ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwfq àpilẹ̀kọ 12
  • Ibo Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ń Rówó Tí Wọ́n Ń Ná?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibo Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ń Rówó Tí Wọ́n Ń Ná?
  • Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Ń Ṣètọrẹ
  • “Ẹ̀bùn Tá A Mú Dání Wá fún Jèhófà”
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Ẹ̀bùn Wo La Lè Fún Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Èló Ni Kí N Fi Ṣètọrẹ Fún Iṣẹ́ Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • ‘Ẹyọ Owó Kéékèèké Méjì’ Tó Níye Lórí
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
Àwọn Míì
Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
ijwfq àpilẹ̀kọ 12
Obìnrin kan ń fowó sínú àpótí ọrẹ.

Ibo Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ń Rówó Tí Wọ́n Ń Ná?

Ọrẹ àtinúwá táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ló pọ̀ jù lára owó tá à ń ná lórí iṣẹ́ wa kárí ayé.a Àpótí ọrẹ máa ń wà láwọn ilé ìpàdé wa, èèyàn tún lè ṣètìlẹyìn ní apá tá a pè ní Ọrẹ lórí ìkànnì wa. Oríṣiríṣi ọ̀nà lẹnì kan lè gbà fi owó ránṣẹ́ níbẹ̀, yálà láti ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé tàbí fún ìnáwó ìjọ, ó sì lè jẹ́ fún méjèèjì.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í san ìdámẹ́wàá, wọn ò sì retí pé kéèyàn ya iye kan sọ́tọ̀ láti máa fi ṣètìlẹyìn. (2 Kọ́ríńtì 9:7) A ò kì í gbé igbá ọrẹ tàbí gba owó ìwọlé, bákan náà àwọn òjíṣẹ́ wa kì í gbowó tí wọ́n bá ṣèrìbọmi fún ẹnì kan, tí wọ́n bá bójú tó ètò ìsìnkú, tí wọ́n bá so tọkọtaya pọ̀ tàbí tí wọ́n bá darí àwọn ètò ìsìn míì. A kì í ná ọjà bàsá, a kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tàbí àjọ̀dún láti fi kówó jọ, a kì í sì í tọrọ owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. A kì í kéde orúkọ àwọn tó bá ṣètìlẹyìn. (Mátíù 6:2-4) A kì í bá àwọn oníṣòwò polówó ọjà lórí ìkànnì wa tàbí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa.

Oṣooṣù làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ka ìsọfúnni nípa bí wọ́n ṣe náwó nínú ìjọ. Wọ́n máa ń tọ́jú àkọsílẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń náwó, wọ́n sì ń ṣàyẹ̀wò ẹ̀ lóòrèkóòrè kí wọ́n lè rí i pé wọ́n ná owó táwọn èèyàn fi ṣètìlẹyìn bó ṣe yẹ.—2 Kọ́ríńtì 8:20, 21.

Bá A Ṣe Ń Ṣètọrẹ

  • Àpótí ọrẹ: A máa ń fi owó tàbí sọ̀wédowó sínú àpótí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ tàbí àwọn ibi míì tá a ti ń ṣèpàdé.

  • Ọrẹ látorí íńtánẹ́ẹ̀tì: Lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè, èèyàn lè fowó ránṣẹ́, èèyàn lè lo káàdì tí wọ́n fi ń rajà tàbí èyí tí wọ́n fi ń gba owó ní báǹkì, èèyàn sì lè lo àwọn ọ̀nà míì láti ṣètìlẹyìn ní abala “Ṣe Ọrẹ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà” lórí ìkànnì wa.b Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan máa ń ṣètò pé kí wọ́n máa yọ iye kan pàtó nínú owó wọn lóṣooṣù látorí ọ̀kan lára àwọn apá tó wà lórí ìkànnì wa.​—1 Kọ́ríńtì 16:2.

    Ọkùnrin kan ń wo abala ‘Ṣe Ọrẹ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà’ lórí ìkànnì jw.org.
  • Ọrẹ téèyàn ṣètò sílẹ̀: Àwọn ọrẹ kan gba pé kéèyàn ṣètò ẹ̀ sílẹ̀ tàbí kéèyàn fi tó agbẹjọ́rò létí. Ó ṣeé ṣe kírú ètò bẹ́ẹ̀ dín owó orí tẹ́nì kan máa san kù tàbí kẹ́ni náà má tiẹ̀ san án rárá. Ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé ó máa ṣe àwọn láǹfààní táwọn bá ṣètò láti máa fi ohun ìní àwọn ṣètìlẹyìn nígbà táwọn ṣì wà láàyè tàbí kó di tẹlòmíì táwọn bá kú. O lè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí rẹ tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè fowó ránṣẹ́ nípasẹ̀:

    • àkáǹtì owó ní báǹkì

    • owó ìbánigbófò àti owó ìfẹ̀yìntì

    • ilẹ̀ àti ilé

    • ìpín ìdókòwò, ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ètò ẹ̀yáwó

    • ìwé ìhágún àti ohun ìní téèyàn fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́

Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ọ̀nà míì tó o lè gbà fi owó ṣètìlẹyìn ládùúgbò rẹ, lọ sí abala “Ṣe Ọrẹ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

a Ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà lè fi owó ránṣẹ́ láti ti iṣẹ́ wa lẹ́yìn.

b Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo fídíò Àlàyé Lórí Bá A Ṣe Lè Fi Ọrẹ Ṣètìlẹ́yìn Látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́