Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú èyíkéyìí tí ìjọ bá ní lọ́wọ́, irú bíi, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? àti àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú márùn-ún tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde: Irú Ìwé Wo Ni Bíbélì Jẹ́?, Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?, Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?, Ta Ló Ń Darí Ayé Yìí? àti Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin? July àti August: Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!, Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé. September: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!
◼ Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kíláàsì tá a máa ṣe lápá ìparí ọdún iṣẹ́ ìsìn 2014, ọjọ́ mẹ́fà la ó máa lò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà, ìyẹn Monday sí Sátidé.