Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní June 30, 2014.
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká fi ìlànà tó wà ní Ẹ́kísódù 23:2 sílò tá a bá fẹ́ yan eré inájú àti eré ìtura tá a fẹ́ ṣe? [May 5, w11 7/15 ojú ìwé 10 sí 11 ìpínrọ̀ 3 sí 7]
Báwo ni òfin tí Jèhófà fún àwọn àlùfàá pé kí wọ́n máa wẹ̀ kí wọ́n tó rú ẹbọ ti ṣe pàtàkì tó, báwo sì ni ìkìlọ̀ yìí ṣe jẹ́ ìránnilétí tó lágbára fáwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní? (Ẹ́kís. 30:18-21) [May 19, w96 7/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 9]
Kí nìdí tí Ọlọ́run kò fi fìyà jẹ Áárónì torí pé ó ṣe ère ọmọ málùú? (Ẹ́kís. 32:1-8, 25-35) [May 19, w04 3/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 4]
Báwo ni ọwọ́ táwọn Kristẹni fi mú ìfẹ́rasọ́nà àti ìgbéyàwó ṣe jọra pẹlú òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ àjèjì? (Ẹ́kís. 34:12-16) [May 26, w89 11/1 ojú ìwé 20 àti 21 ìpínrọ̀ 11 sí 13]
Kí nìdí tí ìtàn Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù fi jẹ́ ìṣírí gidi fún wa? (Ẹ́kís. 35:30-35) [May 26, w10 9/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 13]
Kí ni “àmì mímọ́ ti ìyàsímímọ́” tí àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì ń fi sára láwàní rẹ̀ máa ń rán an létí, kí sì ni àmì yìí kọ́ wa nípa ìyàsímímọ́? (Ẹ́kís. 39:30) [June 2, w01 2/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 2 sí 3]
Kí ni ojúṣe gbogbo Kristẹni tó bá kan ọ̀rọ̀ kí wọ́n sọ ìwà àìtọ́ tí ẹnì kan tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni hù? (Léf. 5:1) [June 9, w97 8/15 ojú ìwé 27]
Iṣẹ́ pàtàkì wo ni ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ń ṣe ní Ísírẹ́lì ìgbaànì, kí sì nìyẹn túmọ̀ sí fún wa lónìí? (Léf. 7:31-33) [June 16, w12 1/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 11 sí 12]
Kí ló ṣeé ṣe kó wà lára ohun tó fa ẹ̀ṣẹ̀ Nádábù àti Ábíhù tí wọ́n jẹ́ ọmọ Áárónì, ẹ̀kọ́ wo la sì kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? (Léf. 10:1, 2, 9) [June 23, w04 5/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 6 sí 8]
Kí nìdí tí ọmọ bíbí fi máa ń sọ obìnrin di “aláìmọ́”? (Léf. 12:2, 5) [June 23, w04 5/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 2]