Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Tí Wọ́n Jẹ́ “Àpẹẹrẹ Fún Agbo”
‘Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín tinútinú, pẹ̀lú ìháragàgà, kí ẹ di àpẹẹrẹ fún agbo.’—1 PÉTÉRÙ 5:2, 3.
1, 2. (a) Àǹfààní wo ni Jésù gbé lé àpọ́sítélì Pétérù lọ́wọ́, kí ló sì fi hàn pé kò sóun tó burú nínú bí Jésù ṣe fọkàn tán Pétérù? (b) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó yàn sípò?
NÍGBÀ tó kù díẹ̀ kí àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ti ọdún 33 Sànmánì Kristẹni wáyé, Pétérù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn mẹ́fà mìíràn ń jẹ oúnjẹ àárọ̀ tí Jésù ṣe fún wọn lẹ́bàá Òkun Gálílì. Kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Pétérù rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde, ó sì dájú pé inú rẹ̀ dùn gan-an pé Jésù wà láàyè. Àmọ́ ó tún ṣeé ṣe kí ẹ̀rù máa ba Pétérù. Ìdí ni pé ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn ló sẹ́, tó lóun ò mọ Jésù rí rárá. (Lúùkù 22:55-60; 24:34; Jòhánù 18:25-27; 21:1-14) Ǹjẹ́ Jésù bá Pétérù tó ti ronú pìwà dà wí nítorí pé kò nígbàgbọ́? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló gbé àǹfààní kan lé Pétérù lọ́wọ́, ìyẹn ni àǹfààní bíbọ́ “àwọn àgùntàn kéékèèké” tó jẹ́ ti Jésù àti ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn. (John 21:15-17) Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ti fi hàn, kò sóun tó burú nínú bí Jésù ṣe fọkàn tán Pétérù yẹn. Ìdí ni pé Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù, àtàwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù, ń bá a lọ láti máa ṣolùṣọ́ àgùntàn ìjọ Kristẹni lákòókò kan tí àdánwò líle wáyé tí iṣẹ́ ìwàásù sì ń gbòòrò gan-an.—Ìṣe 1:15-26; 2:14; 15:6-9.
2 Lákòókò tiwa yìí, Jèhófà ń tipasẹ̀ Jésù Kristi yan àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ìjọ kí wọ́n lè máa darí àwọn àgùntàn Ọlọ́run lákòókò tó nira jù lọ nínú ìtàn ìran èèyàn yìí. (Éfésù 4:11, 12; 2 Tímótì 3:1) Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ dára bí Jèhófà ṣe fọkàn tán àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn? Àlàáfíà tó wà láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé fi hàn pé ó dáa bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́, àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyí kì í ṣe ẹni tí kò lè ṣàṣìṣe gẹ́gẹ́ bí Pétérù náà kò ṣe jẹ́ ẹni tí kò lè ṣàṣìṣe . (Gálátíà 2:11-14; Jákọ́bù 3:2) Síbẹ̀, Jèhófà fọkàn tán wọn pé wọ́n á bójú tó àwọn àgùntàn “tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.” (Ìṣe 20:28) Jèhófà fẹ́ràn àwọn ọkùnrin wọ̀nyí gan-an, ó sì kà wọ́n “yẹ fún ọlá ìlọ́po méjì.”—1 Tímótì 5:17.
3. Ọ̀nà wo làwọn olùṣọ́ àgùntàn inú ìjọ Kristẹni gbà ń fi hàn pé àwọn múra tán láti sìn?
3 Ọ̀nà wo làwọn olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run gbà ń fi hàn pé àwọn múra tán láti sìn, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ fún ìjọ? Bíi ti Pétérù àtàwọn olùṣọ́ àgùntàn mìíràn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, wọ́n gbára lé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run èyí tó ń fún wọn lókun tí wọ́n nílò láti ṣe iṣẹ́ tá a gbé lé wọn lọ́wọ́. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ẹ̀mí mímọ́ tún ń mú kí wọ́n ní èso tẹ̀mí tí í ṣe ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu. (Gálátíà 5:22, 23) Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ọ̀nà kan yẹ̀ wò táwọn olùṣọ́ àgùntàn lè gbà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nínú fífi èso tẹ̀mí yìí hàn bí wọ́n ti ń ṣolùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tó wà níkàáwọ́ wọn.
