Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù July
“Ọwọ́ wo lo rò pé Ọlọ́run fi ń mú àwọn àdúrà wa? Ṣé o rò pé ó máa ń fẹ́ gbọ́ wọn àbí kò tiẹ̀ kà wọ́n sí nǹkan pàtàkì?” Jẹ́ kó fèsì. Fi ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ July 1 hàn án, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ìpínrọ̀ tó wà lábẹ́ ìbéèrè àkọ́kọ́ àti ó kéré tán ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan níbẹ̀. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kí o sì ṣètò láti pa dà wá dáhùn ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ July 1
“Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ alágbára gbogbo, ṣé o rò pé òun ló yẹ ká dá lẹ́bi fún gbogbo nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Jákọ́bù 1:13.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tí àwọn nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀, ó sì sọ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe láti fòpin sí ìwà ibi àti ìyà.”
Ji! July–August
“Ìkànnì àjọlò ti mú kó túbọ̀ rọrùn fáwọn èèyàn láti ní àwọn ọ̀rẹ́ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ju ti ìgbàkígbà lọ. Ìwà wo lo rò pé ó ṣe pàtàkì jù pé kí ọ̀rẹ́ gidi ní? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ìmọ̀ràn tó wúlò tí Bíbélì fún wa nípa bí a ṣe lè yan ọ̀rẹ́. [Ka Jákọ́bù 1:19.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ìlànà mẹ́rin tó lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ irú ẹni táwọn èèyàn máa fẹ́ mú lọ́rẹ̀ẹ́.”