Àtẹ Àwọn Ọjọ́ Ìṣẹ̀lẹ̀
‘Ní àtètèkọ́ṣe . . .’
4026 Ṣ.S.K. Ìṣẹ̀dá Ádámù
3096 Ṣ.S.K. Ádámù Ikú
2370 Ṣ.S.K. Omi bẹ̀rẹ̀ sí í ya lulẹ̀
2018 Ṣ.S.K. A bí Ábúráhámù
1943 Ṣ.S.K. Májẹ̀mú Ábúráhámù
1750 Ṣ.S.K. Wọ́n ta Jósẹ́fù lẹ́rú
ṣáájú 1613 Ṣ.S.K. Àdánwò Jóòbù
1513 Ṣ.S.K. Ìjáde kúrò ní Íjíbítì
1473 Ṣ.S.K. Jóṣúà kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì
1467 Ṣ.S.K. Wọ́n parí ṣíṣẹ́gun àwọn ibi pàtàkì-pàtàkì nílẹ̀ Kénáánì
1117 Ṣ.S.K. A fòróró yan Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọba
1070 Ṣ.S.K. Ọlọ́run bá Dáfídì dá májẹ̀mú Ìjọba
1037 Ṣ.S.K. Sólómọ́nì di ọba
1027 Ṣ.S.K. Wọ́n parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù
nǹkan bí 1020 Ṣ.S.K. Wọ́n parí kíkọ ìwé Orin Sólómọ́nì
997 Ṣ.S.K. A pín ìjọba Ísírẹ́lì sí méjì
nǹkan bí 717 Ṣ.S.K. Àkójọ àwọn Òwe parí
607 Ṣ.S.K. Àwọn ọmọ ogun pa Jerúsálẹ́mù run; ìkónígbèkùn lọ sí Bábílónì bẹ̀rẹ̀
539 Ṣ.S.K. Kírúsì ṣẹ́gun ìlú Bábílónì
537 Ṣ.S.K. Àwọn Júù tó wà nígbèkùn padà sí Jerúsálẹ́mù
455 Ṣ.S.K. A tún odi Jerúsálẹ́mù kọ́; ọ̀sẹ̀ 69 ti ọdún bẹ̀rẹ̀
Lẹ́yìn 443 Ṣ.S.K. Málákì parí ìwé àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀
nǹkan bí 2 Ṣ.S.K. Ìbí Jésù
29 S.K. A batisí Jésù àti Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run
31 S.K. Jésù yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá; ó ṣe Ìwàásù Lórí Òkè
32 S.K. Jésù jí Lásárù dìde
Nísàn 14, 33 S.K. Wọ́n kan Jésù mọ́gi (Oṣù Nísàn bọ́ sí apá kan oṣù March àti apá kan oṣù April)
Nísàn 16 33 S.K. Ọlọ́run jí Jésù dìde
Sífánì 6, 33 S.K. Pẹ́ńtíkọ́sì; ìtújáde ẹ̀mí mímọ́ (Oṣù Sífánì bọ́ sí apá kan oṣù May àti apá kan oṣù June)
36 S.K. Kọ̀nílíù di Kristẹni
nǹkan bí 47 sí 48 S.K. Ìrìn àjò àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù rìn láti lọ wàásù
nǹkan bí 49 sí 52 S.K. Ìrìn àjò ẹlẹ́ẹ̀kejì tí Pọ́ọ̀lù rìn láti lọ wàásù
nǹkan bí 52 sí 56 S.K. Ìrìn àjò ẹlẹ́ẹ̀kẹta tí Pọ́ọ̀lù rìn láti lọ wàásù
60 sí 61 S.K. Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà nígbà tó ń ṣẹ̀wọ̀n ní Róòmù
ṣáájú 62 S.K. Jákọ́bù, iyèkan Jésù kọ lẹ́tà rẹ̀
66 S.K. Àwọn Júù ṣọ̀tẹ̀ sí ìlú Róòmù
70 S.K. Àwọn ará Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run
nǹkan bí 96 S.K. Jòhánù kọ ìwé Ìṣípayá
nǹkan bí 100 S.K. Ikú Jòhánù, ẹni tó gbẹ̀yìn lára àwọn àpọ́sítélì