“Ibo Ni Owó Náà Ti Ń Wá?”
ORÍ àwọn tí wọ́n wo fídíò Watch Tower Society náà, “Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name” wú. Wọ́n rí àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ó dùn-ún wò, tí wọ́n wá láti onírúurú ẹ̀yà ìran àti ipò àtilẹ̀wá, tí wọ́n ń rẹ́rìn-ín músẹ́, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pọ̀ níṣọ̀kan. Kì í ṣe kìkì àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún òṣìṣẹ́ aláyọ̀ ni ó pe àfiyèsí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ilé ńlá rẹpẹtẹ ti orílé iṣẹ́ Society ní Brooklyn àti oko wọn ní Wallkill, New York, pẹ̀lú. Fídíò náà fi hàn pé, a lè rí àwọn irin iṣẹ́ ẹ̀rọ tí ó bóde mu nínú àwọn ilé wọ̀nyí—àwọn ohun èlò ìtẹ̀wé àti ìdìwé ayára bí àṣá, tí ń pèsè ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ìtẹ̀jáde lóṣooṣù, oríṣiríṣi ohun èlò kọ̀m̀pútà, àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ẹ̀ka aṣètìlẹ́yìn.
Èyí ṣàgbéyọ ìnáwó gíga lọ́lá. Nítorí èyí, àwọn kan lè béèrè pé, “Níbo ni owó náà ti ń wá?”
Orí àwọn olùṣèbẹ̀wò sí orílé iṣẹ́ àgbáyé ti Society máa ń wú bákan náà. Wọ́n na ọrùn wọn láti wo ilé gbígbé tuntun tí ó ní 30 àjà, ọ̀kan lára àwọn ilé tí àwọn òjíṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni, tí ó lé ní 3,000, tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ń gbé. Ìbẹ̀wò sí Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Watchtower tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́, tí ó wà ní nǹkan bí 110 kìlómítà ní àríwá Brooklyn tún jẹ́ ohun àgbàyanu. Bí iṣẹ́ ìkọ́lé tilẹ̀ ṣì ń lọ lọ́wọ́, àwọn òṣìṣẹ́ bí 1,200 ń gbé níbẹ̀. A óò máa dá kíláàsì méjì ti àwọn míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ lọ́dọọdún, tí a óò sì máa rán wọn lọ sí ibi iṣẹ́ àyànfúnni wọn nílẹ̀ òkèèrè. Láti ọ̀gangan yìí kan náà ni a ti ń fún àwọn ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó lé ní 10,000 ní United States ní ìtọ́sọ́nà. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀ka lágbàáyé pẹ̀lú ṣẹ̀ṣẹ̀ mú àwọn ilé lílo wọn gbòòrò sí i, tàbí kí wọ́n wà lẹ́nu ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Láti lè ṣe gbogbo àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí ń béèrè owó ńláǹlà. Àwọn ènìyàn ń béèrè pé, “Níbo ni owó náà ti ń wá?”
Ìdáhùn náà ni pé ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan bíi ẹnikẹ́ni nínú wa. Wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn, kárí ayé, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọkàn láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú olórí iṣẹ́ Kristian ti wíwàásù àti kíkọ́ni tẹ̀ síwájú. Irú ẹ̀mí ìfínnúfíndọ̀ bẹ́ẹ̀ kò ṣàìní àpẹẹrẹ ìṣáájú.
Àpẹẹrẹ Tí Israeli Ìgbàanì Fi Lélẹ̀
Àìní fún ìtọrẹ ọlọ́làwọ́ dìde ní ohun tí ó lé ní 3,500 ọdún sẹ́yìn. Jehofa fún Mose ní ìtọ́ni láti kọ́ àgọ́ ìsìn, tàbí “àgọ́ àjọ,” tí a óò máa lò fún ìjọsìn Rẹ̀. Iṣẹ́ ọnà tí a pète látọ̀runwá béèrè fún onírúurú ohun èlò ṣíṣeyebíye. Jehofa pàsẹ pé: “Ẹ̀yin mú ọrẹ wá láti inú ara yín fún OLUWA: ẹnikẹ́ni tí ọkàn rẹ̀ bá fẹ́, kí ó mú un wá, ní ọrẹ fún OLUWA.” (Eksodu 35:4-9) Báwo ni àwọn ènìyàn náà ṣe hùwà padà? Àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé “wọ́n . . . wá, olúkúlùkù ẹni tí ọkàn rẹ̀ ru nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù ẹni tí ọkàn rẹ̀ mú un fẹ́, wọ́n sì mú ọrẹ OLUWA wá fún iṣẹ́ àgọ́ àjọ náà, àti fún ìsìn rẹ̀ gbogbo, àti fún aṣọ mímọ́ wọnnì.” Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, “ọrẹ àtinúwá” yìí di ńlá tó bẹ́ẹ̀ tí ‘ó fi pọ̀ jù fún iṣẹ́ ìsìn náà, tí Jehofa ti pa láṣẹ ní ṣíṣe.’ (Eksodu 35:21-29; 36:3-5, NW) Ẹ wo irú ẹ̀mí àìmọtara ẹni nìkan àti ọlọ́làwọ́ tí àwọn ènìyàn náà fi hàn!
