ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 5/1 ojú ìwé 22-26
  • Jèhófà Ń dá Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Lẹ́kọ̀ọ́ Nítorí Agbo Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Ń dá Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Lẹ́kọ̀ọ́ Nítorí Agbo Rẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Tó Ti Pẹ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn Ń Dá Wọn Lẹ́kọ̀ọ́
  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Kọ́ Wọn
  • “Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye” Ń Kọ́ Wọn
  • Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Tí Wọ́n Jẹ́ “Àpẹẹrẹ Fún Agbo”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ẹ̀yin Olùṣọ́ Àgùntàn, Ẹ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • ‘Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ọkàn-àyà Mi’
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Ẹ̀yin Kristẹni Olùṣọ́ Àgùntàn,—‘Ẹ Jẹ́ Kí Ọkàn-Àyà Yín Gbòòrò’!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 5/1 ojú ìwé 22-26

Jèhófà Ń dá Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Lẹ́kọ̀ọ́ Nítorí Agbo Rẹ̀

“Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.”—ÒWE 2:6.

1, 2. Kí nìdí táwọn ọkùnrin tó ti ṣèrìbọmi fi máa ń fẹ́ láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ púpọ̀ sí i nínú ìjọ?

KRISTẸNI kan tó ń jẹ́ Nick tó ti fi ọdún méje sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà sọ pé: “Inú mi dùn gan-an nígbà tí wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí alàgbà. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ kan láti mú kí iṣẹ́ ìsìn mi sí Jèhófà túbọ̀ gbòòrò sí i ni mo kà á sí. Mo rò pé ó yẹ kí n dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Ọlọ́run fún gbogbo ohun tó ti ṣe fún mi. Mo sì tún fẹ́ láti ran àwọn ará ìjọ mi lọ́wọ́ débi tágbára mi bá gbé e dé, mo fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ báwọn alàgbà ṣe ran èmi náà lọ́wọ́.” Àmọ́ ṣá o, bí inú Nick ti dùn tó yìí, ohun kan tún wà tó ń dà á láàmú. Nick ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Nítorí pé mi ò tíì pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí alàgbà, ẹ̀rù bà mi pé mí ò tíì ní ọgbọ́n àti òye tí mo lè fi ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ lọ́nà tó dára.”

2 Àwọn tí Jèhófà yàn láti máa bójú tó agbo rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń mú wọn láyọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán àwọn alàgbà ìjọ Éfésù létí ohun kan tó ń múni láyọ̀ nígbà tó fa ọ̀rọ̀ Jésù yọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Sísìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà ń mú káwọn ọkùnrin tó ti ṣèrìbọmi túbọ̀ ṣiṣẹ́ sin Jèhófà àti ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń ran àwọn alàgbà lọ́wọ́. Wọ́n tún máa ń bójú tó àwọn iṣẹ́ mìíràn tó máa ń gba àkókò àmọ́ tí wọ́n jẹ́ iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì. Ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wọn ló mú káwọn arákùnrin wọ̀nyí máa ṣe àwọn iṣẹ́ tó ṣeyebíye wọ̀nyẹn.—Máàkù 12:30, 31.

3. Kí nìdí táwọn kan fi lè máa lọ́ tìkọ̀ láti tẹ́wọ́ gba àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ?

3 Bí arákùnrin kan bá ń lọ́ tìkọ̀ láti tẹ́wọ́ gba àǹfààní jíjẹ́ ìránṣẹ́ àti dídi alàgbà tó bá yá ńkọ́, tó ń rò pé òun kò kúnjú ìwọ̀n? Bíi ti Nick, ó lè máa bẹ̀rù pé òun kò tíì ní òye tó yẹ kéèyàn ní kó tó lè ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn lọ́nà tó dára. Ǹjẹ́ ìwọ gẹ́gẹ́ bí arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi wà lára àwọn tó ní irú èrò yìí? Irú èrò bẹ́ẹ̀ kò burú nítorí àwọn olùṣọ́ àgùntàn yóò jíhìn fún Jèhófà nípa ọ̀nà tí wọ́n gbà bójú tó agbo. Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí a bá fi púpọ̀ fún, púpọ̀ ni a ó fi dandan béèrè lọ́wọ́ rẹ̀; àti ẹni tí àwọn ènìyàn fi sí àbójútó púpọ̀, wọn yóò fi dandan béèrè fún púpọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ́wọ́ rẹ̀.”—Lúùkù 12:48.

4. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ran àwọn tó yàn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó lọ́wọ́ láti máa bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀?

4 Ǹjẹ́ Jèhófà retí pé káwọn tí òun yàn sípò ìránṣẹ́ àti alàgbà máa dá gbé ẹrù iṣẹ́ wọn láìsí ìrànlọ́wọ́? Rára o, ó ń pèsè ìrànlọ́wọ́ tó dára tó ń mú kí wọ́n lè bójú tó iṣẹ́ wọn kí wọ́n sì ṣàṣeyọrí. Gẹ́gẹ́ bá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ́ tó ṣáájú, Jèhófà ń fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, èso ẹ̀mí mímọ́ yìí sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn àgùntàn lọ́nà pẹ̀lẹ́tù. (Ìṣe 20:28; Gálátíà 5:22, 23) Láfikún síyẹn, Jèhófà tún ń fún wọn ní ọgbọ́n, ìmọ̀, àti òye. (Òwe 2:6) Báwo ló ṣe ń ṣe èyí? Ẹ jẹ́ ká jíròrò ọ̀nà mẹ́ta tí Jèhófà gbà ń kọ́ àwọn tó yàn láti máa bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀.

Àwọn Tó Ti Pẹ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn Ń Dá Wọn Lẹ́kọ̀ọ́

5. Kí ló mú kí Pétérù àti Jòhánù jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tó dáńgájíá?

5 Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù dúró níwájú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn, àwọn adájọ́ tó mọwá-mẹ̀yìn tó ń gbẹ́jọ́ àwọn ọkùnrin náà kà wọ́n sí “àwọn ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù.” Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, wọ́n mọ̀ọ́kọ wọ́n sì mọ̀ọ́kà, àmọ́ wọn ò lọ sílé ẹ̀kọ́ táwọn rábì tí ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. Síbẹ̀, Pétérù àti Jòhánù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù fi hàn pé àwọn jẹ́ olùkọ́ tó dáńgájíá, ìyẹn sì mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti sọ ọ̀pọ̀ lára àwọn tó gbọ́rọ̀ wọn di onígbàgbọ́. Báwo wá làwọn tí wọ́n kà sí gbáàtúù èèyàn yìí ṣe di olùkọ́ tó dáńgájíá? Lẹ́yìn táwọn adájọ́ náà ti gbọ́rọ̀ lẹ́nu sí Pétérù àti Jòhánù, wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí rí i kedere nípa wọn pé wọ́n ti máa ń wà pẹ̀lú Jésù.” (Ìṣe 4:1-4, 13) Lóòtọ́, wọ́n ti gba ẹ̀mí mímọ́. (Ìṣe 1:8) Síbẹ̀, ó tún hàn kedere sáwọn adájọ́ tí wọ́n jẹ́ òpè nípa tẹ̀mí wọ̀nyí pé Jésù ti dá àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí Jésù wà pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ lórí ilẹ̀ ayé, ó kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa kó àwọn ẹni bí àgùntàn jọ, ó sì tún kọ́ wọ́n bí wọ́n ṣe máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá di ara ìjọ.—Mátíù 11:29; 20:24-28; 1 Pétérù 5:4.

6. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù àti Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ nípa dídá àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́?

6 Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó ń bá a lọ láti máa kọ́ àwọn tó ti yàn sípò olùṣọ́ àgùntàn. (Ìṣípayá 1:1; 2:1–3:22) Bí àpẹẹrẹ, òun fúnra rẹ̀ ló yan Pọ́ọ̀lù tó sì dá a lẹ́kọ̀ọ́. (Ìṣe 22:6-10) Pọ́ọ̀lù mọrírì ẹ̀kọ́ tó gbà ó sì fi ẹ̀kọ́ náà kọ́ àwọn alàgbà yòókù. (Ìṣe 20:17-35) Bí àpẹẹrẹ, ó lo ọ̀pọ̀ àkókò àti okun láti fi dá Tímótì lẹ́kọ̀ọ́ kó lè jẹ́ “aṣiṣẹ́” fún Ọlọ́run “tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú.” (2 Tímótì 2:15) Àjọṣe tó lágbára ló wà láàárín àwọn méjèèjì. Ṣáájú ìgbà yẹn ni Pọ́ọ̀lù ti kọ̀wé nípa Tímótì pé: “Bí ọmọ lọ́dọ̀ baba ni ó sìnrú pẹ̀lú mi fún ìtẹ̀síwájú ìhìn rere.” (Fílípì 2:22) Àmọ́, kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù ń wá bóun ṣe máa sọ Tímótì tàbí àwọn mìíràn di ọmọ ẹ̀yìn ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gba àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ níyànjú láti di ‘aláfarawé òun bí òun ṣe jẹ́ aláfarawé Kristi.’—1 Kọ́ríńtì 11:1.

