ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 11/15 ojú ìwé 14-15
  • Mọrírì Ìwà Ọ̀làwọ́ Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mọrírì Ìwà Ọ̀làwọ́ Jèhófà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌWÀ Ọ̀LÀWỌ́ TÓ TA YỌ JÙ LỌ
  • “Iṣẹ́ Náà Pọ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Àṣẹ́kùsílẹ̀ Wọn Dí Àìnító Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Ní Ẹ̀mí Ìmúratán
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fún Àwọn Èèyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 11/15 ojú ìwé 14-15
Obìnrin kan ki káàdì tó fi ń gbowó ní báǹkì bọ ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń sanwó nílé ìtajà

Mọrírì Ìwà Ọ̀làwọ́ Jèhófà

Ọ̀LÀWỌ́ ni Jèhófà Ọlọ́run. (Ják. 1:17) Àwọn ìràwọ̀ tó máa ń kún ojú ọ̀run lálẹ́ àtàwọn ewéko títutù yọ̀yọ̀ tó ń mú kí ilẹ̀ ayé dùn-ún wò ń fi hàn pé ọ̀làwọ́ ni Jèhófà lóòótọ́.​—Sm. 65:​12, 13; 147:​7, 8; 148:​3, 4.

Onísáàmù náà mọrírì àwọn ohun tí Jèhófà dá gan-an débi pé ó kọ orin kan láti yin Jèhófà lógo. Tó o bá ka ìwé Sáàmù 104, ìwọ náà á rí ìdí tó fi yẹ kó o yin Jèhófà. Onísáàmù náà sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò máa kọrin sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé mi; èmi yóò máa kọ orin atunilára sí Ọlọ́run mi níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà.” (Sm. 104:33) Ṣó wu ìwọ náà láti yin Jèhófà?

ÌWÀ Ọ̀LÀWỌ́ TÓ TA YỌ JÙ LỌ

Jèhófà fẹ́ kí àwa náà jẹ́ ọ̀làwọ́ bíi tiẹ̀. Nínú ọ̀rọ̀ tó mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ, Jèhófà jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká jẹ́ ọ̀làwọ́, ó ní: “Fún àwọn ọlọ́rọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ní àṣẹ ìtọ́ni láti má ṣe jẹ́ ọlọ́kàn-gíga, kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa; láti máa ṣe rere, láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, láti jẹ́ aláìṣahun, kí wọ́n múra tán láti ṣe àjọpín, kí wọ́n máa fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.”​—1 Tím. 6:​17-19.

Nígbà tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì, ó sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ ọ̀làwọ́. Ó sọ pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́r. 9:7) Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù sọ àwọn tó máa ń jàǹfààní látinú ìwà ọ̀làwọ́: ẹni tí wọ́n hùwà ọ̀làwọ́ sí á rí ohun tó nílò gbà; ẹni tó hùwà ọ̀làwọ́ síni á sì rí ìbùkún yanturu gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.​—2 Kọ́r. 9:​11-14.

Níparí lẹ́tà rẹ̀ yìí, Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà títayọ jù lọ tí Ọlọ́run gbà jẹ́ ọ̀làwọ́. Ó sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run fún ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ aláìṣeé-ṣàpèjúwe.” (2 Kọ́r. 9:15) Ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa yìí ni gbogbo oore tó ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi. Oore náà pọ̀ débi pé ó kọjá àfẹnusọ.

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì gbogbo ohun tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ti ṣe fún wa àtàwọn ohun tí wọ́n ṣì máa ṣe? Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa lo àkókò wa, okun wa àtàwọn ohun ìní wa, yálà ó kéré tàbí ó pọ̀, láti ti ìjọsìn mímọ́ Jèhófà lẹ́yìn.​—1 Kíró. 22:14; 29:​3-5; Lúùkù 21:​1-4.