Ní ohun tí ó dín ní 500 ọdún lẹ́yìn náà, ìpè kan tún dún fún àwọn ọmọ Israeli láti ṣètọrẹ ọlọ́làwọ́. Solomoni, ọmọkùnrin Ọba Dafidi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mú ìfẹ́ ọkàn bàbá rẹ̀ láti kọ́ ilé wíwà pẹ́ títí kan fún Jehofa ní Jerusalemu ṣẹ. Dafidi fúnra rẹ̀ ti kó apá púpọ̀ jù lọ nínú ohun tí a óò nílò jọ, ó sì ti fi wọ́n ṣètọrẹ. Àwọn mìíràn dara pọ̀ nígbà tí Dafidi pe ìpè náà láti mú [“ẹ̀bùn wá fún Jehofa,” NW]. Kí ni àbáyọrí rẹ̀? “Àwọn ènìyàn sì yọ̀, nítorí wọ́n fi tinútinú ṣe ìrànlọ́wọ́ fún Oluwa: pẹ̀lúpẹ̀lú Dafidi ọba sì yọ̀ gidigidi.” (1 Kronika 22:14; 29:3-9) Fàdákà àti wúrà nìkan yóò tó nǹkan bíi 50 bílíọ̀nù dọ́là ní iye owó lọ́ọ́lọ́ọ́!—2 Kronika 5:1.
A ṣàkíyèsí láti inú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí pé, a kò fipá mu ẹnikẹ́ni láti ṣètọrẹ. Ó jẹ́ “àtọkànwá” pátápátá, wọ́n sì ṣe é “tinútinú.” Ìtọrẹ àtọkànwá nìkan ni inú Jehofa lè dùn sí. Bákan náà, nígbà tí àǹfààní dìde láti fi owó ṣètọrẹ fún ìrànlọ́wọ́ àwọn Kristian tí wọ́n ṣaláìní, aposteli Paulu kọ̀wé pé kò ní láti jẹ́ “ohun tí a fi agbára gbà.” Ó fi kún un pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí oun ti gbèrò pinnu ninu ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹlu ìlọ́tìkọ̀ tabi lábẹ́ àfipáṣe, nitori Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”—2 Korinti 9:5, 7.
Àìní Náà Lónìí
Àìní kankan ha wà fún ṣíṣètọrẹ lónìí bí? Ní tòótọ́, ó wà, púpọ̀ sí i yóò sì máa wà bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́. Èé ṣe?
A ti fún àwọn Kristian ní ìtọ́ni pàtó fún àkókò òpin yìí. Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nitori naa ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba ati ti Ọmọkùnrin ati ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn lati máa pa gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún yín mọ́.”—Matteu 28:19, 20.
Láti ṣàṣeparí iṣẹ́ kíkọ́ni àti wíwàásù pípabambarì yìí bí a ti ń túbọ̀ sún mọ́ ògógóró “ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan,” ń béèrè àkókò àti ìnáwó púpọ̀. Èé ṣe? Nítorí gbogbo ohun tí ó wé mọ́ mímú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba Ọlọrun lọ “[sí] apá ibi jíjìnnà jùlọ ní ilẹ̀-ayé.” (Ìṣe 1:8) Bíi ti àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní, àwọn ènìyàn púpọ̀ jù lọ kò lóye Ìwé Mímọ́ dáradára. Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé ni kò lóye Bibeli rárá, tí wọn kò sì kà á sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. A gbọ́dọ̀ dá àwọn oníwàásù lẹ́kọ̀ọ́, kí a sì rán wọn lọ sí ilẹ̀ òkèèrè. (Romu 10:13-15) Tilẹ̀ tún ronú nípa iye àwọn èdè tí ó ní nínú! Àwọn tí a wàásù fún ní láti ní Bibeli àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bibeli, láti kà, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní èdè tiwọn. Ó ń béèrè ìṣètò lọ́nà gbígbòòrò láti lè dé ọ̀dọ̀ gbogbogbòò ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, kí wọ́n sì mú wọn wá sí ìdàgbàdénú nípa tẹ̀mí ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, kí àwọn pẹ̀lú baà lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn.—2 Timoteu 2:2.
