Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 7
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 7
Orin 99 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 9 ìpínrọ̀ 21 sí 24 àti àpótí tó wà lójú ìwé 96 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Léfítíkù 17-20 (10 min.)
No. 1: Léfítíkù 19:19-32 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ọmọ Ọlọ́run àti Ọba Tí Ọlọ́run Yàn Ni Jésù Kristi—td 35A (5 min.)
No. 3: Má Ṣe Di Olè!—lr orí 24 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù July. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ fi àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ méjì tó wà lójú ìwé yìí ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, fún gbogbo àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n ka àwọn ìwé ìròyìn náà dáadáa, kí wọ́n sì fìtara kópa nínú fífi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Àwọn Àṣeyọrí Wo La Ṣe? Ìjíròrò. Akọ̀wé ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Sọ àwọn àṣeyọrí tẹ́ ẹ ṣe lásìkò Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì gbóríyìn fún ìjọ fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń pín ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi tàbí nígbà tí wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
Orin 123 àti Àdúrà