7, 8. (a) Ìrírí wo ló fi hàn pé táwọn alàgbà bá fára wé Jésù àti Pọ́ọ̀lù, ó máa ń yọrí sí rere? (b) Ìgbà wo ló yẹ káwọn alàgbà bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn tó lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà lẹ́kọ̀ọ́?

7 Àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ń fara wé Jésù àti Pọ́ọ̀lù nípa dídá àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi lẹ́kọ̀ọ́, ìsapá wọn sì ń yọrí sí rere. Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin Chad yẹ̀ wò. Inú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà àmọ́ wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí alàgbà láìpẹ́ yìí. Ó sọ pé: “Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, àwọn alàgbà mélòó kan tí wọ́n ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ alàgbà ti ràn mí lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Nítorí pé bàbá mi jẹ́ aláìgbàgbọ́, àwọn alàgbà wọ̀nyẹn fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí mi wọ́n sì di bàbá mi nípa tẹ̀mí. Wọ́n lo àkókò wọn láti dá mi lẹ́kọ̀ọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, lẹ́yìn náà, alàgbà kan ní pàtàkì dá mi lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí mo ṣe máa bójú tó iṣẹ́ ìjọ tí wọ́n gbé fún mi.”

8 Gẹ́gẹ́ bá a ti rí i nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin Chad, àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ olóye ti máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn tó lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà lẹ́kọ̀ọ́ tipẹ́ káwọn arákùnrin náà tó tẹ̀ síwájú débi tí wọ́n á kúnjú ìwọ̀n fún iṣẹ́ náà. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Nítorí pé Bíbélì pàṣẹ fáwọn tó fẹ́ di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà pé kí wọ́n ti máa gbé ìgbé ayé ìwà rere kí wọ́n sì jẹ́ ẹni tẹ̀mí ká tó yàn wọ́n láti máa sìn. Wọ́n gbọ́dọ̀ “kọ́kọ́ dán àwọn wọ̀nyí wò ní ti bí wọn ti yẹ sí.”—1 Tímótì 3:1-10.

9. Iṣẹ́ wo la gbé lé àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn lọ́wọ́, kí sì nìdí rẹ̀?

9 Bí a bá fẹ́ yẹ àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi wò bí wọ́n ti yẹ sí, ó yẹ ká kọ́kọ́ dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Wo àpèjúwe yìí: Bí wọ́n bá ní kí akẹ́kọ̀ọ́ kan ṣe ìdánwò kan táwọn olùkọ́ kò kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ rí, ǹjẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà lè yege ìdánwò ọ̀hún? Kò dájú pé yóò yege. Nítorí náà, ìdálẹ́kọ̀ọ́ ṣe pàtàkì. Àmọ́ ṣá o, olùkọ́ tó ń fẹ́ ire àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kì í kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè yege ìdánwò nìkan, àmọ́ á tún kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè máa lo ìmọ̀ tí wọ́n gbà. Bákan náà, àwọn akíkanjú alàgbà máa ń ran àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi lọ́wọ́ nípa dídá wọn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè ní àwọn ànímọ́ táwọn tá a bá yàn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó nínu ìjọ gbọ́dọ̀ ní. Kì í ṣe nítorí kí wọ́n lè ran àwọn arákùnrin náà lọ́wọ́ láti dẹni tá a yàn nìkan ni wọ́n ṣe ń ṣe èyí, ṣùgbọ́n wọ́n tún ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè bójú tó agbo Ọlọ́run dáadáa. (2 Tímótì 2:2) Àmọ́ ṣá o, àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi pàápàá ní láti ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n téèyàn fi ń di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà. (Títù 1:5-9) Síbẹ̀, àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn lè ran àwọn arákùnrin tó fẹ́ tẹ̀ síwájú náà lọ́wọ́ nípa mímúra tán láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè yára tẹ̀ síwájú.

