ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w18 November ojú ìwé 32
  • Ẹ̀bùn Wo La Lè Fún Jèhófà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀bùn Wo La Lè Fún Jèhófà?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ̀bùn Tá A Mú Dání Wá fún Jèhófà”
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • ‘Ẹyọ Owó Kéékèèké Méjì’ Tó Níye Lórí
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Ibo Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ń Rówó Tí Wọ́n Ń Ná?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • A Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Jèhófà Torí Ìfẹ́ Tẹ́ Ẹ̀ Ń Fi Hàn
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
w18 November ojú ìwé 32
donate.jw.org

Ẹ̀bùn Wo La Lè Fún Jèhófà?

JÉSÙ sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn tó bá kan àwọn ohun tá à ń fún Jèhófà. Kí nìdí? Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti fún wa tó ń jẹ́ ká láyọ̀, àmọ́ ayọ̀ wa máa pọ̀ sí i tá a bá ń fún Jèhófà náà ní nǹkan. Ẹ̀bùn wo la lè fún Jèhófà? Òwe 3:9 sọ pé: “Fi àwọn ohun ìní rẹ tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà.” Lára ‘àwọn ohun ìní wa tí ó níye lórí’ ni àkókò wa, ẹ̀bùn àbínibí wa, okun wa àtàwọn nǹkan tara tá a ní. Tá a bá ń lo àwọn ohun tá a ní yìí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, à ń fún Jèhófà lẹ́bùn nìyẹn, ó sì dájú pé a máa ní ayọ̀ tí kò ṣeé díwọ̀n.

Kí ló máa jẹ́ ká máa fún Jèhófà láwọn ohun ìní wa fàlàlà? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé kí wọ́n “ya ohun kan sọ́tọ̀ gedegbe” tí wọ́n á fi ṣe ìtọrẹ. (1 Kọ́r. 16:2) Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè ṣètọrẹ ní àgbègbè rẹ, wo àpótí tó wà nísàlẹ̀ yìí.

Kì í ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè lèèyàn ti lè ṣètọrẹ lórí ìkànnì. Àmọ́, ní abala donate.jw.org, ẹ̀ẹ́ rí àlàyé tá a ṣe nípa àwọn ọ̀nà míì téèyàn lè gbà ṣètọrẹ. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, a ní abala kan lórí ìkànnì wa tó dáhùn àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa béèyàn ṣe lè ṣètọrẹ.

Ọ̀nà Tó Rọrùn Láti Fi Owó Ṣètọrẹ Lórí Ìkànnì

Ó RỌRÙN LÁTI RÍ

  • Ètò tó ń gbéni lọ sórí ìkànnì

    Tẹ ọ̀rọ̀ náà, donate.jw.org sórí ètò tó ń gbéni lọ sórí ìkànnì

  • JW Library

    Lọ́wọ́ ìsàlẹ̀ ojúde ètò ìṣiṣẹ́ JW Library®, tẹ ìlujá “Donations”

Ó RỌRÙN LÁTI LÒ

O lè ṣètọrẹ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo tàbí kó o ṣètò àtimáa ṣe é lóṣooṣù fún ìtìlẹyìn:

  • Iṣẹ́ Kárí Ayé

  • Ìjọ Rẹ

  • Àpéjọ Àgbègbè

  • Àpéjọ Àyíká

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́