Ẹ Nífẹ̀ẹ́ Agbo àti Àgùntàn Kọ̀ọ̀kan
4, 5. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà àti Jésù gbà ń fìfẹ́ hàn fún agbo? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà táwọn olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run gbà ń fìfẹ́ hàn fún agbo?
4 Ìfẹ́ ni ànímọ́ tó gbawájú jù lọ tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ kéèyàn ní. Jèhófà ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ agbo lódindi nípa pípèsè ọ̀pọ̀ oúnjẹ tẹ̀mí. (Aísáyà 65:13, 14; Mátíù 24:45-47) Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe pé ó ń bọ́ agbo nìkan, ó tún ń fìfẹ́ hàn fún àgùntàn kọ̀ọ̀kan nínú agbo. (1 Pétérù 5:6, 7) Jésù pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ agbo. Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún un, ó sì mọ àgùntàn kọ̀ọ̀kan, àní ó mọ “orúkọ” ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.—Jòhánù 10:3, 14-16.
5 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run ń fara wé Jèhófà àti Jésù. Wọ́n máa ń fìfẹ́ hàn fún agbo Ọlọ́run lódindi nípa ‘kíkọ́’ ìjọ lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn àsọyé tó dá lórí Bíbélì tí wọ́n ń sọ ni wọ́n fi ń bọ́ agbo, wọ́n sì tún ń dáàbò bo agbo, gbogbo àwọn ará ìjọ ló sì máa ń rí iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ń ṣe yìí. (1 Tímótì 4:13, 16) Àmọ́, àwọn ohun kan wà táwọn ará kì í rí, ìyẹn ni àkókò tí wọ́n ń lò láti fi bójú tó àkọsílẹ̀ ìjọ, láti kọ àwọn lẹ́tà, láti ṣe àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ àtàwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ mìíràn káwọn ìpàdé ìjọ àtàwọn ìgbòkègbodò yòókù lé máa wáyé “lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.” (1 Kọ́ríńtì 14:40) Àwọn ará ìjọ kì í rí wọn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ọ̀pọ̀ lára àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ sì làwọn iṣẹ́ wọ̀nyí lè má fi bẹ́ẹ̀ jọni lójú. Iṣẹ́ tí ìfẹ́ ń súnni ṣe ni lóòótọ́.—Gálátíà 5:13.
6, 7. (a) Ọ̀nà wo làwọn olùṣọ́ àgùntàn lè gbà di ojúlùmọ̀ àwọn àgùntàn? (b) Nígbà mìíràn, kí nìdí tó fi dára láti sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹni fún alàgbà kan?
6 Àwọn Kristẹni tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ máa ń sápá láti fìfẹ́ hàn sí àgùntàn kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ. (Fílípì 2:4) Ọ̀nà kan táwọn olùṣọ́ àgùntàn gbà ń di ojúlùmọ̀ àgùntàn kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ jẹ́ nípa bíbá wọn ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù. Jésù sábà máa ń rí i pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wà pẹ̀lú òun lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó sì máa ń lo àkókò yẹn láti fún wọn níṣìírí. (Lúùkù 8:1) Arákùnrin kan tó ti ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn bọ̀ tipẹ́, sọ pé: “Mo ti rí i pé ọ̀nà kan tó dára jù lọ láti gbà mọ arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan ni pé kéèyàn bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù.” Bí o kò bá tíì láǹfààní láti bá ọ̀kan lára àwọn alàgbà ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù lẹ́nu àìpẹ́ yìí, o ò ṣe ṣètò láti tètè ṣe bẹ́ẹ̀?
7 Ìfẹ́ ló mú kí Jésù máa bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń yọ̀, tínú rẹ̀ sì máa ń bà jẹ́ nígbà tínú wọn bá bà jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àádọ́rin ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ padà dé látẹnu iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n sì ń yọ̀, Jésù ní “ayọ̀ púpọ̀.” (Lúùkù 10:17-21) Àmọ́, nígbà tó rí i bí ikú Lásárù ṣe ba Màríà àtàwọn ará ilé Màríà àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú jẹ́ tó, “Jésù bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.” (Jòhánù 11:33-35) Bẹ́ẹ̀ náà làwọn olùṣọ́ àgùntàn tó láájò ṣe máa ń bìkítà fáwọn àgùntàn lónìí. Ìfẹ́ ló ń mú káwọn olùṣọ́ àgùntàn “máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ” tí wọ́n sì máa ń “sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.” (Róòmù 12:15) Bí ohun ayọ̀ tàbí nǹkan ìbànújẹ́ bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti sọ bó ṣe rí lára rẹ fáwọn olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Kristẹni. Mímọ̀ tí wọ́n bá mọ̀ nípa ayọ̀ rẹ yóò fún wọn níṣìírí. (Róòmù 1:11, 12) Mímọ̀ tí wọ́n bá sì mọ̀ nípa àdánwò rẹ yóò mú kí wọ́n lè fún ọ lókun àti ìtùnú.—1 Tẹsalóníkà 1:6; 3:1-3.
