Wọn Ṣe Ohun Ti Wọn Lè Ṣe
Bi o tilẹ jẹ pe wọn kò lè san asanpada fun Jehofa fun gbogbo ohun ti o fi ṣanfaani fun wọn, ọpọlọpọ nṣe ohun ti wọn lè ṣe lati ṣe itilẹhin fun iṣẹ iwaasu kari aye ti awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀. (Matiu 24:14; fiwe Maaku 14:3-9.) Ohun ti o dunmọni ninu ọran yii ni ti lẹta kan lati ọdọ idile kan ni Minnesota, U.S.A.:
“Ẹyin Arakunrin Ọwọn,
“Awa nfi iye owo itọrẹ kan tii ṣe $— ranṣẹ si yin. Awa nbeere pe ki a lo o fun inawo iṣẹ naa kari aye tabi ki a lo o gẹgẹ bi Owo Akanlo fun Kikọ Gbọngan Ijọba, tabi fun awọn aini miiran ti eto-ajọ naa lè ni. . . .
“Awa ni igbẹkẹle pe owo yii ni ẹ o lo ni ibamu pẹlu ifẹ [Jehofa]. Awa yoo fẹ lati lo anfaani yii ni fifun yin ni iṣiri lati maa baa lọ ninu iṣẹ rere naa, ati ni pataki lati dupẹ lọwọ yin fun teepu fidio nipa ọna igbaṣiṣẹ [Watch Tower] Society yika aye. Teepu yii ni o jẹ ki awa mọ titobi iṣẹ naa, ti ó sì tẹ ẹ mọ wa lọkan pe awọn itọrẹ afinnufindọṣe wa ni a nilo. Tẹlẹtẹlẹ, awa ti jẹ ki ijọ, ayika, ati agbegbe maa bojuto fifi awọn itọrẹ ranṣẹ si yin, ṣugbọn awa nisinsinyi dupẹ lọwọ Jehofa fun mimu suuru pẹlu wa ninu airiran ri ọkankan wa tó ati fifihan wa lọna onifẹẹ lati ṣeranwọ ninu ọran inawo lẹnikọọkan fun iṣẹ igbẹmila yii, ni afikun si awọn oniruuru itọrẹ ti a ti ṣe. Awa npinnu lati fi ranṣẹ si yin, gẹgẹ bi idile kan, o kere tan $— loṣu kan . . . ni taarata si New York.
“Lẹẹkansii, a dupẹ fun iṣẹ isin rere ti ẹ ti nṣe fun wa ati iṣotitọ si Jehofa ti ẹyin ti ṣaṣefihan rẹ̀.”