Olùfúnni ní “Gbogbo Ẹ̀bùn Rere”
“Ní àkókò kan òjíṣẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì Reformed kan késí mi. Ó fẹ́ mọ bí mo ṣe ń ṣàbójútó ṣọ́ọ̀ṣì mi. Mo wí fún un pé: . . . ‘A kìí san owó oṣù; kò sí ohun tí àwọn ènìyàn lè jà sí. A kìí gba owó-igbá.’ ‘Bawó ni o ṣe ń rí owó?’ ni ó béèrè. Mo fèsì pé, ‘Wàyí o, Dókítà——, bí mo bá sọ òkodoro òtítọ́ fún ọ yóò ṣoro fún ọ láti gbà á gbọ́. Nígbà tí àwọn ènìyàn bá lọ́kàn-ìfẹ́ nínú ọ̀nà yìí, wọn kìí rí i kí a gbé igbá ọrẹ kọjá níwájú wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n ríi pé àwọn ìnáwó wà láti ṣe. Wọ́n á wí fún araawọn pé, “Gbọ̀ngàn yìí náni ní iye kan. . . . Báwo ni mo ṣe le fowó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ yìí?”’ Ó wò mí bí ẹni pé ó ronú pé, ‘Kí ni ó fi mí pè—súpo?’ Mo wí pé, ‘Wàyí o, Dókítà——, òtítọ́ gidi ni mo ń sọ fún ọ. . . . Nígbà tí a bá bùkún ẹnìkan tí ó sì ní ohun-ìní èyíkéyìí, yoo fẹ́ láti lò ó fún Oluwa. Bí òun kò bá ní ohun-ìní, èéṣe tí a fi níláti tì í sí i?’”
—Charles T. Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Society, “Ile-Iṣọ Na,” July 15, 1915 [Gẹ̀ẹ́sì].
ÀWA ń fifúnni nítorí pé Jehofa Ọlọrun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó fifúnni. Fífúnni rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìṣẹ̀dá ní ọdún gbọ́nhan sẹ́yìn—ìṣẹ̀dá rẹ̀ àkọ́kọ́ gan-an, “Ọmọ bíbí rẹ kanṣoṣo.” (Johannu 3:16) Nítorí ìfẹ́, ó fi ẹ̀bùn ìwàláàyè fún àwọn ẹlòmíràn.
Jesu Kristi, Ọmọkùnrin Ọlọrun, ni ẹ̀bùn Jehofa títóbi jùlọ fún wa. Ṣùgbọ́n Ọmọkùnrin Ọlọrun, nínú araarẹ̀, kìí ṣe òpin fífúnni Ọlọrun. “Ọ̀pọ̀ ore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun” ni ohun tí aposteli Paulu pè ní “aláìlèsọ ẹ̀bùn” Jehofa. (2 Korinti 9:14, 15) Ó ṣe kedere pé ẹ̀bùn yìí ní àròpọ̀ gbogbo iye inúrere àti ìṣeun-ìfẹ́ tí Ọlọrun nawọ́ rẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ̀ nípasẹ̀ Jesu nínú. Irú inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí bẹ́ẹ̀ jẹ́ àgbàyanu débi pe ó rékọjá agbára ìṣàpèjúwe tàbí ti ìsọ̀rọ̀ ènìyàn. Síbẹ̀, àwọn apá mìíràn ṣì wà nípa ti fífúnni Ọlọrun.
Ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, ọba kan fi pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìrẹ̀lẹ̀ gbà pé ohun rere yòówù tí òun ìbáà fifúnni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn níti gidi jẹ́ ti Jehofa. Ó wí pé: “Nítorí ohun gbogbo ní ọ̀run àti ní ayé tìrẹ ni; ìjọba ni tìrẹ, Oluwa, a sì gbé ọ lékè ni orí fún ohun gbogbo. . . . Ṣùgbọ́n ta ni èmi, àti kí ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí? nítorí ohun gbogbo ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní tií wá, àti nínu ohun ọwọ́ rẹ ni àwa ti fifún ọ.”—1 Kronika 29:11-14.