8, 9. (a) Ọ̀nà wo ni alàgbà kan gbà fìfẹ́ hàn fún ìyàwó rẹ̀? (b) Báwo ló ṣe ṣe pàtàkì tó pé kí olùṣọ́ àgùntàn máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará ilé rẹ̀?
8 Ìfẹ́ tí olùṣọ́ àgùntàn kan ní fún agbo máa ń hàn ní pàtàkì nínú ọ̀nà tó ń gbà hùwà sí ìdílé tirẹ̀. (1 Tímótì 3:1, 4) Tó bá jẹ́ ẹni tó ti ṣègbéyàwó, ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tó ń fi hàn sí aya rẹ̀ yóò jẹ́ àpẹẹrẹ rere táwọn ọkọ tó wà nínú ìjọ máa tẹ̀ lé. (Éfésù 5:25; 1 Pétérù 3:7) Ìwọ wo ohun tí obìnrin Kristẹni kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Linda sọ. Ó lé lógún ọdún tí ọkọ rẹ̀ fi jẹ́ alábòójútó kó tó kú. Obìnrin náà sọ pé: “Ọwọ́ ọkọ mi máa ń dí gan-an bó ti ń bójú tó ìjọ. Àmọ́ ó jẹ́ kí n mọ̀ pé a jọ ń ṣiṣẹ́ náà ni. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ mi pé mò ń ti òun lẹ́yìn, ó sì máa ń wà pẹ̀lú mi nígbà tí kò bá sí lẹ́nu iṣẹ́ ìjọ. Nípa bẹ́ẹ̀, mo rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ mi, èyí kò sì ń jẹ́ kí n bínú nígbà tó bá ń lo àkókò rẹ̀ láti fi gbọ́ ti ìjọ.”
9 Bí olùṣọ́ àgùntàn kan bá láwọn ọmọ, ọ̀nà tó ń gbà fìfẹ́ bá wọn wí tó sì ń yìn wọ́n déédéé yóò jẹ́ àpẹẹrẹ fáwọn òbí yòókù láti tẹ̀ lé. (Éfésù 6:4) Ká sòótọ́, ìfẹ́ tó ń fi hàn fáwọn ará ilé rẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé ó kúnjú ìwọ̀n iṣẹ́ tí wọ́n gbé lé e lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án.—1 Tímótì 3:4, 5.
Jíjùmọ̀sọ̀rọ̀ Ń Mu Ayọ̀ àti Alàáfíà Wá
10. (a) Kí ló lè ṣàkóbá fún ayọ̀ àti àlàáfíà ìjọ? (b) Ọ̀ràn wo ló fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀ nínú àwọn ìjọ ọ̀rúndún kìíní, báwo ni wọ́n sì ṣe yanjú ọ̀ràn náà?
10 Ẹ̀mí mímọ́ lè mú kí ayọ̀ àti àlàáfíà wà nínú ọkàn Kristẹni kọ̀ọ̀kan, ó sì lè mú kó wà láàárín ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà àti nínú ìjọ lódindi. Àmọ́ ṣá o, bí olúkúlùkù kò bá ń sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ jáde nígbà tí wọ́n bá ń jíròrò, èyí lè nípa tí kò dára lórí ayọ̀ àti àlàáfíà ìjọ. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.” (Òwe 15:22) Ní ìdà kejì, sísọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti látọkànwá máa ń mú kí ayọ̀ àti àlàáfíà wà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀ràn ìdádọ̀dọ́ fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀ nínú àwọn ìjọ ọ̀rúndún kìíní, ìgbìmọ̀ olùdarí ní Jerúsálẹ́mù wá ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́. Àwọn alàgbà náà tún sọ èrò tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wọ́n ní lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́. Lẹ́yìn tí wọ́n ti jọ sọ̀rọ̀ gan-an, wọ́n ṣe ìpinnu kan. Nígbà tí wọ́n sọ ìpinnu tí wọ́n jọ fohùn ṣọ̀kan lé náà fáwọn ìjọ, àwọn ará “yọ̀ nítorí ìṣírí náà.” (Ìṣe 15:6-23, 25, 31; 16:4, 5) Èyí sì ń mú kí ayọ̀ àti àlàáfíà wà nínú ìjọ.
11. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè mú kí ayọ̀ àti àlàáfíà máa wà nínú ìjọ?
11 Bákan náà lónìí, àwọn olùṣọ́ àgùntàn ń mú kí ayọ̀ àti àlàáfíà wà nínú ìjọ nípa bíbá àwọn ará sọ̀rọ̀ dáadáa. Nígbà táwọn ìṣòro kan bá fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ, wọ́n á pàdé pọ̀ wọ́n á sì sọ èrò ọkàn wọn nípa ọ̀ràn náà láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Wọ́n máa ń fetí sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sóhun táwọn tí wọ́n jọ jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn bá ń sọ. (Òwe 13:10; 18:13) Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbàdúrà pé kí ẹ̀mí mímọ́ wà pẹ̀lú wọn, wọ́n á gbé ìpinnu wọn ka ìlànà Bíbélì àti àwọn ìlànà tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti tẹ̀ jáde. (Mátíù 24:45-47; 1 Kọ́ríńtì 4:6) Nígbà tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà bá ti ṣe ìpinnu kan tó bá Ìwé Mímọ́ mu, alàgbà kọ̀ọ̀kan yóò tẹ̀ lé ìdarí ẹ̀mí mímọ́ nípa títi ìpinnu yẹn lẹ́yìn àní bí ọ̀pọ̀ jù lọ kò tiẹ̀ tẹ́wọ́ gba èrò tirẹ̀. Fífi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ hàn lọ́nà yìí máa ń mú kí ayọ̀ àti àlàáfíà wà, ó sì máa ń jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn àgùntàn láti tẹ̀ lé nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa bá Ọlọ́run rìn. (Míkà 6:8) Ǹjẹ́ ó máa ń fìrẹ̀lẹ̀ kọ́wọ́ ti ìpinnu tó bá Bíbélì mú táwọn olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ ṣe?
Jẹ́ Onípamọ́ra àti Onínúure
12. Kí nìdí tí Jésù fi ní láti lo ìpamọ́ra kó sì fi inú rere bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lò?
12 Jésù ní ìpamọ́ra ó sì fi inú rere bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lò láìka àṣìṣe tí wọ́n ṣe léraléra sí. Bí àpẹẹrẹ, léraléra ni Jésù tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn lọ́kàn pé ó yẹ kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (Mátíù 18:1-4; 20:25-27) Síbẹ̀, lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, kété lẹ́yìn tó ti fún wọn nítọ̀ọ́ni nípa béèyàn ṣe ń lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ lẹ́yìn tó wẹ ẹsẹ wọn tán, “awuyewuye gbígbónájanjan kan tún dìde láàárín wọn lórí èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ.” (Lúùkù 22:24; Jòhánù 13:1-5) Ǹjẹ́ Jésù sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sáwọn àpọ́sítélì náà? Rárá o, ńṣe ló fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún wọn, ó ní: “Ta ni ẹni tí ó tóbi jù, ṣé ẹni tí ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì ni tàbí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́? Kì í ha ṣe ẹni tí ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì ni? Ṣùgbọ́n èmi wà láàárín yín gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.” (Lúùkù 22:27) Ìpamọ́ra àti inú rere Jésù, pa pọ̀ pẹ̀lú àpẹẹrẹ rere rẹ̀, wá wọ àwọn àpọ́sítélì náà lọ́kàn gan-an nígbà tó yá.
13, 14. Ìgbà wo ló yẹ kí olùṣọ́ àgùntàn finú rere hàn gan-an?
13 Lọ́nà kan náà, ó lè pọn dandan kí olùṣọ́ àgùntàn kan nínú ìjọ fún ẹnì kan nímọ̀ràn léraléra nípa ìkùdíẹ̀-káàtó kan. Èyí lè mú kínú bí olùṣọ́ àgùntàn náà sí onítọ̀hún. Àmọ́ ṣá o, ó yẹ kí olùṣọ́ àgùntàn náà máa rántí pé òun náà ní kùdìẹ̀-kudiẹ bó ti ‘ń fún àwọn tí ń ṣe ségesège ní ìṣílétí.’ Nípa bẹ́ẹ̀, èyí á jẹ́ kó lè fi ìpamọ́ra àti inú rere hàn sí arákùnrin rẹ̀. Lọ́nà yẹn, ó ń fara wé Jésù àti Jèhófà, àwọn ti ń fi àwọn ànímọ́ wọ̀nyí hàn sí gbogbo Kristẹni, títí kan àwọn olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ.—1 Tẹsalóníkà 5:14; Jákọ́bù 2:13.
