Ṣiṣayẹwo Awọn Apa-iha Ohun Alaiṣeediyele Ti Ọlọrun—Bibeli!
NI 1867 àgbẹ̀ kan ara South Africa ti njẹ Schalk van Niekerk nwo awọn ọmọ ti wọn nfi awọn okuta ṣere. Okuta didara ti o si ndan yanranyanran kan wọ̀ ọ́ loju. Iya awọn ọmọ naa wi pe, “Iwọ le mú un bi o ba fẹ.” Bi o ti wu ki o ri, van Niekerk fi okuta naa ranṣẹ si ọmọran nipa ohun alumọni ilẹ kan fun ayẹwo. Boya ni awọn ọmọ naa fi mọ pe awọn nfi dayamọndi nla ti iye rẹ tó £500 ṣere!
O ha ṣeeṣe pe ki iwọ pẹlu ni ohun ọṣọ alaiṣeediyele laimọ? Fun apẹẹrẹ, ọpọlọpọ ní Bibeli, gẹgẹ bi o ti jẹ iwe ti o tà julọ ti a tii mọ, ti o wà larọwọọto lodidi tabi lapakan ni iye ede ti o ju 1,900 lọ. Sibẹ, ọpọlọpọ awọn eniyan ni ko tii ka Bibeli ati fun idi yii wọn ko mọ ohunkohun nipa awọn ohun ti ó wà ninu rẹ.
Bibeli sọ pe oun ní “imisi Ọlọrun” ati nitori naa oun jẹ Ọrọ Ọlọrun. (2 Timoti 3:16; fiwe 1 Tẹsalonika 2:13.) O jẹ ohun ìní ti o ṣọwọn julọ ti araye. Nipasẹ rẹ, a kẹkọọ bi a ṣe le gbadun igbesi-aye nisinsinyi ati, ni pataki ju, bi a ṣe le jere iye ainipẹkun! (Johanu 17:3, 17) Ohun kan ha wa ti o le ṣọwọn ju iyẹn lọ bi?
Bi o ti wu ki o ri, lati mọriri ohun iyebiye yii ati gbogbo awọn apa-iha rẹ, ẹnikan gbọdọ dojulumọ pẹlu rẹ. Ni yíyẹ̀ ẹ́ wò fun igba akọkọ, eyi le dabi ohun ti o ṣoro gidigidi. O ṣetan, Bibeli jẹ akojọpọ awọn iwe 66 ọtọọtọ. Ki ni awọn iwe wọnyi ni ninu? Awọn idi kan ha wa fun bi wọn ti farahan ni itotẹlera? Bi o ba ri bẹẹ, bawo ni ẹnikan ṣe le wa awọn ayọka akanṣe rí ninu Bibeli?
Didi ojulumọ pẹlu Bibeli jẹ ipenija kan. Ṣugbọn gẹgẹ bi ohun ọṣọ gidi kan, Bibeli ni idọgba ati eto. Awa le ri iyẹn bi a ba gbe awọn ohun ti o ni ninu yẹwo ni ṣoki.
Iwe Mimọ Lede Heberu —Ntọka si Kristi
Bibeli ni gbogbogboo pin si “Majẹmu Laelae” ati “Majẹmu Titun.” Bi o ti wu ki o ri, iwọnyi jẹ aṣipe orukọ ti nfunni ni ero pe “Majẹmu Laelae” ni ko ba igba mu mọ ti pe iniyelori rẹ ko si tó nǹkan. Orukọ kan ti o ba a mu ju fun apa Iwe mimọ yẹn yoo jẹ Iwe mimọ lede Heberu, niwọn bi o ti jẹ pe ede Heberu ni a ti kọ eyi fi o eyi ti o pọ julọ ninu apa Bibeli yii ni ipilẹṣẹ. “Majẹmu Titun” ni a kọ ni ede Giriiki ni ọrundun kìn-ínní ti Sanmani Tiwa; fun idi yii, a pe é ni Iwe mimọ Kristian lede Giriiki lọna ti o tubọ bojumu.
Iwe akọkọ Bibeli, Jẹnẹsisi, bẹrẹ ni àtọdúnmọ́dún sẹhin nigba ti Ọlọrun dá ọrun ati ilẹ-aye ti o si bẹrẹ si mura ilẹ-aye silẹ fun gbigbe eniyan. Tọkọtaya eniyan akọkọ ni a dá ni pipe; bi o ti wu ki o ri, wọn yan ipa ọna ẹṣẹ, pẹlu awọn abajade ti o bani ninu jẹ fun iru ọmọ wọn. Sibẹ, bii ohun iyebiye ti a ri ninu imọlẹ bàìbàì, Bibeli pese ìtànná ireti fun araye ẹlẹṣẹ: “iru-ọmọ” kan ti yoo mu awọn iyọrisi ẹṣẹ ati iku kuro lẹhin-ọ-rẹhin. (Jẹnẹsisi 3:15) Ta ni iru-ọmọ yii yoo jẹ? Jẹnẹsisi bẹrẹ sii tọpasẹ ila iran Iru-ọmọ ti nbọ yii, ni kiko afiyesi jọ sori igbesi-aye diẹ lara awọn baba nla oluṣotitọ ti Iru-ọmọ naa, awọn bii Aburahamu, Isaaki, ati Jakọbu.
Ẹkisodu ṣapejuwe ìbí Mose tẹle e. Ni ọpọlọpọ awọn ọna ni igbesi-aye Mose fi jẹ ojiji iṣaaju fun ti Iru-ọmọ ti nbọ yẹn. Lẹhin iyọnu mẹwaa, Isirẹli jadelọ lọpọ jaburata kuro ni Ijibiti a si fidi rẹ mulẹ gẹgẹ bi orilẹ-ede ti Ọlọrun yan ni Oke Sinai. Lefitiku, gẹgẹ bi orukọ naa ti fihan, gbé awọn ilana Ọlọrun fun ipo alufaa ti awọn ọmọ Lefi kalẹ ni Isirẹli. Numeri sọ nipa awọn akoko ti a ka awọn ọmọ Isirẹli (nipasẹ eto ikaniyan) ati nipa awọn iṣẹlẹ laaarin akoko atipo Isirẹli ninu aginju. Ati nisinsinyi, ni wiwa ni imurasilẹ lati wọ Ilẹ Ileri naa, Isirẹli gba awọn igbaniniyanju ikẹhin lọdọ Mose. Eyi ni koko ẹkọ Deutaronomi. Ni titọka si Iru-ọmọ ti nbọ, Mose rọ orile-ede naa lati feti silẹ si ‘wolii kan ti Ọlọrun yoo gbé dide.’—Deutaronomi 18:15.
Awọn iwe itan ni o tẹle e. Apa ti o pọ julọ ninu iwọnyi tò tẹlera ni ọna kika akoko. Joṣua ṣapejuwe iṣẹgun ati ipin funni Ilẹ Ileri. Awọn Onidaajọ pitan awọn iṣẹlẹ amunijigiri ti awọn ọdun ti o tẹle nigba ti a jọba lé Isirẹli lori nipasẹ ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ awọn onidaajọ. Ruutu sọ nipa obinrin olubẹru Ọlọrun kan ti o gbé laaarin saa akoko awọn Onidaajọ ti o si ni anfaani didi iya-nla Jesu Kristi.
Bi o ti wu ki o ri, saa iṣakoso nipasẹ awọn onidaajọ wa si opin. Samuẹli Kin-inni sọ nipa iṣakoso onibanujẹ ti ọba Isirẹli akọkọ, Sọọlu, gẹgẹ bi a ti ri nipasẹ oju wolii Samuẹli. Samuẹli Keji ṣapejuwe aṣeyọri si rere ijọba Dafidi, agbapò Sọọlu. Awọn Ọba Kin-inni ati Ekeji lẹhin naa mu wa lọ lati igba ijọba ologo ti Solomọni si igbekun ti o banininujẹ ti orilẹ-ede Isirẹli ni Babiloni ni 607 B.C.E. Kironika Kin-inni ati Ekeji tun itan yii sọ lẹẹkan sii gẹgẹ bi a ti fi oju iwoye orilẹ-ede kan ti o pada lati igbekun yii wò ó. Nikẹhin, Ẹsira, Nehemaya, ati Ẹsiteri ṣapejuwe bi a ṣe mu awọn ọmọ Isirẹli ti padabọ si ilẹ ibilẹ wọn ati itan wọn ti o tẹle e.
Awọn iwe elewi ni wọn tẹle e, ti wọn ni diẹ lara awọn ewi didara julọ ti a tii kọ ri ninu. Joobu pese aworan aruni soke ti iwatitọ labẹ ijiya ati ere rẹ. Iwe Awọn Saamu ni awọn orin iyin si Jehofa ati adura fun aanu ati iranlọwọ ninu. Iwọnyi ti tu ẹgbẹẹgbẹrun awọn iranṣẹ Ọlọrun ninu. Ni afikun, Saamu ni ọgọọrọ awọn asọtẹlẹ ti o tubọ la wa loye nipa dide Mesaya naa. Owe ati Awọn Oniwaasu ṣipaya awọn apa-iha ọgbọn atọrunwa nipasẹ awọn ọrọ ṣiṣe ṣoki, nigba ti Orin Solomọni jẹ ewi didara julọ nipa ifẹ pẹlu itumọ alasọtẹlẹ jijinlẹ.
Awọn iwe 17 ti wọn tẹle e—lati Aisaya si Malaki—jẹ alasọtẹlẹ ni pataki julọ. Gbogbo wọn, yatọ si Awọn Ìdárò, jẹ orukọ onkọwe rẹ. Ọpọlọpọ awọn asọtẹlẹ wọnyi ti ni imuṣẹ yiyanilẹnu. Wọn tun tọka si awọn iṣẹlẹ ogogoro opin ni ọjọ wa ati ni ẹhin ọla ti o sunmọle.
Iwe Mimọ lede Heberu tipa bayii gbe oniruuru yiyanilẹnu ninu iru ati ọna ikọwe kalẹ. Sibẹ, gbogbo rẹ ni ẹṣin-ọrọ kan naa. Awọn asọtẹlẹ, itan iran, ati awọn iṣẹlẹ apafiyesi rẹ tàn yanranyanran pẹlu ọgbọn ti o ṣee fi silo ati itumọ alasọtẹlẹ.
Iwe Mimọ Kristian Lede Giriiki —Iru-ọmọ Naa Farahan
Ẹgbẹẹrun mẹrin ọdun ti kọja lọ lati igba ti eniyan ti ṣubu sinu ẹṣẹ. Lojiji Iru-ọmọ ti a ti nduro de tipẹtipẹ naa, Mesaya, Jesu, farahan lori ilẹ-aye! Iwe mimọ Kristian lede Giriiki ṣakọsilẹ iṣẹ-ojiṣẹ ẹni pataki ninu itan eniyan yii ninu awọn iwe mẹrin ọtọọtọ ṣugbọn ti wọn ṣàlékún araawọn, ti a npe ni awọn Ihinrere. Awọn wọnyi ni Matiu, Maaku, Luuku, ati Johanu.
Ẹ wo bi awọn akọsilẹ Ihinrere mẹrin wọnyi ti ṣọwọn to fun awa Kristian! Wọn sọ nipa awọn iṣẹ iyanu yiyanilẹnu ti Jesu, awọn owe-akawe rẹ onitumọ, Iwaasu rẹ lori Oke, apẹẹrẹ ẹmi irẹlẹ rẹ, ìyọ́nú rẹ ati iṣegbọran timọtimọ si Baba rẹ, ifẹ rẹ fun “awọn agutan” rẹ, ati nikẹhin iku irubọ ati ajinde ologo rẹ. Ikẹkọọ awọn Ihinrere gbe ifẹ jijinlẹ fun Ọmọkunrin Ọlọrun ró ninu wa. Ju gbogbo rẹ lọ, a fà wa sunmọra pẹkipẹki si ẹni naa ti o ran Kristi—Jehofa Ọlọrun. Awọn akọsilẹ wọnyi yẹ ni kika leralera sii.
Iṣe Awọn Apọsteli bẹrẹ nibi ti awọn Ihinrere pari si. O funni ni akọsilẹ awọn ọdun ijimiji ti ijọ Kristian lati awọn ọjọ Pẹntikọsi si ifisẹwọn Pọọlu ni Roomu ni 61 C.E. Ninu iwe yii, a kà nipa Stefanu, ajẹriiku Kristian akọkọ, iyilọkan pada Sọọlu, ẹni ti o di Pọọlu apọsteli lẹhin naa, imuwọle awọn Keferi akọkọ ti a yí lọkan pada, ati awọn irin ajo iwaasu aruni soke ti Pọọlu. Awọn akọsilẹ iṣẹlẹ wọnyi ru ni soke o si gbé igbagbọ ró.
Lẹta mokanlelogun, tabi awọn lẹta awọn apọsteli ni o tẹle e nisinsinyi. Mẹrinla akọkọ, lati ọwọ Pọọlu, ni a pe lorukọ awọn Kristian tabi ijọ ti o gbà wọn; awọn yooku ni a pe lorukọ tẹle awọn onkọwe naa—Jakọbu, Peteru, Johanu, ati Juuda. Ẹ wo iru ọrọ̀ iṣileti ati iṣiiri ti awọn lẹta wọnyi ni ninu! Wọn kari ẹkọ-igbagbọ ati imuṣẹ awọn asọtẹlẹ. Wọn ran awọn Kristian lọwọ lati wà lọtọ gédégbé kuro ninu ayika buburu ninu eyi ti wọn gbọdọ gbe. Wọn tẹnumọ aini naa lati mu ifẹ ara dagba ati awọn animọ oniwa bi Ọlọrun miiran. Wọn gbe apẹẹrẹ kalẹ fun eto ijọ ti o bojumu, labẹ ipo aṣiwaju awọn agba ọkunrin tẹmi.
Gẹgẹ bi Iwe mimọ lede Heberu ti pari pẹlu gbolohun alasọtẹlẹ, bẹẹ naa ni Iwe Mimọ lede Giriiki ti ṣe. Iṣipaya, ti a kọ lati ọwọ apọsteli Johanu ni nǹkan bi 96 C.E, fa awọn asọtẹlẹ ati ẹṣin ọrọ pataki inu Bibeli papọ—idalare orukọ Jehofa nipasẹ Ijọba ti Mesaya rẹ. Ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ awọn iran fi iparun agbara isin, ologun ati oṣelu ti eto-igbekalẹ bibajẹ ti Satani han lọna aworan. Iwọnyi ni a fi ilu nla ijọba ti Kristi rọpo, eyi ti o dari afiyesi rẹ si bibojuto awọn àlàámọ̀rí ilẹ-aye. Labẹ iṣakoso Ijọba yii, Ọlọrun ṣeleri lati “nu omije gbogbo nù kuro . . . Ki yoo sì sí iku mọ.”—Iṣipaya 21:4.
Iye meji kankan ha wà, nigba naa, pe Bibeli jẹ ohun iyebiye pipe, ti ntan imọlẹ atọrunwa? Bi iwọ ko ba tii kà á jalẹ, eeṣe ti iwọ ko fi bẹrẹ nsinsinyi? Iwọ ni a o famọra nipasẹ idọgba rẹ, mu ọ loye nipasẹ ìdán yanranyanran rẹ, wú ọ lori nipasẹ ẹwa rẹ, dun ọ ninu nipasẹ ihin-iṣẹ rẹ. Nitootọ o jẹ “ẹbun pipe . . . lati ọdọ Baba imọlẹ wa.”—Jakọbu 1:17.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 28, 29]
AKOJỌ AWỌN IWE BIBELI
Ti ntọka onkọwe, ibi ikọwe, akoko ipari ikọwe, ati akoko ti awọn iṣẹlẹ iwe naa kárí.
Orukọ onkọwe awọn iwe kan ati ibi ti a ti a kọ wọn kò daju. Ọpọlọpọ ninu awọn deeti wulẹ jẹ ifojúbù ni, ami naa a. tumọsi “lẹhin,” b. tumọsi “ṣaaju,” ati c. tumọsi “sunmọ,” tabi “nǹkan bii.”
Awọn Iwe Mimọ Bibeli Lede Heberu (B.C.E.)
Iwe (Awọn) Onkọwe Ibi Ti a Ikọwe Akoko Ti
ti Kọ ọ́ Pari O Kárí
Jẹnẹsisi Mose Aginju 1513 “Ni ibẹrẹ”
si 1657
Ẹkisodu Mose Aginju 1512 1657-1512
Lefitiku Mose Aginju 1512 1 oṣu (1512)
Numeri Mose Aginju/Awọn/ 1473 1512-1473
Pẹtẹlẹ Moabu
Deutaronomi Mose Awọn Pẹtẹlẹ 1473 2 oṣu (1473)
Moabu
Joṣua Joṣua Kenani c. 1450 1473-c.