Jesu wí pé “a óò” kọ́kọ́ “wàásù ìhìnrere ìjọba” náà “ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé lati ṣe ẹ̀rí fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè; nígbà naa ni òpin yoo sì dé.” (Matteu 24:14) Nítorí náà, àkókò náà nìyí láti yọ̀ọ̀da gbogbo ohun tí a bá lè yọ̀ọ̀da láti rí i pé iṣẹ́ yìí di ṣíṣe. Kò sí ọ̀nà míràn tí ó sàn jù, tí a tún lè gba lo ohun ìní wa ju èyí lọ, ṣáájú kí ọrọ̀ àlùmọ́nì tó di aláìwúlò mọ́.—Esekieli 7:19; Luku 16:9.
Níbo Ni Owó Náà Ń Lọ?
Watch Tower Society ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli jáde ní èdè tí ó lé ní 230, bẹ́ẹ̀ sì ni ìwé Braille fún àwọn afọ́jú àti fídíò ní èdè àwọn adití. Èyí ń béèrè fún agbo òṣìṣẹ́ àwọn olùtúmọ̀ àti akàwéyẹ̀wò ní èdè kọ̀ọ̀kan. Wíwulẹ̀ ronú nípa ṣíṣe gbogbo iṣẹ́ yìí, ní pàtàkì fún ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà, tí a ń tẹ̀ jáde lóṣooṣù ní èdè 121, àti lẹ́ẹ̀mejì lóṣù ní èdè 101, yani lẹ́nu púpọ̀. Síbẹ̀, ó pọn dandan kí àwọn ènìyàn kárí ayé baà lè ní ìsọfúnni kan náà, kí wọ́n sì kà á. Lọ́dọọdún ni iye owó bébà àti àwọn ohun èlò míràn tí a ń lò ní mímú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà jáde lọ́nà ìwé títẹ̀ tàbí ìgbohùnsílẹ̀, tàbí ìmóhùnmáwòrán fídíò ń ga sí i. A ń san irú owó bẹ́ẹ̀ nípa ìtọrẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn ará.
Iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni náà ń bá a lọ ní àwọn agbègbè ìpínlẹ̀ tí àwọn ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí ó lé ní 75,000 kárí ayé, ti ń ṣiṣẹ́. Láti lè mú wọn wà níṣọ̀kan, kí a sì fún wọn níṣìírí, àwọn alábòójútó arìnrìn àjò tí a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ ń bẹ ìjọ kọ̀ọ̀kan wò ní bí ìgbà méjì lọ́dọọdún. Àwọn àpèjọ tún máa ń kó ipa pàtàkì nínú fífúnni ní ìtọ́ni. A gbọ́dọ̀ háyà àwọn ilé lílò ńláǹlà fún àwọn àpéjọpọ̀, tí ó jẹ́ afúngbàgbọ́lókun gan-an. A ń lo àwọn ìtọrẹ yín fún ète wọ̀nyí pẹ̀lú.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìgbà mẹ́ta ni a sábà máa ń ṣe àwọn àpéjọpọ̀ lọ́dùn, àwọn ìjọ àdúgbò ń pàdé pọ̀ fún ìpàdé márùn-ún lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. (Fi wé Eksodu 34:23, 24.) Bí àwọn ẹni tuntun tí ń dáhùn padà sí ìhìn rere náà ṣe ń rọ́ wọlé ti túmọ̀ sí àfikún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìjọ tuntun lọ́dọọdún. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù dọ́là tí Society ń yáni, a ń kọ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun lọ́dọọdún, a sì ń tún ọ̀pọ̀lọpọ̀ míràn kọ́, tí a sì ń mú wọn gbòòrò sí i. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, owó yìí ni a ń lò ní àlòtúnlò, àìní náà túbọ̀ ń pọ̀ sí i.