10, 11. Báwo làwọn olùṣọ́ àgùntàn ṣe lè dá àwọn arákùnrin mìíràn lẹ́kọ̀ọ́ káwọn náà lè tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i?

10 Báwo làwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ṣe lè dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ láti bójú tó iṣẹ́ ìjọ? Wọ́n á kọ́kọ́ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn arákùnrin nínú ìjọ jẹ wọ́n lọ́kàn, wọ́n á jọ máa ṣiṣẹ́ déédéé lóde ìwàásù, wọ́n á sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ béèyàn ṣe ń fi ọwọ́ “títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tímótì 2:15) Àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn yóò máa bá àwọn arákùnrin náà sọ̀rọ̀ nípa ayọ̀ téèyàn máa ń rí nínú lílo ara rẹ̀ fáwọn ẹlòmíràn, àti ayọ̀ táwọn olùṣọ́ àgùntàn fúnra wọn máa ń rí bí wọ́n ti ń lé àwọn nǹkan tẹ̀mí, tọ́wọ́ wọ́n sì ń tẹ̀ ẹ́. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn tún máa ń dábàá àwọn nǹkan kan pàtó tó ní í ṣe pẹ̀lú bí arákùnrin kan ṣe lè túbọ̀ ṣe dáadáa sí i nínú jíjẹ́ “àpẹẹrẹ fún agbo.”—1 Pétérù 5:3, 5.

11 Nígbà tí wọ́n bá yan arákùnrin kan gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, àwọn alàgbà tó lóye kì í dáwọ́ dúró láti máa dá ẹni náà lẹ́kọ̀ọ́. Arákùnrin Bruce tó ti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà fún nǹkan bí àádọ́ta ọdún sọ pé: “Èmi àti ìránṣẹ́ tá a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn jọ máa ń jókòó láti ṣàyẹ̀wò àwọn ìtọ́sọ́nà tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye ti tẹ̀ jáde. A tún jọ máa ń ka ìlànà nípa iṣẹ́ kan pàtó tá a gbé fún ẹni náà, lẹ́yìn náà màá tún bá a ṣiṣẹ́ pọ̀ títí yóò fi mọ àwọn iṣẹ́ tá a gbé fún un dunjú.” Bí ìránṣẹ́ náà ti ń ní ọ̀pọ̀ oyè sí i, a óò tún dá a lẹ́kọ̀ọ́ nínú iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn. Bruce ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Nígbà tí mo bá mú ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lọ ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, mo máa ń ràn án lọ́wọ́ láti yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan pàtó tí yóò fún ẹni tá a lọ bá tàbí ìdílé tá a lọ bẹ̀ wò náà níṣìírí. Kíkọ́ bá a ṣe ń lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lọ́nà tí yóò wọni lọ́kàn dáadáa ṣe pàtàkì bí ìránṣẹ́ kan bá máa di alàgbà tó dáńgájíá.”—Hébérù 4:12; 5:14.

12. Báwo làwọn olùṣọ́ àgùntàn tó lóye ṣe lè dá àwọn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò alàgbà lẹ́kọ̀ọ́?

12 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn tún máa ń jàǹfààní gan-an tá a bá dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i. Arákùnrin Nick tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níṣàájú sọ pé: “Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mo gbà lọ́dọ̀ àwọn àgbàlagbà méjì tí wọ́n jẹ́ alábòójútó ló ràn mí lọ́wọ́ ní ti gidi. Àwọn arákùnrin wọ̀nyí sábà máa ń lóye bó ṣe yẹ kéèyàn bójú tó àwọn ọ̀ràn. Ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń fi sùúrù fetí sí mi, tí wọ́n sì máa ń gbé ohun tí mo bá sọ yẹ̀ wò, àní bí wọn ò bá tiẹ̀ ní gbà á. Mo ti kọ́ ohun púpọ̀ nípa ṣíṣàkíyèsí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ọ̀wọ̀ tí wọ́n fi ń bójú tó àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú ìjọ. Àwọn alàgbà wọ̀nyí tẹ̀ ẹ́ mọ́ mi lọ́kàn pé èèyàn ní láti lo Bíbélì lọ́nà tó já fáfá nígbà tèèyàn bá ń yanjú ìṣòro tàbí nígbà tèèyàn bá ń fúnni níṣìírí.”