Ọ̀nà Táwọn Kan ń gbà Ṣètọrẹ Fún Iṣẹ́ Kárí Ayé

Bó ṣe rí nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń “ya ohun kan sọ́tọ̀,” tàbí kí wọ́n ya iye owó kan sọ́tọ̀, kí wọ́n sì fi owó náà sínú àpótí ìjọ tá a kọ “Ọrẹ fún Iṣẹ́ Kárí Ayé” sí. (1 Kọ́r. 16:2) Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè wọn. O sì tún lè fi ọrẹ ránṣẹ́ ní tààràtà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. Tó o bá fẹ́ mọ orúkọ àjọ tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lábẹ́ òfin, jọ̀wọ́ kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè rẹ. O lè rí àdírẹ́sì ẹ̀ka ọ́fíìsì náà lórí ìkànnì www.jw.org/yo. Lára àwọn ọrẹ tó o lè fi ránṣẹ́ sí wa ní tààràtà rèé:

Ẹ̀BÙN

  • O lè fi ọrẹ ránṣẹ́ látinú àkáǹtì rẹ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí kó o lo káàdì tí owó wà lórí rẹ̀ tàbí káàdì tí wọ́n fi ń rajà láwìn láti fi ọrẹ ránṣẹ́. Ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kan, o lè fi ọrẹ ránṣẹ́ látorí ìkànnì jw.org tàbí ìkànnì míì tí ẹ̀ka ọ́fíìsì bá fọwọ́ sí.

  • O lè fi owó, ohun ọ̀ṣọ́ tó ṣeyebíye tàbí dúkìá mìíràn ṣètọrẹ. Kọ lẹ́tà kó o sì fi ránṣẹ́ pẹ̀lú owó tàbí ọrẹ náà láti fi hàn pé ẹ̀bùn ni.

ỌRẸ TÓ ṢEÉ GBÀ PA DÀ

  • O lè fi owó síkàáwọ́ àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò pé kí wọ́n máa lò ó. Àmọ́, àjọ náà máa dá owó náà pa dà tó o bá béèrè fún un.

  • Kọ lẹ́tà láti fi hàn pé ńṣe lo fi owó náà síkàáwọ́ àjọ náà títí dìgbà tí wàá fẹ́ gbà á pa dà.

ỌRẸ TÉÈYÀN WÉWÈÉ

Yàtọ̀ sí pé ká dìídì fi owó tàbí dúkìá mìíràn ṣètọrẹ, àwọn ọ̀nà míì tún wà tá a lè gbà ṣètọrẹ tó máa ṣàǹfààní fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Ọ̀nà yòówù kó o fẹ́ gbà ṣètọrẹ, jọ̀wọ́ kọ́kọ́ kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè rẹ, kí wọ́n lè jẹ́ kó o mọ ọ̀nà tó bófin mu tó o lè gbà ṣe é. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun tí òfin sọ nípa ọrẹ máa ń yàtọ̀ síra, ó ṣe pàtàkì pé kó o fi ọ̀rọ̀ lọ amòfin tó mọ̀ nípa rẹ̀ dáadáa kó o tó yan ọ̀nà tó o máa gbà ṣètọrẹ. Díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tó o lè gbà ṣètọrẹ rèé:

Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gba owó ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́.

Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó tá a ní sí báńkì, tàbí owó tá a fi pa mọ́ sí báńkì fún àkókò pàtó kan, tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́, síkàáwọ́ àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò pé kí àjọ náà máa lò ó tàbí ká ṣètò pé kí wọ́n san owó náà fún àjọ náà lẹ́yìn ikú ẹni gẹ́gẹ́ bí ìlànà báńkì ti sọ.

Ìpín Ìdókòwò, Ẹ̀tọ́ Orí Owó Ìdókòwò àti Ti Ètò Ẹ̀yáwó: A lè fi ẹ̀tọ́ ìpín ìdókòwò, ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ẹ̀yáwó ta àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò lọ́rẹ. A sì lè tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn, pé kí ẹ̀tọ́ náà di ti àjọ náà lẹ́yìn ikú ẹni.

Ilẹ̀ àti Ilé: A lè fi ilẹ̀ tó ṣeé tà tọrẹ fún àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn, tàbí tó bá jẹ́ ilẹ̀ tí ilé wà lórí rẹ̀ téèyàn ṣì ń gbé inú rẹ̀, olùtọrẹ náà lè fi tọrẹ àmọ́ kó sọ pé òun á ṣì máa gbé inú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tóun bá ṣì wà láàyè.

Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Téèyàn Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò nípasẹ̀ ìwé ìhágún tá a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí ká ṣe ìwé pé àjọ náà ni ẹni tí yóò ni ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́.

Gbólóhùn náà, “ọrẹ téèyàn wéwèé” fi hàn pé ẹni tó fẹ́ ṣètọrẹ gbọ́dọ̀ ronú dáadáa kó tó ṣe irú ìtọrẹ bẹ́ẹ̀.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́