ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w16 November ojú ìwé 19-20
  • “Iṣẹ́ Náà Pọ̀”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Iṣẹ́ Náà Pọ̀”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mọrírì Ìwà Ọ̀làwọ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Ní Ẹ̀mí Ìmúratán
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Àṣẹ́kùsílẹ̀ Wọn Dí Àìnító Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fún Àwọn Èèyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
w16 November ojú ìwé 19-20
Ọba Dáfídì ń fi àwòrán bí wọ́n á ṣe kọ́ tẹ́ńpìlì han ọkùnrin kan; arákùnrin kan ń wo àwòrán bí wọ́n á ṣe kọ́ ilé

“Iṣẹ́ Náà Pọ̀”

LỌ́JỌ́ kan, Dáfídì pe ìpàdé pàtàkì kan ní Jerúsálẹ́mù. Ó pe àwọn ọmọ aládé, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àtàwọn ọkùnrin alágbára ńlá. Inú gbogbo wọn dùn nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì tí Dáfídì tìtorí rẹ̀ pè wọ́n. Ó sọ fún wọn pé Jèhófà ti yan Sólómọ́nì ọmọ òun láti kọ́ ilé kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n máa yà sí mímọ́ fún ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́. Ọlọ́run ti fi àwòrán ilé náà han Dáfídì lábẹ́ ìmísí, Dáfídì sì fún Sólómọ́nì ní àwòrán náà. Dáfídì wá sọ pé: “Iṣẹ́ náà pọ̀; nítorí ilé aláruru náà kì í ṣe fún ènìyàn, bí kò ṣe fún Jèhófà Ọlọ́run.”—1 Kíró. 28:1, 2, 6, 11, 12; 29:1.

Lẹ́yìn náà Dáfídì wá bi wọ́n pé: ‘Ta ni ń bẹ níbẹ̀ tí ó fẹ́ fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti fi ẹ̀bùn kún ọwọ́ rẹ̀ lónìí fún Jèhófà?’ (1 Kíró. 29:5) Ká sọ pé ìwọ náà wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, kí lo máa ṣe? Ṣé wàá fi àwọn ohun ìní rẹ ṣe ìtìlẹyìn fún iṣẹ́ ńlá yìí? Ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ohun ìní wọn ṣe ìtìlẹyìn. Èyí mú káwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ‘yọ̀ lórí ṣíṣe àwọn ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe, nítorí pé ọkàn-àyà pípé pérépéré ni wọ́n fi ṣe àwọn ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe fún Jèhófà.’—1 Kíró. 29:9.

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà ṣètò tẹ́ńpìlì míì tó ju tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́, ìyẹn sì ni tẹ́ńpìlì tẹ̀mí. Jèhófà ṣètò tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí yìí kí àwa èèyàn lè máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. (Héb. 9:11, 12) Báwo ni Jèhófà ṣe ń fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀ lónìí? Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ni. (Mát. 28:19, 20) Iṣẹ́ ìwàásù yìí ń sèso rere torí pé lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn là ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣèrìbọmi, ọ̀pọ̀ ìjọ la sì ń dá sílẹ̀.

Ìbísí yìí ń mú kó pọn dandan pé ká túbọ̀ máa tẹ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Bákan náà, à ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó pọ̀ sí i, a sì ń tún àwọn tó ń fẹ́ àbójútó ṣe, yàtọ̀ síyẹn a tún ń kọ́ àwọn gbọ̀ngàn àpéjọ. Ó dájú pé iṣẹ́ ńlá là ń gbéṣe bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere jákèjádò ayé, iṣẹ́ ọ̀hún sì ń mérè wá.—Mát. 24:14.

Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti àwọn èèyàn máa ń mú ká “fi ẹ̀bùn kún ọwọ́ wa fún Jèhófà’ nípa ṣíṣe ọrẹ àtinúwá. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti “fi àwọn ohun ìní [wa] tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà,” a sì ń rí bí ètò Ọlọ́run ṣe ń fi ọgbọ́n àti òye lo àwọn ọrẹ náà ká lè ṣàṣeparí iṣẹ́ tó tóbi jù lọ tí Jèhófà gbé fáwa èèyàn rẹ̀.—Òwe 3:9.

