ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w18 November ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó O Ṣe Lè Wá Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Nínú Bíbélì Rẹ
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìgbà Wo Ni Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Àtijọ́ Run?—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àtẹ Àwọn Ọjọ́ Ìṣẹ̀lẹ̀
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Ọba Méjì wọ Gídígbò
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
w18 November ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Àwọn wo ni àwọn Olóore tí Jésù mẹ́nu kàn ní alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, kí sì nìdí tí wọ́n fi ń fáwọn èèyàn ní oyè yìí?

Olóore kan láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì

Ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Jésù kú, ó kìlọ̀ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí ẹnikẹ́ni nínú wọn má ṣe máa wá ipò ọlá. Ó sọ fún wọn pé: “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn tí wọ́n sì ní ọlá àṣẹ lórí wọn ni a ń pè ní àwọn Olóore. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀yin kò ní jẹ́ bẹ́ẹ̀.”​—Lúùkù 22:​25, 26.

Àwọn wo ni Olóore tí Jésù ń sọ? Àwọn àwòrán àti ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbẹ́ sára ilé, ẹyọ owó àtàwọn ìkọ̀wé fi hàn pé àwọn Gíríìkì àtàwọn ará Róòmù máa ń fi oyè Euergetes, ìyẹn Olóore dá àwọn sàràkí-sàràkí àtàwọn alákòóso lọ́lá. Wọ́n ń fún wọn ní oyè yìí torí nǹkan ribiribi tí wọ́n ṣe fún àwọn aráàlú.

Àwọn ọba kan wà tí wọ́n fún ní oyè yìí. Lára wọn ni Olóore Tọ́lẹ́mì Kẹta (nǹkan bíi 247 sí 222 Ṣ.S.K.) àti Olóore Kejì Tọ́lẹ́mì Kẹjọ (nǹkan bíi 147 sí 117 Ṣ.S.K.) tí wọ́n jẹ́ alákòóso Íjíbítì. Àwọn míì ni Júlíọ́sì Késárì (48 sí 44 Ṣ.S.K.) àti Ọ̀gọ́sítọ́sì (31 Ṣ.S.K. sí 14 S.K.) tí wọ́n jẹ́ alákòóso Róòmù. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n fún Hẹ́rọ́dù Ńlá tó jẹ́ ọba Jùdíà ní oyè yìí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé ó kó wíìtì wọ̀lú nígbà tí ìyàn mú tó sì fún àwọn aláìní láṣọ.

Adolf Deissmann tó jẹ́ onímọ̀ nípa Bíbélì sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni wọ́n fún ní oyè Olóore nígbà yẹn. Ó sọ pé: “Wọ́n sábà máa ń fún àwọn èèyàn ní oyè yìí débi pé téèyàn bá ń ka àwọn àwòrán àti ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbẹ́ sára ilé láyé ìgbà yẹn, kò ní pẹ́ táá fi rí ọgọ́rùn-ún èèyàn tí wọ́n fún ní oyè náà.”

Kí wá ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin kò ní jẹ́ bẹ́ẹ̀”? Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé kí wọ́n má lọ́wọ́ sóhun tó lè ṣe àwọn aráàlú láǹfààní tàbí kí wọ́n má rí tàwọn èèyàn rò? Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ohun tí Jésù fẹ́ tẹnu mọ́ ni ohun tó ń mú káwọn èèyàn máa ṣe oore.

Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn olówó máa ń fẹ́ káwọn èèyàn kan sárá sí wọn. Torí náà, wọ́n máa ń ṣe agbátẹrù àwọn eré ìdárayá àtàwọn géèmù ní gbọ̀ngàn ìwòran, wọ́n máa ń kọ́ tẹ́ńpìlì àtàwọn ibi téèyàn ti lè gbafẹ́, wọ́n sì máa ń ṣe oríṣiríṣi nǹkan míì. Àmọ́, ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn gba tiwọn, wọ́n fẹ́ lókìkí tàbí káwọn èèyàn dìbò fún wọn. Ìwé ìwádìí kan sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé tinútinú làwọn kan fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí, síbẹ̀ torí àǹfààní tí wọ́n máa rí ni ọ̀pọ̀ fi ń ṣe é.” Irú ìwà bẹ́ẹ̀ ni Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra fún.

Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ kókó yìí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà ọ̀làwọ́. Ó kọ̀wé sáwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”​—2 Kọ́r. 9:7..

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́