MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ̀bùn Tá A Mú Dání Wá fún Jèhófà
Báwo lẹ́nì kan ṣe lè mú ẹ̀bùn dání wá fún Jèhófà lónìí? (1Kr 29:5, 9, 14) Tá a bá fẹ́ fí ọrẹ àtinúwá ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe bóyá fún ìjọ tàbí fún iṣẹ́ kárí ayé, oríṣiríṣi ọ̀nà tó wà nísàlẹ̀ yìí la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.
ỌRẸ TÁ A FI RÁNṢẸ́ LÓRÍ ÌKÀNNÌ TÀBÍ ÈYÍ TÁ A FI SÍNÚ ÀPÓTÍ:
IṢẸ́ KÁRÍ AYÉ
a máa ń fi kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì, ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè, a sì máa ń fi tún wọn ṣe
àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run
àwọn tó wà nínú àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún
ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá
títẹ ìwé, fídíò àti àwọn ìtẹ̀jáde orí ìkànnì
ỌRẸ FÚN ÌNÁWÓ ÌJỌ
àwọn ìnáwó ìjọ, irú bí owó iná, owó omi àti àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba
àwọn ìpinnu tí ìjọ ti ṣe láti fi iye owó kan pàtó ránṣẹ́ sí ètò Ọlọ́run fún:
kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ kárí ayé
Ètò Ìrànwọ́ Kárí Ayé
àwọn iṣẹ́ kárí ayé míì
ÀWỌN ÀPÉJỌ ÀYÍKÁ ÀTI ÀGBÈGBÈ
A máa ń fi àwọn ọrẹ tá a ṣe nígbà àpéjọ àgbègbè ránṣẹ́ fún iṣẹ́ kárí ayé. Inú ọrẹ kárí ayé la ti máa ń mú owó tá a ná lórí àpéjọ àgbègbè, àkànṣe àpéjọ àti àpéjọ àgbáyé.
Àwọn ọrẹ tá a ṣe nígbà àpéjọ àyíká la máa ń fi sanwó ibi tá a ti ń ṣe àpéjọ, a máa ń fi tún ibẹ̀ ṣe, a sì fi ń ṣe àwọn nǹkan míì tó bá yẹ. Àyíká kan sì lè pinnu láti fi owó tó bá ṣẹ́ kù ránṣẹ́ sí ètò Ọlọ́run fún iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé.