Bí Àwọn kan Ṣe Ń Ṣe Ìtọrẹ Fún Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Náà
◻ ÀWỌN ỌRẸ FÚN IṢẸ́ YÍKÁ-AYÉ: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ya iye kan sọ́tọ̀ tàbí ṣètò iye owó kan tí wọ́n ń fi sínú àwọn àpótí ọrẹ tí a lẹ ìsọfúnni náà: “Àwọn Ọrẹ fún Iṣẹ́ Society Yíká-Ayé—Matteu 24:14” mọ́ lára. Lóṣooṣù ni àwọn ìjọ ń fi àwọn owó wọ̀nyí ránṣẹ́ yálà sí orílé-iṣẹ́ àgbáyé ní Brooklyn, New York, tàbí sí ọ́fíìsì ẹ̀ka tí ó súnmọ́ wọn jùlọ.
◻ ÀWỌN Ẹ̀BÙN: Àwọn ìtọrẹ owó tí a fínnúfíndọ̀ ṣe ni a lè fi ránṣẹ́ ní tààràtà sí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, 25 Columbia Heights, Brooklyn, New York 11201-2483, tàbí sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Society tí ń bójútó orílẹ̀-èdè rẹ̀. Àwọn ohun iyebíye tàbí ohun àlùmọ́ọ́nì mìíràn ni a tún lè fi tọrẹ. Lẹ́tà ṣókí kan tí ń fihàn pé irú ohun bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn pátápátá níláti bá àwọn ọrẹ wọ̀nyí rìn.
◻ ÌṢÈTÒ ÌTỌRẸ ONÍPÒ ÀFILÉLẸ̀: Owó ni a lè fifún Watch Tower Society láti máa lò bí ohun àfúnniṣọ́ títí fi di ìgbà ikú olùtọrẹ náà, pẹ̀lú ìṣètò pé tí àìní fún lílo owó náà bá dìde, a óò dá a padà fún ẹni tí ó fi tọrẹ.
◻ OWÓ ÌBÁNIGBÓFÒ: A lè lo orúkọ Watch Tower Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní nínú ìlànà ètò ìbánigbófò ìwàláàyè tàbí nínú ìwéwèé owó àsanfúnni fún ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́. A níláti fi irú ìṣètò èyíkéyìí bẹ́ẹ̀ tó Society létí.
◻ ÀWỌN ÀKÁǸTÌ OWÓ NÍ BÁǸKÌ: Àwọn àkáǹtì owó ní báǹkì, àwọn ìwé ẹ̀rí owó ìdókòwò, tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ẹnì kan ni a lè fi sí ìkáwọ́ tàbí mú kí ó ṣeé san nígbà ikú fún Watch Tower Society, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí báǹkì àdúgbò bá béèrè fún. A níláti fi irú àwọn ìṣètò èyíkéyìí bẹ́ẹ̀ tó Society létí.
◻ ÀWỌN ÌWÉ Ẹ̀TỌ́ LÓRÍ OWÓ ÌDÓKÒWÒ ÀTI LÓRÍ OWÓ TÍ A FI YÁNI: Àwọn ìwé ẹ̀tọ́ lórí owó ìdókòwò àti lórí owó tí a fi yáni ni a lè fi tọrẹ fún Watch Tower Society yálà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pátápátá tàbí lábẹ́ ìṣètò kan níbi tí a óò ti máa bá a nìṣó láti san owó tí ń wọlé wá lórí èyí fún olùtọrẹ náà.
◻ DÚKÌÁ ILÉ TÀBÍ ILẸ̀: Àwọn dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ tí ó ṣe é tà ni a lè fi tọrẹ fún Watch Tower Society yálà nípa ṣíṣe é ní ẹ̀bùn pátápátá tàbí nípa pípa á mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun-ìní olùtọrẹ náà nígbà tí ó bá ṣì wàláàyè, ẹni tí ó ṣì lè máa gbé inú rẹ̀ nìṣó nígbà ayé rẹ̀. Ẹnì kan níláti kàn sí Society ṣáájú fífi ìwé àṣẹ sọ dúkìá ilé-tàbí-ilẹ̀ èyíkéyìí di ti Society.
◻ ÀWỌN ÌWÉ-ÌHÁGÚN ÀTI OHUN-ÌNÍ ÌFISÍKÀÁWỌ́: Dúkìá tàbí owó ni a lè fi sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania nípasẹ̀ ìwé ìhágún tí a múṣẹ lábẹ́ òfin, Society ni a sì lè dárúkọ gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní irú ìwé àdéhùn fífi ohun sí ìkáwọ́ ẹni bẹ́ẹ̀. Àwọn ohun-ìní ìfisíkàáwọ́ tí ètò-àjọ ìsìn kan ń jàǹfààní nínú rẹ̀ lè pèsè àwọn àǹfààní mélòókan nínú ọ̀ràn owó-orí. Ẹ̀dà kan nínú ìwé ìhágún tàbí ìwé àdéhùn ohun-ìní ìfisíkàáwọ́ ni a níláti fi ránṣẹ́ sí Society.
Fún ìsọfúnni síwájú síi nípa irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, kọ̀wé sí Treasurer’s Office, Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, 25 Colombia Heights, Brooklyn, New York 11201-2483, tàbí sí ọ́fíìsì Society tí ń bójútó orílẹ̀-èdè rẹ̀.