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Kọ́ Wọn

13. (a) Kí ni arákùnrin kan nílò kó tó lè di olùṣọ́ àgùntàn tó dáńgájíá? (b) Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi “?

13 Dájúdájú, Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní àwọn òfin, àwọn ìlànà, àtàwọn àpẹẹrẹ táwọn olùṣọ́ àgùntàn nílò kí wọ́n lè dẹni tó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Arákùnrin kan lè jẹ́ ọ̀mọ̀wé, àmọ́ ìmọ̀ tó ní nínú ìwé mímọ́ àti bó ṣe ń lò ó ni yóò sọ ọ́ di olùṣọ́ àgùntàn tó dáńgájíá. Gbé àpẹẹrẹ Jésù yẹ̀ wò. Òun ló ní ìmọ̀ jù lọ, òun ló lóye jù lọ, òun sì ni olùṣọ́ àgùntàn tẹ̀mí tó gbọ́n jù lọ tó tíì gbé ayé rí, síbẹ̀ kò gbẹ́kẹ̀ lé ọgbọ́n ti ara rẹ̀ nígbà tó ń kọ́ àwọn àgùntàn Jèhófà. Ó sọ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” Kí nìdí tí Jésù fi fògo fún Bàbá rẹ̀ ọ̀run lọ́nà yìí? Ó ṣàlàyé pé: “Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ láti inú àpilẹ̀ṣe ti ara rẹ̀ ń wá ògo ti ara rẹ̀.”—Jòhánù 7:16, 18.

14. Báwo làwọn olùṣọ́ àgùntàn ṣe lè yẹra fún wíwá ògo ti ara wọn?

14 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ kì í wá ògo ti ara wọn. Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìmọ̀ràn àti ìṣírí tí wọ́n máa ń fúnni ti ń wá, kì í ṣe látinú ọgbọ́n ti ara wọn. Wọ́n mọ̀ pé iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ni láti ran àwọn àgùntàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní “èrò Kristi,” kì í ṣe kí wọ́n lè ní èrò tàwọn alàgbà. (1 Kọ́ríńtì 2:14-16) Bí àpẹẹrẹ, bí tọkọtaya kan bá ní ìṣòro nínú ìgbéyàwó wọn, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí alàgbà tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ bá gbé ìmọ̀ràn rẹ̀ karí èrò tara rẹ̀ dípò kó jẹ́ lórí ìlànà Bíbélì àtàwọn ìsọfúnni tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tẹ̀ jáde? (Mátíù 24:45) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àṣà ìbílẹ̀ àti ìwọ̀nba ìmọ̀ tó ní ló máa gbé ìmọ̀ràn tó ń fún wọn kà. Ká sòótọ́, àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan kò burú, alàgbà náà sì lè jẹ́ ẹni tó ní ìmọ̀ tó sì lóye ọ̀pọ̀ nǹkan láyé. Àmọ́ àwọn àgùntàn á jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ táwọn olùṣọ́ àgùntàn bá sọ fún wọn pé kí wọ́n fetí sí ohùn Jésù àti sí ọ̀rọ̀ Jèhófà dípò èrò ti ènìyàn tàbí ohun tí àṣà ìbílẹ̀ kan sọ.—Sáàmù 12:6; Òwe 3:5, 6.

“Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye” Ń Kọ́ Wọn

15. Iṣẹ́ wo ni Jésù gbé lé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” lọ́wọ́, kí sì ni ohun kan tó mú kí ẹgbẹ́ ẹrú náà máa ṣàṣeyọrí?