Àwọn orílẹ̀-èdè ní Ìlà Oòrùn Europe tí wọ́n wà lábẹ́ Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí jẹ́ agbègbè kan tí ìbísí tí a kò ní rí tí wáyé. Ẹ wo bí ìròyìn dídùn mọ́ni náà pé a ti fàyè gba iṣẹ́ náà ní àwọn ibi wọ̀nyí ti múni láyọ̀ tó! Nísinsìnyí, a ti ń rán àwọn míṣọ́nnárì lọ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè wọ̀nyí. A ti dá àwọn ẹ̀ka tuntun sílẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ kan, tí ó mú kí iye àwọn òjíṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ ìdílé Beteli kárí ayé lé ní 15,000. Dájúdájú, a ní láti ra àwọn ilé ẹ̀ka tí wọn óò gbé tàbí kí a kọ́ wọn. Ọrẹ yín ń ṣèrànwọ́ láti kúnjú àìní yìí.
Satani àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kò ṣàìfiyèsí gbogbo iṣẹ́ yìí. Wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti lè ké ìsapá àwọn ìránṣẹ́ Jehofa olùṣòtítọ́ nígbèrí tàbí dá ìṣòro sílẹ̀ fún wọn. (Ìṣípayá 12:17) Èyí túmọ̀ sí ìjà òfin púpọ̀ sí i ní ilé ẹjọ́ láti lè dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn Ọlọrun láti wàásù àti láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin òdodo rẹ̀. Ní àfikún sí i, ọṣẹ́ tí ogun ti ṣe nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti Satani, àti ti ìjábá ti ìṣẹ̀dá, túmọ̀ sí pé, a sábà máa ń nílò àwọn ìpèsè ìrànwọ́ fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ti jàm̀bá ṣẹlẹ̀ sí àti àwọn mìíràn tí wọ́n wà pẹ̀lú wọn. Ọrẹ yín tí ẹ fi ṣèrànwọ́ ń pèsè ìrànwọ́ pàtàkì yìí.
Jehofa Yóò San Yín Lẹ́san
Fífi ìwà ọ̀làwọ́ lo àkókò àti ohun ìní wa láti gbárùkù ti iṣẹ́ Oluwa ń mú àwọn ìbùkún gíga lọ́lá gidigidi wá. Lọ́nà wo? Nítorí pé, Ọlọrun tí ohun gbogbo jẹ́ tirẹ̀ lásẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, yóò san wá lẹ́san. Owe 11:25 sọ pé: “Ọkàn ìṣoore ni a óò mú sanra, ẹni tí ó ń bomi rin ni, òun tìkáraarẹ̀ ni a óò sì bomi rin pẹ̀lú.” Inú Jehofa máa ń dùn púpọ̀, nígbà tí a bá ń ṣe ipa tiwa, láti mú ìjọsìn rẹ̀ tẹ̀ síwájú. (Heberu 13:15, 16) Ó ṣe ìlérí fún àwọn ọmọ Israeli ìgbàanì, ti yóò bá mu ọrẹ tí a béèrè lábẹ́ májẹ̀mú Òfin wá pé: “Ẹ . . . fi èyí dán mi wò nísinsìnyí, bí èmi kì yóò bá ṣí àwọn fèrèsé ọ̀run fún-un yín, kí n sì tú ìbùkún jáde fún-un yín, tó bẹ́ẹ̀ tí kì yóò sì àyè tó láti gbà á.” (Malaki 3:10) Aásìkí nípa tẹ̀mí, tí àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ń gbádùn lónìí, jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọrun ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ.
Iṣẹ́ kíkọyọyọ ti pípolongo ọjọ́ ìgbàlà àti ríran àwọn aláìlábòsí-ọkàn lọ́wọ́ láti wá sí ọ̀nà ìyè kì yóò máa bá a nìṣó títí láé. (Matteu 7:14; 2 Korinti 6:2) Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ kó gbogbo àwọn “àgùtàn mìíràn” Oluwa jọ. (Johannu 10:16) Ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó lónìí láti kojú ìpèníjà yẹn! Ẹ sì wo bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa yóò ṣe láyọ̀ tó, ní bíbojú wẹ̀yìn láti inú ayé tuntun òdodo yẹn, láti sọ pé, ‘Mo ti nípìn-ín kíkún nínú iṣẹ́ ìkójọpọ̀ àṣekágbá yẹn’!—2 Peteru 3:13.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30, 31]
Bí Àwọn Kan Ṣe Ń Ṣe Ìtọrẹ Fún Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Náà
ỌRẸ FÚN IṢẸ́ YÍKÁ AYÉ: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ya iye kan sọ́tọ̀ tàbí ṣètò iye owó kan tí wọ́n ń fi sínú àwọn àpótí ọrẹ tí a lẹ ìsọfúnni náà: “Ọrẹ fún Iṣẹ́ Society Yíká Ayé—Matteu 24:14” mọ́ lára. Lóṣooṣù ni àwọn ìjọ ń fi àwọn owó wọ̀nyí ránṣẹ́ yálà sí orílé-iṣẹ́ àgbáyé ní Brooklyn, New York, tàbí sí ọ́fíìsì ẹ̀ka tí àdúgbò.