Ọ̀nà Táwọn Kan ń gbà Ṣètọrẹ Fún Iṣẹ́ Kárí Ayé

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń “ya ohun kan sọ́tọ̀,” tàbí kí wọ́n ya iye owó kan sọ́tọ̀, kí wọ́n sì fi owó náà sínú àpótí ìjọ tá a kọ “Ọrẹ fún Iṣẹ́ Kárí Ayé” sí. (1 Kọ́r. 16:2) Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè wọn. O sì tún lè fi ọrẹ ránṣẹ́ ní tààràtà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. Tó o bá fẹ́ mọ orúkọ àjọ tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lábẹ́ òfin, jọ̀wọ́ kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè rẹ. O lè rí àdírẹ́sì ẹ̀ka ọ́fíìsì náà lórí ìkànnì www.jw.org/yo. Lára àwọn ọrẹ tó o lè fi ránṣẹ́ sí wa ní tààràtà rèé:

Ẹ̀BÙN

  • O lè fi ọrẹ ránṣẹ́ látinú àkáǹtì rẹ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí kó o lo káàdì tí owó wà lórí rẹ̀ tàbí káàdì tí wọ́n fi ń rajà láwìn láti fi ọrẹ ránṣẹ́, o sì lè fi owó ránṣẹ́ látorí fóònù rẹ. Ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kan, o lè fi ọrẹ ránṣẹ́ látorí ìkànnì jw.org tàbí ìkànnì míì tí ẹ̀ka ọ́fíìsì bá fọwọ́ sí.

  • O lè fi owó, ohun ọ̀ṣọ́ tó ṣeyebíye tàbí dúkìá mìíràn ṣètọrẹ. Kọ lẹ́tà kó o sì fi ránṣẹ́ pẹ̀lú owó tàbí ọrẹ náà láti fi hàn pé ẹ̀bùn ni.

ỌRẸ TÓ ṢEÉ GBÀ PA DÀ

  • O lè fi owó síkàáwọ́ àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò pé kí wọ́n máa lò ó. Àmọ́, àjọ náà máa dá owó náà pa dà tó o bá béèrè fún un.

  • Kọ lẹ́tà láti fi hàn pé ńṣe lo fi owó náà síkàáwọ́ àjọ náà títí dìgbà tí wàá fẹ́ gbà á pa dà.

ỌRẸ TÉÈYÀN WÉWÈÉ

Yàtọ̀ sí pé ká dìídì fi owó tàbí dúkìá mìíràn ṣètọrẹ, àwọn ọ̀nà míì tún wà tá a lè gbà ṣètọrẹ tó máa ṣàǹfààní fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Ọ̀nà yòówù kó o fẹ́ gbà ṣètọrẹ, jọ̀wọ́ kọ́kọ́ kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè rẹ, kí wọ́n lè jẹ́ kó o mọ ọ̀nà tó bófin mu tó o lè gbà ṣe é. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun tí òfin sọ nípa ọrẹ máa ń yàtọ̀ síra, ó ṣe pàtàkì pé kó o fi ọ̀rọ̀ lọ amòfin tó mọ̀ nípa rẹ̀ dáadáa kó o tó yan ọ̀nà tó o máa gbà ṣètọrẹ. Díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tó o lè gbà ṣètọrẹ rèé:

Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gba owó ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́.

Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó tá a ní sí báńkì, tàbí owó tá a fi pa mọ́ sí báńkì fún àkókò pàtó kan, tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́, síkàáwọ́ àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò pé kí àjọ náà máa lò ó tàbí ká ṣètò pé kí wọ́n san owó náà fún àjọ náà lẹ́yìn ikú ẹni gẹ́gẹ́ bí ìlànà báńkì ti sọ.

Ìpín Ìdókòwò, Ẹ̀tọ́ Orí Owó Ìdókòwò àti Ti Ètò Ẹ̀yáwó: A lè fi ẹ̀tọ́ ìpín ìdókòwò, ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ẹ̀yáwó ta àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò lọ́rẹ. A sì lè tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn, pé kí ẹ̀tọ́ náà di ti àjọ náà lẹ́yìn ikú ẹni.

Ilẹ̀ àti Ilé: A lè fi ilẹ̀ tó ṣeé tà tọrẹ fún àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn, tàbí tó bá jẹ́ ilẹ̀ tí ilé wà lórí rẹ̀ téèyàn ṣì ń gbé inú rẹ̀, olùtọrẹ náà lè fi tọrẹ àmọ́ kó sọ pé òun á ṣì máa gbé inú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tóun bá ṣì wà láàyè.

Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Téèyàn Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún àjọ kan tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò nípasẹ̀ ìwé ìhágún tá a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí ká ṣe ìwé pé àjọ náà ni ẹni tí yóò ni ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́.

Gbólóhùn náà, “ọrẹ téèyàn wéwèé” fi hàn pé ẹni tó fẹ́ ṣètọrẹ gbọ́dọ̀ ronú dáadáa kó tó ṣe irú ìtọrẹ bẹ́ẹ̀.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, lọ sí ìlujá náà “Ṣe Ọrẹ Láti Ti Iṣẹ́ Tá À Ń Ṣe Kárí Ayé Lẹ́yìn” tó wà lọ́wọ́ ìsàlẹ̀ ojúde ìkànnì wa, ìyẹn jw.org/yo tàbí kó o kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́