14 Nígbà mìíràn, àwọn olùṣọ́ àgùntàn lè ní láti bá ẹnì kan tó dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wí gidigidi. Bí onítọ̀hún kò bá ronú pìwà dà, àwọn olùṣọ́ àgùntàn ní láti yọ ẹlẹ́ṣẹ̀ náà kúrò nínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 5:11-13) Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀nà tí wọ́n máa gbà bá onítọ̀hún lò yẹ kó fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ náà ni wọ́n kórìíra kì í ṣe ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà. (Júdà 23) Inú rere táwọn olùṣọ́ àgùntàn fi hàn lè mú kó rọrùn fún àgùntàn tó ń ṣáko lọ yìí láti padà wá sínú agbo níkẹyìn.—Lúùkù 15:11-24.
Ìgbàgbọ́ Ló Ń Mú Kéèyàn Ṣe Iṣẹ́ Rere
15. Ọ̀nà wo làwọn olùṣọ́ àgùntàn gbà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwà rere Jèhófà, kí ló sì ń mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀?
15 ‘Jèhófà ń ṣe rere fún gbogbo èèyàn,’ àní fáwọn tí kò mọyì ohun tó ń ṣe fún wọn pàápàá. (Sáàmù 145:9; Mátíù 5:45) Ọ̀nà kan tó ṣe kedere gan-an tí Jèhófà gbà ń fi ìwà rere rẹ̀ hàn ni bó ṣe ń rán àwọn èèyàn rẹ̀ láti lọ wàásù “ìhìn rere ìjọba náà.” (Mátíù 24:14) Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ń gbé ìwà rere Ọlọ́run yọ nípa mímú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù yìí. Kí ló ń sún wọn ṣe iṣẹ́ náà láìkáàárẹ̀? Ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà àti nínú àwọn ìlérí rẹ̀ ni.—Róòmù 10:10, 13, 14.
16. Báwo làwọn olùṣọ́ àgùntàn ṣe lè “ṣe ohun rere” sí àwọn àgùntàn?
16 Láfikún sí ṣíṣe “ohun rere sí gbogbo ènìyàn” nípa lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, àwọn olùṣọ́ àgùntàn tún ní láti máa ṣe ohun rere “ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá [wọn] tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Ọ̀nà kan tí wọ́n ń gbà ṣe èyí ni ṣíṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn ará láti lọ fún wọn níṣìírí. Alàgbà kan sọ pé: “Mo máa ń gbádùn ṣíṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn. Ó máa ń fún mi láǹfààní láti yin àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin fún ìsapá wọn, ó sì tún ń fún mi láǹfààní láti fì hàn pé mo mọyì iṣẹ́ àṣekára wọn.” Nígbà mìíràn, àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń dámọ̀ràn àwọn ọ̀nà tí ẹnì kan lè gbà mú kí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Jèhófà dára sí i. Ó dára káwọn olùṣọ́ àgùntàn máa fara wé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nínú èyí. Wo bó ṣe rọ àwọn arákùnrin tó wà ní Tẹsalóníkà, ó ní: “Àwa ní ìgbọ́kànlé nínú Olúwa nípa yín, pé ẹ ń ṣe àwọn ohun tí a pa láṣẹ, ẹ ó sì máa bá a lọ ní ṣíṣe wọ́n.” (2 Tẹsalóníkà 3:4) Sísọ irú àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí máa ń jẹ́ káwọn àgùntàn túbọ̀ lo ànímọ́ rere tí wọ́n ní, ó sì tún ń jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún wọn láti “jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú.” (Hébérù 13:17) Nígbà táwọn olùṣọ́ àgùntàn bá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ, o ò ṣe jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó mọrírì ìbẹ̀wò tí wọ́n ṣe náà?
Ìwà Tútù Gba Pé Kéèyàn Ní Ìkóra-Ẹni-Níjàánu
17. Ẹ̀kọ́ wo ni Pétérù rí kọ́ lára Jésù?
