Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀—Àpẹẹrẹ Kan Tó Yọrí Sí Rere
Lẹ́yìn tí a tẹ ẹ̀dà Jí!, January 8, 2000, jáde tó sọ nípa ìtọ́jú àti iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀, àwọn olóòtú ìwé ìròyìn náà gba lẹ́tà ìṣírí yìí.
“Ẹ̀dà Jí! yìí rán èmi àti ọkọ mi létí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọbìnrin wa, Janice. Gbàrà tí a bí i tán, wọ́n ṣàwárí pé ó ní oríṣi àrùn márùn-ún tí ó jẹ́ ti ọkàn. Èyí tí ó le jù lọ níbẹ̀ ni ti àwọn lájorí òpójẹ̀ tó ṣípò padà.a Níwọ̀n bí ó ti gba kí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ́ fún un, a wá dókítà kan tó ń tọ́jú àrùn àwọn ọmọdé lọ tó sì jẹ́ oníṣẹ́ abẹ ọkàn ní Buffalo, New York, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, tó gbà láti ṣiṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀.
“Nígbà tí Janice wà lọ́mọ oṣù mẹ́rin ni wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ àkọ́kọ́ fún un—iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ṣe láìla ọkàn-àyà rẹ̀, ìdí tí wọ́n fi ṣe é jẹ́ láti dín ṣíṣàn ẹ̀jẹ̀ lọ sínú ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀ kù. Oṣù márùn-ún lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ kejì fún un—lọ́tẹ̀ yìí wọ́n la ọkàn-àyà rẹ̀ láti mú kí ṣíṣàn ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ́. Wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ méjèèjì láìlo ẹ̀jẹ̀, wọ́n sì yọrí sí rere!
“Janice ti pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún báyìí ara rẹ̀ sì le dáadáa. A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ abẹ, tí wọ́n gbóyà, tí wọ́n múra tán láti bọ̀wọ̀ fún ìdúró wa nípa ẹ̀jẹ̀. Lóòótọ́, ohun tí ẹ pè wọ́n nínú ìtẹ̀jáde January 8, yẹn gan-an ni wọ́n jẹ́, ‘Àwọn Òléwájú Nínú Iṣẹ́ Ìṣègùn.’ Ní ìdáhùn sí ìbéèrè tó wà nínú ìwé ìròyìn yẹn pé, Iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ ha fini lọ́kàn balẹ̀ bí? a lè fi ìdánilójú dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, ó fini lọ́kàn balẹ̀!”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ni pé, òpójẹ̀ ńlá tó ń gbé ẹ̀jẹ̀ láti ọkàn lọ sí àwọn òpójẹ̀ kéékèèké tó lọ káàkiri ara kúrò ní àyè rẹ̀ lọ sí àyè òpójẹ̀ tó ń gbé ẹ̀jẹ̀ látinú ọkàn lọ sínú ẹ̀dọ̀fóró. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀jẹ̀ tó ní afẹ́fẹ́ oxygen nínú tó yẹ kó máa lọ sínú ara kàn ń lọ sínú ẹ̀dọ̀fóró ni. A sọ nípa irú ìṣòro yẹn nínú ìtẹ̀jáde wa ti April 8, 1986, ojú ìwé 18 sí 20 [Gẹ̀ẹ́sì].