Orin 123
Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Jẹ́ Ẹ̀bùn
1. Jèhófà fáwa èèyàn rẹ̀ ní
Olùṣọ́ àgùntàn.
Wọ́n ń fi àpẹẹrẹ wọn kọ́ wa
Bó ṣe yẹ ká máa rìn.
(ÈGBÈ)
Ọlọ́run yan àwọn ọkùnrin
Olóòótọ́ táa fọkàn tán.
Wọ́n ńbójú tó agbo rẹ̀ ọ̀wọ́n;
Nífẹ̀ẹ́ wọn, iṣẹ́ wọn pọ̀.
2. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa, wọ́n fi wá sọ́kàn;
Wọ́n tún ńtọ́ wa sọ́nà.
Táa bá fara pa, wọ́n ńtọ́jú wa,
Wọ́n ńsọ̀rọ̀ tó tura.
(ÈGBÈ)
Ọlọ́run yan àwọn ọkùnrin
Olóòótọ́ táa fọkàn tán.
Wọ́n ńbójú tó agbo rẹ̀ ọ̀wọ́n;
Nífẹ̀ẹ́ wọn, iṣẹ́ wọn pọ̀.
3. Wọ́n ńfún wa nímọ̀ràn Ọlọ́run,
Ká má bàa ṣáko lọ.
Wọ́n ńmú ká rìn lọ́nà Ọlọ́run,
Ká sìnín lójoojúmọ́.
(ÈGBÈ)
Ọlọ́run yan àwọn ọkùnrin
Olóòótọ́ táa fọkàn tán.
Wọ́n ńbójú tó agbo rẹ̀ ọ̀wọ́n;
Nífẹ̀ẹ́ wọn, iṣẹ́ wọn pọ̀.
(Tún wo Aísá. 32:1, 2; Jer. 3:15; Jòh. 21:15-17; Ìṣe 20:28.)