17 Jésù jẹ́ onínú tútù, kódà nígbà tí wọ́n mú un bínú pàápàá. (Mátíù 11:29) Nígbà ti wọ́n da Jésù, tí wọ́n sì mú un, ó fi ìwà tútù hàn ó sì lo ìkóra-ẹni-níjàánu gan-an. Àmọ́, kíá ni Pétérù fa idà yọ tó sì gbẹ̀san. Ṣùgbọ́n Jésù rán an létí ohun kan, ó sọ pé: “Ìwọ ha rò pé èmi kò lè ké gbàjarè sí Baba mi láti pèsè àwọn áńgẹ́lì tí ó ju líjíónì méjìlá fún mi ní ìṣẹ́jú yìí?” (Mátíù 26:51-53; Jòhánù 18:10) Ẹ̀kọ́ náà wọ Pétérù lọ́kàn gan-an, ó sì rán àwọn Kristẹni létí lẹ́yìn ìgbà náà pé: “Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí . . . . Nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà. Nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni.”—1 Pétérù 2:21-23.
18, 19. (a) Ìgbà wo ló yẹ káwọn olùṣọ́ àgùntàn fi ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu hàn gan-an? (b) Àwọn ìbéèrè wo la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
18 Bákan náà, táwọn olùṣọ́ àgùntàn bá fẹ́ ṣàṣeyọrí, wọ́n ní láti jẹ́ oníwà tútù kódà nígbà táwọn kan ò bá bọ̀wọ̀ fún wọn pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan tí wọ́n fẹ́ ràn lọ́wọ́ nínú ìjọ lè má tẹ́wọ́ gba ìrànwọ́ náà. Bí wọ́n bá fún ẹnì kan tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí tó sì nílò ìrànlọ́wọ́ nímọ̀ràn, ó lè fèsì padà nípa ‘sísọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.’ (Òwe 12:18) Àmọ́ o, bíi ti Jésù, àwọn olùṣọ́ àgùntàn kò ní dáhùn padà lọ́nà líle tàbí kí wọ́n ṣe àwọn nǹkan kan láti gbẹ̀san. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á kóra wọn níjàánu, wọ́n á fẹ̀mí ìfọ̀rọ̀-rora-ẹni-wò hàn, èyí á sì jẹ́ ìbùkún fún ẹni tó nílò ìrànlọ́wọ́ náà. (1 Pétérù 3:8, 9) Ǹjẹ́ ò ń kẹ́kọ̀ọ́ lára àpẹẹrẹ àwọn alàgbà tó ń fi ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu hàn nígbà tí wọ́n bá ń fún ọ nímọ̀ràn?
19 Láìsí àní-àní, Jèhófà àti Jésù mọrírì iṣẹ́ takuntakun tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùṣọ́ àgùntàn ń ṣe láti máa fìfẹ́ bójú tó agbo Ọlọ́run kárí ayé. Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ tún fẹ́ràn ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí wọ́n ń ti àwọn alàgbà lẹ́yìn nínú ‘ṣíṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́.’ (Hébérù 6:10) Kí wá nìdí táwọn arákùnrin kan tí wọ́n ti ṣèrìbọmi fi lè máa lọ́ tìkọ̀ láti tẹ́wọ́ gba “iṣẹ́ àtàtà” yìí? (1 Tímótì 3:1) Báwo sì ni Jèhófà ṣe ń da àwọn tó yàn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn lẹ́kọ̀ọ́? A óò gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo làwọn olùṣọ́ àgùntàn ń gbà fìfẹ́ hàn fún agbo?
• Báwo ni gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ṣe lè mú kí ayọ̀ àti àlàáfíà máa wà?
• Kí nìdí táwọn olùṣọ́ àgùntàn fi máa ń lo ìpamọ́ra àti inú rere nígbà tí wọ́n bá ń fúnni nímọ̀ràn?
• Báwo làwọn alàgbà ṣe ń fi ìwà rere àti ìgbàgbọ́ hàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ìfẹ́ ló ń mú káwọn alàgbà máa bójú tó ìjọ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Wọ́n tún máa ń wáyè láti ṣe eré ìnàjú pẹ̀lú ìdílé wọn . . .
. . . wọ́n sì tún máa ń bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Bí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dára bá wà láàárín àwọn alàgbà, ayọ̀ àti àlàáfíà máa ń wà nínú ìjọ