Àpẹẹrẹ ti Ọlọrun
Jakọbu, ọmọlẹ́yìn Jesu Kristi, mọ̀ pé ní gbogbo ọ̀nà Jehofa Ọlọrun ni orísun ohunkóhun tí ó bá dára. Kìkì àwọn ẹ̀bùn pípé ni ó ń wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Jakọbu kọ̀wé pé: “Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì ń sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ Ẹni tí kò lè sí ìyípadà tàbí òjìji àyídà.”—Jakọbu 1:17.
Àní nínú ọ̀ràn fífúnni ní ẹ̀bùn, Jakọbu rí bí Ọlọrun ti yàtọ̀ sí àwọn ènìyàn tó. Àwọn ènìyàn lè fúnni ní àwọn ẹ̀bùn tí ó dára ṣùgbọ́n wọn kìí fìgbà gbogbo ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí lè rúyọ láti inú ìsúnniṣe onímọtara-ẹni-nìkan, tàbí kí a lò wọ́n láti fi dán ẹnìkan wò láti ṣe ohun tí kò dára. Níti Jehofa, kò sí àyídà; òun kìí yípadà. Fún ìdí yìí, bí àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ ti rí kò yípadà. Wọ́n sábà máa ń jẹ́ mímọ́. Wọ́n sábà máa ń gbé ire àti ayọ̀ ìran ènìyàn ga síwájú. Wọ́n sábà máa ń jẹ́ onínúrere tí ó sì kún fun ìrànlọ́wọ́, wọn kìí ṣe apanirun.
Àwọn Ìsúnniṣe fún Fífúnni ní Àwọn Ẹ̀bùn
Ní àwọn ọjọ́ Jakọbu, àwọn gbajúmọ̀ olórí ìsìn ń fúnni ní ẹ̀bùn kìkì kí àwọn ènìyàn baà lè rí wọn. Wọ́n ń fúnni láti inú ìsúnniṣe búburú. Bí wọ́n ti ní ìhárag̀ag̀a fún ìyìn àwọn ènìyàn, wọ́n fi àwọn ìlànà òdodo wọn bánidọ́rẹ̀ẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Kristian, níláti yàtọ̀. Jesu gbà wọ́n nímọ̀ràn pé: “Nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìtọrẹ àánú rẹ, máṣe fun fèrè níwájú rẹ, bí àwọn àgàbàgebè ti ń ṣe ní sinagogu àti ní ìta, kí wọn kí ó lè gba ìyìn ènìyàn. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ná. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìtọrẹ àánú rẹ, máṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ kí ó mọ ohun ti ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe; kí ìtọrẹ àánú rẹ kí ó lè wà ní ìkọ̀kọ̀; Baba rẹ tí ó sì ríran ní ìkọ̀kọ̀, òun tìkáraarẹ̀ yóò san án fún ọ ní gbangba.”—Matteu 6:2-4.
Ìdí tí Kristian kan fi ń fúnni ní ẹ̀bùn jẹ́ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kúnjú àìní kan tàbí láti mú wọn láyọ̀ tàbí láti gbé ìjọsìn tòótọ́ ga síwájú. Kìí ṣe fún ìṣògo ara-ẹni. Ó ṣetán, ojú Jehofa, lè ríran rí ibi igun ọkàn-àyà wa tí ó wà ní kọ́lọ́fín jùlọ. Ó lè rí ìsúnniṣe inú-lọ́hùn-ún jùlọ tí ó wà lẹ́yìn àwọn ẹ̀bùn àánú wa.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń sakun láti tẹ̀lé àpẹẹrẹ Jehofa àti Ọmọkùnrin rẹ̀ níti fífúnni ní ẹ̀bùn. Wọ́n ń fúnni nínú ohun tí wọ́n ní. Wọ́n ní ìhìnrere Ìjọba náà, wọ́n sì fi èyí fúnni fún ìbùkún àwọn ẹlòmíràn. Wọ́n mọ̀ pé Owe 3:9 sọ pe: “Fi ohun-ìní rẹ bọ̀wọ̀ fún Oluwa, àti láti inú gbogbo àkọ́bí ìbísí-oko rẹ.” Nítorí pé ọ́fíìsì ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan, ìjọ, àti ẹnìkọ̀ọ̀kan ń fi ìfọkànsìn wá ọ̀nà láti ṣètìlẹ́yìn fún ire gbogbo ènìyàn, ẹgbẹ́ ará lápapọ̀ ni a mú lókun tí a sì mú láásìkí nípa tẹ̀mí. Aásìkí ti ara kìí jálẹ̀ sí aásìkí tẹ̀mí, ṣùgbọ́n aásìkí tẹ̀mí ń mú aásìkí ti ara tí ó tó fún àwọn ohun tí iṣẹ́ Jehofa nílò wá.
