́ọ̀sì tó ń fa àrùn éèdì, lè wọnú ẹ̀jẹ̀. Inú kọ́kọ́ bí àwọn iléeṣẹ́ tí ń tọ́jú ẹ̀jẹ̀ nígbà táwọn èèyàn ń sọ pé kòkòrò àrùn lè ti wọ ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n dì pa mọ́. Ọ̀pọ̀ wọn ò kọ́kọ́ kọbi ara sí ìkìlọ̀ nípa fáírọ́ọ̀sì tí ń fa àrùn éèdì. Dókítà Bruce Evatt tiẹ̀ sọ pé, “ńṣe ló dà bí ìgbà tí àtọ̀húnrìnwá kan já wọ̀lú látinú aginjù, tó ní, ‘mo rí àwọn ará ọ̀run.’ Wọ́n ní àkíìkà, ṣùgbọ́n wọn ò gbà á gbọ́.”
Àmọ́, ńṣe ni àṣírí wá bẹ̀rẹ̀ sí tú ní orílẹ̀-èdè kan tẹ̀ lé òmíràn, pé fáírọ́ọ̀sì tí ń fa àrùn éèdì ti wà nínú àwọn ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n dì pa mọ́. Nílẹ̀ Faransé, wọ́n sọ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà sí mẹ́jọ èèyàn ló ti kó fáírọ́ọ̀sì tí ń fa àrùn éèdì nínú ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n fà sí wọn lára láàárín ọdún 1982 àti 1985. Ìfàjẹ̀sínilára ló ń fa ìpín mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí fáírọ́ọ̀sì tí ń fa àrùn éèdì ń ràn ní Áfíríkà àti ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí àrùn éèdì ń ràn ní ilẹ̀ Pakistan. Lónìí, nítorí àyẹ̀wò fínnífínní, àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ kó fáírọ́ọ̀sì tí ń fa àrùn éèdì mọ́ nípasẹ̀ ìfàjẹ̀sínilára ní àwọn ilẹ̀ ọlọ́rọ̀. Àmọ́, ó ṣì ń ran àwọn èèyàn gan-an ní àwọn ilẹ̀ tó tòṣì, níbi tí kò ti sí àyẹ̀wò.
Ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé láìpẹ́ yìí, ọkàn àwọn èèyàn wá túbọ̀ ń fà sí ìtọ́jú àti iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀. Ṣùgbọ́n o, ṣé òun náà ò méwu dání ni?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Ìfàjẹ̀sínilára—Àwọn Oníṣègùn Ò Ní Ìlànà Pàtó
Lọ́dọọdún, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan, ó lé ní bílíọ̀nù márùn-ún ààbọ̀ mìlílítà sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ń fà sí mílíọ̀nù mẹ́ta aláìsàn lára. Pẹ̀lú bí iye yẹn ti pọ̀ tó, ńṣe lèèyàn máa rò pé ìlànà pàtó wà táwọn oníṣègùn ń tẹ̀ lé nínú ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ lílò. Ṣùgbọ́n, ìwé ìròyìn The New England Journal of Medicine sọ pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí àkọsílẹ̀ “tó ń darí ìpinnu tó jẹ mọ́ ìfàjẹ̀sínilára.” Àní, kálukú kàn ń ṣe bó ṣe wù ú ni, kì í ṣe kìkì nípa ohun tí wọ́n ń fà síni lára àti bó ṣe pọ̀ tó, ṣùgbọ́n ẹnu wọn ò tún kò nípa bóyá ó tilẹ̀ yẹ kí wọ́n fàjẹ̀ síni lára rárá. Ìwé ìròyìn ìṣègùn náà, Acta Anæsthesiologica Belgica, sọ pé: “Yálà èèyàn gbẹ̀jẹ̀ tàbí kò gbẹ̀jẹ̀ sinmi lórí irú dókítà tó bá pàdé, kò sinmi lórí irú àìsàn tó ń ṣe onítọ̀hún.” Lójú ìwòye ohun tó wà lókè yìí, kò yani lẹ́nu pé ìwádìí kan tí wọ́n tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn The New England Journal of Medicine sọ pé “nǹkan bí ìpín mẹ́rìndínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èèyàn tí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sí lára ni kò yẹ kí wọ́n fún lẹ́jẹ̀ rárá.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ogun Àgbáyé Kejì ló tún jẹ́ kí ìlò ẹ̀jẹ̀ pọ̀ sí i
[Àwọn Credit Line]
Imperial War Museum, London
Àwọn fọ́tò U.S. National Archives