15 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn bíi àpọ́sítélì Pétérù, Jòhánù àti Pọ́ọ̀lù wà lára àwọn tí Jésù pè ní “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Ẹgbẹ́ ẹrú yìí jẹ́ àwọn arákùnrin Jésù tá a fi ẹ̀mí yàn tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n sì nírètí láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lọ́run. (Ìṣípayá 5:9, 10) Kò sí àní-àní pé àwọn arákùnrin Jésù tó kù lórí ilẹ̀ ayé ti dín kù gan-an láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò nǹkan ìsinsìnyí. Àmọ́, iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́ láti ṣe, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kí òpin tó dé ti gbòòrò báyìí ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Síbẹ̀, ẹgbẹ́ ẹrú náà ti ṣàṣeyọrí lọ́nà tó gadabú! Kí ló fà á? Dé ìwọ̀n àyè kan, ó jẹ́ nítorí pé wọ́n ti dá àwọn “àgùntàn mìíràn” lẹ́kọ̀ọ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni. (Jòhánù 10:16; Mátíù 24:14; 25:40) Lónìí, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ náà ló jẹ́ pé àwọn àgùntàn mìíràn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ló ń ṣe é.

16. Báwo ni ẹgbẹ́ ẹrú náà ṣe ń dá àwọn ọkùnrin tá a yàn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó lẹ́kọ̀ọ́?

16 Báwo ni ẹgbẹ́ ẹrú náà ṣe ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́? Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn aṣojú ẹgbẹ́ ẹrú náà ní àṣẹ láti máa dá àwọn alábòójútó lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì máa yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí alábòójútó nínú àwọn ìjọ, àwọn alábòójútó náà á sì wá dá àwọn ará ìjọ lẹ́kọ̀ọ́. (1 Kọ́ríńtì 4:17) Bákan náà ló ṣe rí lónìí. Ìgbìmọ̀ Olùdarí, ìyẹn àwọn alàgbà ẹni àmì òróró mélòó kan tí wọ́n ń ṣojú fún ẹgbẹ́ ẹrú náà ló ń fún àwọn aṣojú rẹ̀ láṣẹ láti yan àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àtàwọn alàgbà nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìjọ kárí ayé, kí wọ́n sì dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Láfikún sí i, Ìgbìmọ̀ Olùdarí tún ń ṣètò àwọn ilé ẹ̀kọ́ láti dá àwọn tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n lè mọ̀ bí wọ́n ṣe máa bójú tó àwọn àgùntàn lọ́nà tó dára jù lọ. Síwájú sí i, wọ́n máa ń pèsè ìtọ́sọ́nà nípasẹ̀ lẹ́tà, àwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ àti nípasẹ̀ àwọn ìwé mìíràn, irú bí ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà.a

17. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú ẹgbẹ́ ẹrú náà? (b) Ọ̀nà wo làwọn olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run lè gbà fi hàn pé àwọn nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú ẹgbẹ́ ẹrú náà?

17 Jésù nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé gan-an nínú ẹgbẹ́ ẹrú náà débi pé ó yàn án ṣe àbójútó “gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀,” ìyẹn gbogbo nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 24:47) Àwọn tá a yàn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ń fẹ̀rí hàn pé àwọn náà nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú ẹgbẹ́ ẹrú náà nípa títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà tí wọ́n ń rí gbà látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Dájúdájú, nígbà táwọn olùṣọ́ àgùntàn bá dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa kọ́ àwọn náà, tí wọ́n sì fi ẹ̀kọ́ tí ẹgbẹ́ ẹrú náà ń kọ́ wọn sílò, ìṣọ̀kan á túbọ̀ wà láàárín agbo Ọlọ́run. A mà kún fún ọpẹ́ gan-an o pé Jèhófà ń dá àwọn ọkùnrin tí wọ́n ń fìfẹ́ bójú tó àwọn èèyàn nínú ìjọ lẹ́kọ̀ọ́!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Báwo làwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ṣe máa ń dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́?

• Kí nìdí táwọn olùṣọ́ àgùntàn kì í fi í kọ́ni ní èrò ti ara wọn?

• Ọ̀nà wo làwọn olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run ń gbà fi hàn pé àwọ́n nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú ẹgbẹ́ ẹrú náà, kí sì nìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Àwọn alàgbà máa ń dá àwọn ọ̀dọ́kùnrin nínú ìjọ lẹ́kọ̀ọ́

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

“Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” máa ń fún àwọn alàgbà ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́