1450
Awọn Onidaajọ Samuẹli Isirẹli c. 1100 c. 1450-
c. 1120
Ruutu Samuẹli Isirẹli c. 1090 Ọdun 11 ti
iṣakoso
awọn onidaajọ
1 Samuẹli Samuẹli; Gadi; c. 1078 c. 1180-
Natani Isirẹli 1078
2 Samuẹli Gadi; Natani Isirẹli c. 1040 1077-c.
1040
1 Awọn Ọba Jeremaya Jerusalẹmu 580 c. 1040-911
/Juda
2 Awọn Ọba Jeremaya Jerusalẹmu 580 c. 920-580
/Ijibiti
1 Kironika Ẹsira Jerusalẹmu (?) c. 460 Lẹhin
1 Kironika
9:44, 1077-1037
2 Kironika Ẹsira Jerusalẹmu (?) c. 460 1037-537
Ẹsira Ẹsira Jerusalẹmu c. 460 537-c. 467
Nehemaya Nehemaya Jerusalẹmu a. 443 456-a. 443
Ẹsiteri Mọdekai Ṣuṣani, Elamu c. 475 493-c. 475
Joobu Mose Aginju c. 1473 Ju 140 ọdun
laaarin 1657
ati 1473
Awọn Saamu Dafidi ati c. 460
awọn miiran
Awọn Owe Solomọni; Jerusalẹmu c. 717
Aguri; Lemuẹli
Oniwaasu Solomọni Jerusalẹmu b. 1000
Orin Solomọni Solomọni Jerusalẹmu c. 1020
Aisaya Aisaya Jerusalẹmu a. 732 c. 778-a.
732
Jeremaya Jeremaya Juda/Ijibiti 580 647-580
Awọn Ìdárò Jeremaya Lẹbaa 607
Jerusalẹmu
Esikiẹli Esikiẹli Babiloni c. 591 613-c. 591
Daniẹil Daniẹli Babiloni c. 536 618-c. 536
Hosea Hosea Samaria a. 745 b. 804-a.
745
(Agbegbe)
Joẹli Joẹli Juda c. 820 (?)
Amosi Amosi Juda c. 804
Obadaya Obadaya c. 607
Jona Jona c. 844
Mika Mika Juda b. 717 c. 777-717
Nahumu Nahumu Juda b. 632
Habakuku Habakuku Juda c. 628 (?)
Sefanaya Sefanaya Juda b. 648
Hagai Hagai Jerusalẹmu 520 112 ọjọ
(520)
Sekaraya Sekaraya Jerusalẹmu 518 520-518
Malaki Malaki Jerusalẹmu a. 443
Awọn Iwe Mimọ Kristian Lede Giriiki (C.E.)
Iwe (Awọn) Onkọwe Ibi Ti a Ikọwe Akoko Ti
ti Kọ ọ́ Pari O Kárí
Matiu Matiu Palẹstini c. 41 2 B.C.E.
–33 C.E.
Maaku Maaku Roomu c. 60-65 29-33 C.E.
Luuku Luuku Kesaria c. 56-58 3 B.C.E.
–33 C.E.
Johanu Apọsteli Efesu, tabi c. 98 Lẹhin ọrọ-
Johanu nitosi rẹ iṣaaju, 29-
33 C.E.
Iṣe Luuku Roomu c. 61 33-c. 61 C.E.
Awọn Pọọlu Kọrinti c. 56
Ara Roomu
1 Awọn Pọọlu Efesu c. 55
Ara Kọrinti
2 Awọn Pọọlu Makedonia c. 55
Ara Kọrinti
Awọn Pọọlu Kọrinti tabi c. 50-52
Ara Galatia Siria Antioku
Awọn Pọọlu Roomu c. 60-61
Ara Efesu
Awọn Pọọlu Roomu c. 60-61
Ara Filipi
Awọn Pọọlu Roomu c. 60-61
AraKolose
1 Awọn Ara Pọọlu Kọrinti c. 50
Tẹsalonika
2 Awọn Ara Pọọlu Kọrinti c. 51
Tẹsalonika
1 Timoti Pọọlu Makedonia c. 61-64
2 Timoti Pọọlu Roomu c. 65
Titu Pọọlu Makedonia (?) c. 61-64
Filemoni Pọọlu Roomu c. 60-61
Heberu Pọọlu Roomu c. 61
Jakọbu Jakọbu Jerusalẹmu b. 62
(Arakunrin Jesu)
1 Peteru Peteru Babiloni c. 62-64
2 Peteru Peteru Babiloni (?) c. 64
1 Johanu Apọsteli Efesu, tabi c. 98
Johanu nitosi rẹ
2 Johanu Apọsteli Efesu, tabi c. 98
Johanu nitosi rẹ
3 Johanu Apọsteli Efesu, tabi c. 98
Johanu nitosi rẹ
Juuda Juudu Palẹstini (?) c. 65
(Arakunrin Jesu)
Iṣipaya Apọsteli Patimosi c. 96
Johanu