Ẹ̀BÙN: Ìtọrẹ owó tí a fínnúfíndọ̀ ṣe ni a lè fi ránṣẹ́ ní tààràtà sí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, 25 Columbia Heights, Brooklyn, New York 11201-2483, tàbí sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Society tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. Ohun ọ̀ṣọ́ ṣíṣeyebíye tàbí ohun àlùmọ́ọ́nì míràn ni a tún lè fi tọrẹ. Lẹ́tà ṣókí kan tí ń fi hàn pé irú ohun bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn pátápátá ní láti bá àwọn ọrẹ wọ̀nyí rìn.
ÌṢÈTÒ ÌTỌRẸ ONÍPÒ ÀFILÉLẸ̀: A lè fún Watch Tower Society ni owó láti máa lò ó bí ohun àfúnniṣọ́, títí di ìgbà ikú olùtọrẹ náà, pẹ̀lú ìṣètò pé tí àìní fún lílo owó náà bá dìde, a óò dá a padà fún ẹni tí ó fi tọrẹ.
OWÓ ÌBÁNIGBÓFÒ: A lè lo orúkọ Watch Tower Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní nínú ìlànà ètò ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí nínú ìwéwèé owó àsanfúnni fún ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́. A ní láti fi irú ìṣètò èyíkéyìí bẹ́ẹ̀ tó Society létí.
ÀKÁǸTÌ OWÓ NÍ BÁǸKÌ: Àkáǹtì owó ní báǹkì, ìwé ẹ̀rí owó ìdókòwò, tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ẹnì kan ni a lè fi sí ìkáwọ́ tàbí mú kí ó ṣeé san nígbà ikú, fún Watch Tower Society, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí báǹkì àdúgbò bá béèrè fún. A ní láti fi irú àwọn ìṣètò èyíkéyìí bẹ́ẹ̀ tó Society létí.
ÌWÉ Ẹ̀TỌ́ LÓRÍ OWÓ ÌDÓKÒWÒ ÀTI LÓRÍ OWÓ TÍ A YÁNI: Ìwé ẹ̀tọ́ lórí owó ìdókòwò àti lórí owó tí a yáni ni a lè fi ta Watch Tower Society lọ́rẹ, yálà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pátápátá, tàbí lábẹ́ ìṣètò kan, níbi tí a óò ti máa bá a nìṣó láti san owó tí ń wọlé wá lórí èyí fún olùtọrẹ náà.
DÚKÌÁ ILÉ TÀBÍ ILẸ̀: A lè fi dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ tí ó ṣeé tà, ta Watch Tower Society lọ́rẹ, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn pátápátá, tàbí nípa pípa á mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní olùtọrẹ náà, nígbà tí ó bá ṣì wà láàyè, ẹni tí ó ṣì lè máa gbé inú rẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Ẹnì kan ní láti kàn sí Society ṣáájú fífi ìwé àṣẹ sọ dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ èyíkéyìí di ti Society.
ÌWÉ ÌHÁGÚN ÀTI OHUN ÌNÍ ÌFISÍKÀÁWỌ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower Society nípasẹ̀ ìwé ìhágún tí a ṣe lábẹ́ òfin, a sì lè dárúkọ Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní irú ìwé àdéhùn fífi ohun sí ìkáwọ́ ẹni bẹ́ẹ̀. Àwọn ohun ìní ìfisíkàáwọ́ tí ètò àjọ ìsìn kan ń jàǹfààní nínú rẹ̀ lè pèsè àwọn àǹfààní mélòó kan nínú ọ̀ràn owó orí. A ní láti fi ẹ̀dà kan nínú ìwé ìhágún tàbí ìwé àdéhùn ohun ìní ìfisíkàáwọ́ ránṣẹ́ sí Society.
Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀ràn tí ó wà lókè yìí, kọ̀wé sí Treasurer’s Office, Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, 25 Columbia Heights, Brooklyn, New York 11201-2483, tàbí sí ọ́fíìsì Society, tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ̀.