Àwọn Ọ̀nà Láti Ṣàjọpín
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni ó wà tí olúkúlùkù ènìyàn lè gbà ṣètọrẹ lẹ́nìkọ̀ọ̀kan láti ṣètìlẹ́yìn fún ìhìnrere. Ọ̀nà kan jẹ́ nípa ti àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Gbogbo àwọn mẹ́ḿbà ìjọ ni wọ́n ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ẹnìkan ti pèsè owó fún kíkọ́ tàbí híháyà, fún iná mànàmáná, fún ẹ̀rọ amúlégbóná tàbí amúlétutù, àti fún àbójútó rẹ̀. Níwọ̀n bí ìtìlẹ́yìn tí olúkúlùkù ènìyàn ń ṣe fún ìjọ ti ṣepàtàkì, àwọn àpótí ọrẹ ni a ń gbé sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe tí a kójọ ni a sì ń lò fún àwọn ìnáwó ìjọ. Láti inú àwọn owó tí ó ṣẹ́kù, a lè fi ọrẹ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ Watch Tower àdúgbò, ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu ìjọ náà.
Àwọn ọrẹ ni a lè fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ Society fúnraarẹ̀ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìtìlẹ́yìn fún àwọn míṣọ́nárì àti àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní àwọn apá ilẹ̀-ayé níbi tí ìhìnrere náà kò tíì dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn. Àwọn ìnáwó mìíràn nínú títan ìhìnrere kálẹ̀ wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò. Aposteli Paulu, ẹni tí ó fi àpẹẹrẹ náà lélẹ̀ nínú iṣẹ́ rírìnrìn-àjò ní ọ̀rùndún kìn-ín-ní, gbóríyìn fún ìjọ tí ó wà ní Filippi pé: “Ẹ̀yin ránṣẹ́, ẹ sì tún ránṣẹ́ fún àìní mi.” (Filippi 4:14-16) Yàtọ̀ sí iye owó tí àwọn apá-ẹ̀ka iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún wọ̀nyí ń náni, èyí tí gbogbo ẹ̀ka ní, gbígbọ́ bùkátà ilé Beteli kọ̀ọ̀kan àti àwọn tí wọ́n ń gbé tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Kíkọ àti títẹ àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ní ìhìn-iṣẹ́ gbígbádùnmọ́ni ti ihinrere náà jẹ́ àwọn àǹfààní tí Ọlọrun fifúnni níti gidi, ṣùgbọ́n ìpínkiri àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tún ṣe pàtàkì, ó sì mú àwọn ìnáwó lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà ìnáwó lórí àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀ wà, láì mẹ́nukan àwọn ẹjọ́ tí a ti ṣe ni kóòtù láti ‘gbèjà kí a sì fìdí ìhìnrere múlẹ̀ lọ́nà òfin.’—Filippi 1:7.
Àkókò tí ìránṣẹ́ Jehofa kọ̀ọ̀kan ń lò ní wíwàásù ìhìnrere náà jẹ́ pẹ̀lú ìfínnúfíndọ̀, bákan náà sì ni fífi tí ó ń fi owó-àkànlò ṣètọrẹ. Yíya owó sọ́tọ̀ déédéé láti lò fún ìtìlẹ́yìn ìmúgbòòrò ìjọsìn tòótọ́ ni aposteli Paulu dá lámọ̀ràn: “Ǹjẹ́ níti ìdáwó fún àwọn ènìyàn mímọ́, . . . ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín fi sínú ìṣúra lọ́dọ̀ araarẹ̀ ní apákan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti ṣe rere fún un.”—1 Korinti 16:1, 2.
Nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìtọrẹ, òun kìí sábà mọ bí a o ṣe lò ó ní pàtó, ṣùgbọ́n ó ń rí àwọn ìyọrísí rẹ̀ nínú ìmúgbòòrò ìwàásù Ìjọba náà. Àwọn ìròyìn nínú 1993 Yearbook of Jehovah’s Witnesses fihàn pé ìhìnrere Ìjọba náà ni àwọn Kristian òjíṣẹ́ tí iye wọn ju 4,500,000 lọ ti ń wàásù rẹ̀ ní iye tí ó ju 200 ilẹ̀ àti àwọn erékùṣù òkun lọ. Àwọn ìròyìn wọ̀nyí ń mú ọkàn-àyà yọ̀. Nítorí náà, láìka ìwọ̀n ẹ̀bùn èyíkéyìí sí, ó ń ṣèrànlọ́wọ́ nínú títan ìhìnrere náà kálẹ̀ kárí-ayé.
Iṣẹ́ yìí ni a ń pèsè ìnáwó fún nípasẹ̀ àpapọ̀ fífúnni tí gbogbo ènìyàn ń ṣe. Àwọn kan lè pèsè púpọ̀, èyí tí ń ṣèrànlọ́wọ́ fún iṣẹ́ ìwàásù náà ní ìwọ̀n kan tí ó túbọ̀ ga síi. Àwọn mìíràn ń pèsè díẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn wọnnì tí wọ́n ṣe ìtọrẹ tí kò tó nǹkan kò níláti tijú tàbí lérò pé ìpín tiwọn kò jẹ́ nǹkankan. Dájúdáju Jehofa kò nímọ̀lára lọ́nà yẹn. Jesu mú èyí ṣe kedere nígbà tí ó fihàn bí Jehofa ṣe mọrírì ọrẹ kékeré opó náà tó. “Ó sì rí tálákà opó kan pẹ̀lú, ó ń sọ owó-idẹ wẹ́wẹ́ méjì síbẹ̀. Ó sì wí pé, Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, tálákà opó yìí fi sí i ju gbogbo wọn lọ: nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí fi sínú ẹ̀bùn Ọlọrun láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní wọn; ṣùgbọ́n òun nínú àìní rẹ̀ ó sọ gbogbo ohun-ìní rẹ̀ tí ó ní sínú rẹ̀.”—Luku 21:2-4.
Láìka ohun tí ipò ìṣúnná-owó wa lè jẹ́ sí, a lè fifúnni ní àwọn ọ̀nà tí ó dùnmọ́ Jehofa nínú. Onipsalmu náà ṣàkópọ̀ bí a ṣe lè fi ògo fún Ọba àti Onídàájọ́ wa lọ́nà tí ó dára. Ó wí pé: “Ẹ fi ògo fún orúkọ Oluwa: mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀.” (Orin Dafidi 96:8) Nítorí náà, ǹjẹ́ kí àwa kí ó ṣàfarawé àpẹẹrẹ onífẹ̀ẹ́ ti Baba wa ọ̀run nípa fífúnni ni ẹ̀bùn ọlọ́yàyà nítorí òun ni ó kọ́kọ́ fifún wa.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]
BÍ ÀWỌN KAN ṢE Ń ṢE ÌTỌRẸ FÚN IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ ÌJỌBA NAA
◻ ÀWỌN ỌRẸ FUN IṢẸ́ YÍKÁ-AYÉ: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ya iye kan sọ́tọ̀ tàbí ṣètò iye owó kan tí wọ́n ń fi sínú àwọn àpótí ọrẹ tí a lẹ ìsọfúnni náà: “Àwọ́n Ọrẹ fun Iṣẹ́ Society Yíká-Ayé—Matteu 24:14” mọ́ lára. Lóṣooṣù ni ìjọ ń fi àwọn owó wọ̀nyí ránṣẹ́ yálà sí orílé-iṣẹ́ àgbáyé ní Brooklyn, New York, tàbí sí ẹ̀ka ilẹ́-iṣẹ́ tí ó súnmọ́ wọn jùlọ.
◻ ÀWỌN Ẹ̀BÙN: Àwọn ìtọrẹ owó tí a fínúfíndọ̀ ṣe ni a lè fi ránṣẹ́ ní tààràtà sí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, 25 Columbia Heights, Brooklyn, New York 11201, tàbí si ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ Society ti àdúgbò. Òkúta iyebíye tàbí àwọn nǹkan iyebíye mìíràn ni a lè fi tọrẹ pẹ̀lú. Lẹ́tà ṣókí kan tí ó sọ pé irú èyí jẹ́ ẹ̀bùn pàtápátá níláti bá àwọn ọrẹ wọ̀nyí rìn.
◻ ÌṢÈTÒ ÌTỌRẸ ONÍPÒ ÀFILÉLẸ̀: Owó ni a lè fifún Watch Tower Society làti máa lò bíi ohun àfúnniṣọ́ títí fi di ìgbà ikú olùtọrẹ náà, pẹ̀lú ìpèsè pé ti ọ̀ràn ìlò ara-ẹni kan bá dìde, a o dá a padà fún ẹni tí ó fi tọrẹ.
◻ OWÓ ÌBÁNIGBÓFÒ: Watch Tower Society ni a lè lò orúkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní ìlànà ètò ìbánigbófò ìwàláàyè tàbí nínú ìwéwèé owó àsanfúnni fún ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́. A gbọ́dọ̀ fi irú àwọn ìṣètò bẹ́ẹ̀ tó Society létí.
◻ OWÓ TÍ A FI PAMỌ SÍ BÁǸKÌ: Awọ́n àkáǹtì ní bánkì, àwọn ìwé ẹ̀rí owó ìdókòwò, tàbí owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ẹnìkan tí a fi pamọ́ ni a lè físíkàáwọ́ tàbí mú kí ó ṣeé san nígbà ikú fún Watch Tower Society, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àbèèrè-fún ti bánkì àdúgbò náà. A gbọ́dọ̀ fi irú àwọn ìṣètò bẹ́ẹ̀ tó Society létí.
◻ ÀWỌN ÌWÉ Ẹ̀TỌ́ LÓRÍ OWÓ ÌDÓKÒWÒ ATI LÓRÍ OWÓ TÍ A FI YÁNI: Àwọn ìwé ẹ̀tọ́ lórí owó ìdókòwò àti lórí owó tí a fi yáni ni a lè fi tọrẹ fún Watch Tower Society yálà gẹgẹ bí ẹ̀bùn pátápátá tàbí lábẹ́ ìṣètò kan níbi tí a ó ti máa báa lọ ní sísan owó tí ó wọlé wá lórí èyí fún olùtọrẹ náà.
◻ ILÉ TÀBÍ ILẸ̀: Àwọn ilé tàbí ilẹ̀ tí ó ṣeétà ni a lè fi tọrẹ fún Watch Tower Society yálà nípa ṣíṣe é ní ẹ̀bùn pátápátá tàbí nípa pípa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun-ìní olùtọrẹ náà nígbà tí ó bá ṣì wàláàyè, ẹni tí ó ṣì lè máa báa lọ láti máa gbé inú rẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Ẹni kan níláti kàn sí Society ṣáájú fífi ìwé àṣẹ sọ ilè tàbí ilẹ̀ èyíkéyìí di ti Society.
◻ ÀWỌN ÌWÉ ÌHÁGÚN ATI OHUN-ÌNÍ ÌFISÍKÀÁWỌ́: Dúkìá tàbí owó ni a lè fi sílẹ̀ bíi ogún fún Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania nípasẹ̀ ìwé ìhágún tí a múṣẹ lábẹ́ òfin, tàbí tí a lè dárúkọ Society gẹ́gẹ́ bí olùjànfààní irú ìwé àdéhùn fífi ohun-ìní síkàáwọ́ ẹni bẹ́ẹ̀. Àwọn ohun-ìní ìfisíkàáwọ́ tí ètò-àjọ ìsìn kan ń jànfààní nínú rẹ̀ lè pèsè àwọn ànfààní mélòókan nínú ọ̀ràn owó-orí. Ẹ̀dà kan nínú ìwé ìhágún tàbí ìwé ohun-ìní ìfisíkàáwọ́ ni a níláti fi ránṣẹ́ sí Society.
Fún isọ́fúnni síwáju síi nípa àwọn irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, kọ̀wé sí Treasurer’s Office, Watch Tower Bible and Tract Society, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State. Nigeria.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Bí a ti ṣe ń lo àwọn ọrẹ rẹ:
1. Àwọn olùyọ̀nda ara-ẹni fún iṣẹ́ Beteli
2. Iṣẹ́ ìkọ́lé ẹ̀ka ọ́fíìsì
3. Ìpèsè ìrànlọ́wọ́ fún ìjábá
4. Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba
5. Àwọn míṣọ́nnárì